Taoreed Lagbaja: Ògo ìdílé àti ìlú wa ti sọnù – Àwọn mọ̀lẹ́bí

Àkọlé fídíò, Taoreed Lagbaja: Ògo ìdílé àti ìlú wa ti sọnù – Àwọn mọ̀lẹ́bí
Taoreed Lagbaja: Ògo ìdílé àti ìlú wa ti sọnù – Àwọn mọ̀lẹ́bí

Awọn mọlẹbi ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria to di ologbe, Taoreed Lagbaja ti n daro ipapoda rẹ.

Nigba ti BBC Yoruba ṣabẹwo si ilu Ilobu, to jẹ ilu ibilẹ oloogbe naa, niṣe lawọn mọlẹbi rẹ n wa ẹkun mu.

Awọn mọlẹbi ọhun sọ pe adanu nla ni iku rẹ jẹ fun awọn ati fun gbogbo ilu wọn lapapọ.

Aburo baba ologbe naa, ọgbẹni Tajudeen Adeyinka juwe rẹ gẹgẹ bii ẹni ti oun mu gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ oun.

O ni “Bii ko gba ẹmi emi gan lọ ni, bẹẹ lo ri loju mii.... mo ka a kun awọn ọmọ mi ni, o jẹ ibanujẹ fun gbogbo ẹbi pata.

Baba agba naa ṣalaye pe oloogbe naa lo fi owo ranṣẹ ti awọn fi ṣe omi si adugbo awọn, eyii ti wọn ko le gbagbe lailai.

Ọkan lara awọn oloye ilu rẹ, to jẹ Ọtun Jagun ilu Ilobu, Adegoke Ogunsola sọ pe “Inu wa ti kọkọ bajẹ nigba ti a gbọ pe ara rẹ ko le, ojojumọ ni ilu ati baba wa Kabiesi Olobu n gbadura pe ki Ọlọrun da pada si ipo ilera to wa.

“Ṣugbọn nigba ti a gbọ pe o ti pada si ọdọ Ẹlẹda rẹ to da a, inu wa bajẹ, inu wa ko dun, a si barajẹ, koda a n ṣọfọ lọwọ niluu Ilobu.”

Iwadii wa fi han pe asiko yii ni wọn n ṣe ayẹyẹ idasilẹ ilu Ilobu (Ilobu day) lọwọ amọ wọn dawọ ajọyọ naa duro latari iku Lagbaja.

Awọn eeyan ilu naa juwe Lagbja gẹgẹ bii ogo ilu wọn eyii to wọ lọsan an gangan.

Lẹyin naa ni wọn bẹ ijọba Naijiria pe ki wọn maṣẹ sin oku rẹ siluu Abuja nitori awọn n fẹ ki wọn sin oku rẹ sinu ilu awọn.