Kí ni yóò ṣẹlẹ sí okòòwò, ìrànlọ́wọ́ àti ààbò Africa lábẹ́ ìṣàkóso Trump?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi gbogbo oju ṣe ti ri i pe Donald Trump lo jawe olubori ninu ibo aarẹ ilẹ America, awọn olori ilẹ Africa kaakiri ni wọn ti n ki i ku oriire lẹẹkan si i.
"Zimbabwe setan lati ṣiṣẹ pẹlu rẹ", Aarẹ Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa, lo sọ bẹẹ fun Trump, bẹẹ lo n foju sọna fun ajọṣepọ pẹlu orilẹede nla naa. Bakan naa ni Aarẹ Bola Tinubu naa ti loun lero pe ipadabọ Trump yoo mu ajọṣepọ to gunmọ waye laaarin ilẹ Africa ati orilẹede America.
Ṣugbọn ṣe Trump yoo si fi oju ire wo ilẹ Adulawọ bi?
Ninu iṣakoso rẹ akọkọ, awọn awoye fi ẹsun kan Trump pe o dẹyẹ si ilẹ Africa, pẹlu bo ṣe ge awọn owo iranwọ kan ku, to dena irinajo lọ s'America fawọn kan, to si tun pe Africa ni iho idi, nibi ti ẹgbin ti n jade.
Ẹwẹ, Trump ṣe awọn eto kan to ni yoo mu igbega ba idokowo l'Africa. Awọn eto naa si n tẹsiwaju lẹyin ọdun mẹta to ti kuro nipo aarẹ America.
Ṣugbọn oju wo ni yoo fi wo ilẹ Africa ni saa rẹ tuntun yii?
Ìdókoòwò àti dídá iléeṣẹ́ sílẹ̀
Iṣakoso Joe Biden to n pari lọ yii gbiyanju lati fidi ẹ mulẹ pe ilẹ Africa ko kere ninu aye, paapaa lẹka idokoowo ati dida ileeṣẹ silẹ. W Gyude Moore, lati ẹka Center for Global Development, to tun jẹ minisita tẹlẹ ni Liberia lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
O ni Biden gbiyanju lati ri i pe ajọṣepọ gidi waye .Fun apẹẹrẹ, orilẹeede America gba oriyin fun pe wọn ṣe ọna oju irin kan ti wọn pe ni Lobito, si orilẹede Angola, to gba Congo kọja to si tun de Zambia, eyi ti wọn ni wọn yoo maa fi ko awọn nnkan eelo to lagbara wọlu.
Ni 2023, ilẹ America loun ti na ju $22bn lọ latigba ti Biden ti gba ipo agbara.
Ṣugbọn ẹru n ba ọpọ eeyan bayii, pe Trump le fa ọwọ aago idokoowo ati idaṣẹsilẹ pẹlu Africa ku. Awọn eeyan mọ Trump bii ẹni to maa n fi ti America ṣaaju lẹka okoowo. Wọn ni nitori ẹ lo ṣe fi ọrọ akọmọna rẹ ṣe "America First". To tumọ si pe America ni akọkọ ṣaaju ohunkohun.
Eto kan ti a mọ si 'The African Growth and Opportunity Act (Agoa), to maa n fun awọn ilẹ Africa kan lanfaani lati ko ọja wọ America lai sanwo ori lati ọdun 2000, ẹru ti n ba ọpọ eeyan lori rẹ bayii.
Trump ti sọ nipa rẹ ninu iṣakoso akọkọ, o ni oun ko ni i ṣe akọtun Agoa ti eyi ti wọn n jẹ anfaani rẹ lọwọ ba tan ni 2025.
Nigba to n si n polongo ibo ni 2024 yii, Trump jẹjẹẹ lati fi owo ori ida mẹwaa si ori awọn ọja to ba n ti okeere wa. Eyi yoo mu ki ọja ilẹ okeere wọn, yoo si di dandan fun awọn olokoowo lati Africa lati ta ọja wọn lowo pọọku lọja agbaye.
Awọn awoye lati South Africa ti n kọminu si ohun ti yoo ṣẹlẹ si Agoa, ati ipa aburu ti yoo ni lori ọrọ aje wọn.
Ṣugbọn ẹka Brookings Institution nilẹ America, sọ pe o le ma ni ipa to pọ lorii South Africa, wọn ni ida mẹfa naa ni yoo fi kan wọn( 0.06%), nitori ọpọ nnkan ti South Africa n ko wọ America bii irin ni Agoa ko tiẹ kan.
Bo si tilẹ jẹ pe Trump ko karamasiiki Agoa, o mọ pe bi America yoo ba ka apa China to n ba a figa gbaga lẹka ọrọ aje, to si n gbe Africa mọra yii, oun gbọdọ ṣe nnkan kan si i.
Ni 2018 , iṣakoso Trump igba naa gbe eto kan kalẹ, eyi to pe ni 'Prosper Africa'
Eto naa jẹ ọna lati ran awọn ileeṣẹ America ti wọn fẹẹ da ileeṣẹ silẹ l'Africa lọwọ
O tun gbe omiran kalẹ ti wọn pe ni Development Finance Corporation (DFC), eyi to n fowo ran ileeṣẹ lọwọ l'Africa ati kaakiri agbaye. Mejeeji ni Biden ri i pe wọn n ṣiṣẹ lọ nigba to gba akoso. Bẹẹ ni DFC sọ pe oun ti na ju $10bn (£8bn) lori ẹ l'Africa.
Ti a ba waa wo ti pe China ko ṣee fọwọ rọ sẹyin l'Africa, to si jẹ pe Trump lo gbe awọn eto mejeeji ta a wi yii aklẹ, o ṣee ṣe ko ro o wo lẹẹmeji ko too gbe igbese lorii wọn.
Ìrànwọ́
Ọdọ America ni ilẹ Africa ti n ri iranwọ gba ju, eyi naa lo jẹ ki America sọ pe oun ti fi owo to to $3.7bn ta wọn lọrẹ lọdun yii.
Ṣugbọn iṣakoso Trump to kọja ko yee sọ pe oun yoo ge awọn iranwọ yii ku kaakiri agbaye.Gẹgẹ bi akọsilẹ kaakiri aye ṣe wi, awọn kan ni wọn o gba fun un lati ge e ku.
To ba jẹ pe adinku ti Trump fẹ naa ti waye ni, awọn iranwọ lẹka ilera, ijọba awarawa, aabo ati ajọṣepọ ilẹ yii pẹlu America yoo ti fara gba a. Gẹgẹ bi ẹka Council on Foreign Relations, ni Washington ṣe sọ.
Ibẹru bojo tun wa, pe Trump le ge owo nla ti wọn fi n ṣeranwọ fun awọn to ba ni arun HIV ku. Pepfar ni wọn pe orukọ eto yii, eyi ti wọn ti fi n ran Africa lọwọ fun ọpọlọpọ ọdun.
Lọdun to kọja, awọn aṣofin Republican koro oju si Pepfar, wọn ni awọn to fẹẹ ṣẹyun ni wọn fi n ti lẹyin. Wọn saa fẹnuko si pe ki wọn ṣi fi i silẹ di oṣu kẹta ọdun to n bọ, ṣugbọn Trump ko fẹran keeyan maa ṣẹyun, boya yoo wo eyi lati fi oju ire wo Pepfa.
Ìrìnàjò
Trump ko fi bo, pe oun ko nifẹẹ si ki eeyan wọ ilu oniluu lai ni iwe aṣẹ to yẹ lati gbe nibẹ. Nibi ipolongo ibo rẹ ni 2024 yii, o ṣeleri lati da miliọnu kan eeyan pada sibi ti wọn ti wa, iyẹn awọn ti ko laṣẹ lati gbe l'America.
Eyi kan ilẹ Africa, ni 2022, o fẹrẹ to ẹgbẹrun mẹtala eeyan (13,000) ti wọn jẹ ọmọ Africa to n rin irin ajo wọ America, ti wọn ṣe akọsilẹ wọn ni bode America si Mexico. Gẹgẹ bi awọn aṣọbode America ṣe wi, nigba ti yoo fi di 2023, onka naa ti pọ ni ilọpo mẹta, o ti di 58,000. Awọn kan ninu wọn sọ pe ogun lo le awọn kuro lorilẹede awọn, bẹẹ lawọn mi-in ni ẹmi awọn ko balẹ nibi ti wọn bi awọn si, awọn kan si sọ pe iṣẹ ati oṣi lo le awọn de ilẹ alawọ funfun America.
Ọrọ ti Trump ṣe pe oun yoo le awọn ti ko lẹtọọ lati gbe l'America yii kọ ni akọkọ iru rẹ ti yoo sọ, ni saa akọkọ rẹ, Trump ṣe awọn eto kan to gbegidina lilọ si America fun awọn orilẹede bii Nigeria, Eritrea, Sudan ati Tanzania.
Bẹẹ naa lẹru ṣe n ba awọn ọmọ Kenya l'America bayii, o fẹrẹ to ọgọjọ ẹgbẹrun (160,000) wọn ti ẹru n ba, pe wọn yoo fi ọwọ osi juwe ilu awọn fawọn pẹlu iwọle Trump sipo agbara.
Ààbò àti aáwọ̀
Loootọ ni Trump kuro nipo aarẹ lasiko kan, ṣugbọn Russia rólé rẹ l'Africa.
Ọkan lara ọna ti wọn gba ṣe e ni pipese ọmọ ogun ati nnkan ija fun awọn orilẹede ti awọn agbesunmọmi n yọ lẹnu. Awọn bii Mali, Niger ati Burkina Faso.
Igbesẹ Russia yii naa n ke tantan leti America ti wọn jọ jẹ alatako ara wọn fun ọdun pipẹ.
Njẹ Trump yoo ran African lọwọ lati kọ oju Russia si oorun alẹ bi?
" Bo tilẹ jẹ pe ilẹ America ri Russia bii adunkooko mọ ni, Trump gẹgẹ bii ẹnikan ko ri eyi bẹẹ" Mr Moore lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.
Awọn ahesọ ọrọ kan n lọ nigboro, pe Trump ni ajọṣepọ to dan mọọnran pẹlu aarẹ Russia, Vladimir Putin, ju ohun to fi n han nita lọ.
Ṣugbọn ṣaa, Trump ti figba kan dide si orọ Boko Haram ni Naijiria, lati ran orilẹede naa lọwọ,.
"Nigba ti Barack Obama n ṣe'jọba, awọn ọmọ Niijiaira ti wọn tun jẹ ọmọ America bẹ ẹ titi lati ran wọn lọwọ, ṣugbọn ko dahun, ko ra nnkan ogun fun wọn. Nigba ti awọn eeyan wa ni Naijiria n koju ikọlu Boko Haram,Trump lo dide to ra awọn ọkọ ofurufu Tucano fun wọn lati koju ija naa, to si jẹ ki ikọ tiwa naa lagbara si i,"
Aṣofin tẹlẹ, Ehiozuwa Johnson Agbonayinmma lo sọrọ yii nipa Trump fun ẹka iroyin Vanguard.
Bakan naa ni ogun abẹle to n lọ ni Sudan, eyi to ti bẹrẹ lati oṣu mejidinlogun sẹyin, to si ti pe ẹgbẹẹgbẹrrun eeyan.
Ṣugbọn ko ti i si ẹni to ri aridaju ohun ti Trump yoo ṣe to ba gba ọpa aṣẹ ijọba lọfiisi aarẹ ilẹ America.
Gẹgẹ bi Mr Moore ṣe wi: " Iṣesi Trump yatọ ninu ohun gbogbo. Fun idi eyi, a gbọdọ reti nnkan tuntun, o le ma jẹ nnkan daadaa o, ṣugbọn nnkan tuntun yoo ṣẹlẹ ṣaa."















