Kí ni ìdí tí PDP sẹ fẹ́ kí INEC pààrọ̀ ọ̀gá àgbà ọọ́físì rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo?

Oluwatoyin Babalola

Oríṣun àwòrán, INEC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu ZLP nipinlẹ Ondo, dokita Abass Mimiko ti tako bi ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe n ke si ajọ INEC lati alabojuto ajọ naa nipinlẹ Ondo, Oluwatoyin Babalola lọ ipinlẹ mii ṣaaju eto ibo gomina.

Ṣaaju ni PDP ti kọkọ sọ pe ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni obinrin naa, ati pe o ṣeeṣe ko gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo gomina ti yo waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu yii.

Amọ ẹgbẹ oṣelu APC, ZLP atawọn ẹgbẹ kan ti kii ṣe ti ijọba ti sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ.

Ninu ọrọ gomina ipinlẹ Ondo, to tun n dije du ipo gomina, Lucky Aiyedatiwa, o ni oṣiṣẹ ijọba n obinrin naa, ibi to ba wu ijọba lo si le gbe oṣiṣẹ rẹ si.

"Obinrin naa ko le yi esi ibo pada"

BBC Yoruba kan si Henry Olonimoyo, to jẹ onimọ nipa eto oṣelu ipinlẹ Ondo lati da si ọrọ naa.

Olonimoyo sọ pe ko nii ṣe boya ọmọ ipinlẹ Ondo ni obinrin naa tabi ipinlẹ Ondo lo gbe dagba.

O ni “Boya ipinlẹ Ondo lo ti wa o, tabi bẹẹ kọ, ko ni nnkan sẹ pẹlu eto idibo naa.

“Ti a ba wo daadaa, oun kọ lo maa ka ibo, oun kọ lo maa wa ni gbogbo ibudo dibo, oun kọ lo maa kede esi ibo.

“Bẹẹ si ni, pupọ ninu awọn to to fẹ ṣiṣẹ eto idibo naa lo n gbe ni ipinlẹ yii, kii ṣe ara ita.”

Olonimoyo sọ pe eeyan daadaa ni obinrin ọhun, bẹẹ ni kii ṣe ẹni ti ko mọ iṣẹ rẹ bii iṣẹ.

Nipa eredi ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sọ pe ki wọn gbe obirin naa kuro nipinlẹ Ondo ṣaaju eto idibo gomina, Olonimoyo sọ pe ọrọ oṣelu lasan ni.

O ni lootọ ni obinrin naa dagba si ipinlẹ Ondo, ko tumọ si pe o lagbara lati yi esi ibo gomina pada.