Donald Trump: Àlàyé nípa ìdílé Ààrẹ Amẹrika tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Ana Faguy
    • Role, BBC News, Washington
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ṣaaju ko to wọ inu oṣelu ni Donald Trump ti jẹ oniṣowo, to si ni owo rẹpẹtẹ.

Lara awọn dukia rẹ ni oniruru ileeṣẹ ati ọpọlọpọ ile.

Ni bayii, orukọ Trump ti di gbajumọ kakiri agbaye, paapaa ninu ẹgbẹ oṣelu Republican.

Yatọ si Trump funra rẹ, ọpọ awọn mọlẹbi rẹ lawọn naa ti di gbajumọ ati alagbara nilẹ Amẹrika.

Donald Trump Jr

Donald Trump Jr

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Akọbi Trump, Donald Trump Jr, ti n ṣiṣẹ takuntakun lati igba ti baba rẹ ti kuro nile ijọba, White House.

O ṣiṣẹ takuntakun pẹlu awọn ileeṣẹ iroyin lasiko ti wọn kede JD Vance gẹgẹ bii igbakeji baba rẹ, nibi to ti sọ pe Vance kii ṣe aṣimu igbakeji baba oun.

O jẹ ki gbogbo aye mọ pe inu oun dun bi wọ ṣe yan JD Vance.

Orukọ iyawo rẹ akọkọ ni Vanessa Trump ki aarin wọn to daru, ni bayii Kimberly Guilfoyle ni iyawo afẹsọna rẹ tuntun.

Eric Trump

Eric Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eric lo wa ni ipo kẹta awọn ọmọ Trump, iroyin si sọ pe o maa n ba baba rẹ sọrọ nipa awọn nnkan to n fẹ ko ṣe.

Kii ṣe ẹnikan to fẹran lati maa wa ninu iwe iroyin gẹgẹ bii ẹgbọn rẹ, Donald Trump Jr amọ kii ṣe ọmọde nidi owo idile Trump.

Ivanka Trump ati Jared Kushner

Ivanka Trump ati Jared Kushner

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ivanka Trump ati Jared Kushner lo gbajumọ julọ ninu idile Trump lasiko ijọba rẹ akọkọ ni White House.

Ọdun 2009 ni wọn ṣe igbeyawo, wọn si bi ọmọ mẹta.

Lasiko ijọba Trump akọkọ, ọpọ igba ni Ivanka maa n ṣoju baba rẹ lawọn ibi ti ko le lọ.

Ni ti ọgbẹni Kushner, o di ipo olubadamọran agba mu ninu ijọba Trump laarin ọdun 2017 si ọdun 2021.

Tiffany Trump

Tiffany Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Tiffany Trump ni ọmọ Trump kẹrin, ati ọmọ kan ṣoṣo ti iyawo rẹ keji, Marla Maples bi fun un.

Ko ko ipa kankan ninu ipolongo ibo baba rẹ bẹẹ ni ko ṣiṣẹ ninu ijọba rẹ.

Ọdun 2022 lo ṣe igbeyawo pẹlu Micheal Boulos.

Idile Trump

Kimberly Guilfoyle

Kimberly Guilfoyle

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kimberly Guilfoyle ati Donald Trump Jr ti wa papọ fun ọdun mẹfa gbako lẹyin ti wọn gbe ara wọn gẹgẹ bii afẹsọna lọdun 2020.

Ileeṣẹ iroyin Fox News ni Kimberly n ba ṣiṣẹ laarin ọdun 2006 si 2018 ko to kuro nibẹ to si darapọ mọ ẹgbẹ “pro-Trump super PAC,’” to jẹ ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Trump.

O jẹ ẹnikan to maa n sọrọ ni gbangba nipa atilẹyin rẹ fun Trump, paapaa lori ẹrọ amohunmaworan.

Ni ibẹrẹ ọdun 2000 lo ṣe igbeyawo pẹlu goonina ipinlẹ California, Gavin Newsom.

Lara Trump

Lara Trump

Oríṣun àwòrán, EPA

Lara ni iyawo Eric Trump, o si wa lara igbimọ ẹgbẹ oṣelu Republican gẹgẹ bii ọkan lara awọn alaga ẹgẹ naa.

Ninu oṣu Keje ọdun yii, o sọrọ nibi ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu naa nibi to ti sọrọ rere nipa baba ọkọ rẹ, Donald Trump.

Melania Trump

Melania Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Melania ni iyawo Donald Trump, wọn si ti ṣe igbeyawo lati ọdun 2005.

Lasiko ijọba Trump akọkọ, o gbiyanju lati gbe ara rẹ pamọ, o si yẹra fun awọn akọroyin fun ọpọ igba.

Ninu oṣu Keje, o yọju sibibi ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu Republican lẹyin ọjọ diẹ ti agbẹbọn kan fẹ gbẹmi ọkọ rẹ, eyii to ya ọpọ eeyan lẹnu.

Ninu iwe kan to kọ, o sọ pe oun ko faramọ ki obinrin maa ṣẹyun.

Ọmọ kan ṣoṣo lo bi fun Trump, orukọ ọmọ ọdun mejidinlogun naa ni Barron Trump.

Barron Trump

Barron Trump ati baba rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Baron Trump ko yọju sita lọpọ igba lasiko ipolongo ibo Trump.

Ninu oṣu Karu un, iroyin ni yoo wa lara awọn aṣoju sibi ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu Republicans amọ lẹyin naa ni iya rẹ sọ pe oun ko nifẹ ati yọju sibẹ.

Ile ẹkọ Oxbridge Academy to wa ni Palm Beach lo ti kẹkọọ ko to darapọ mọ Stern School of Business ni fasiti New York.

Kai Trump

Kai Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kai ni akọbi awọn ọmọ-ọmọ Trump ati ọmọ akọbi Trump, iyẹn Donald Trump Jr.

Ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa sọrọ nibi ipade gbogbogbo ẹgbẹ oṣelu Republican, nibi to ti ṣalaye irufẹ eeyan ti Trump jẹ gẹgẹ bii baba-baba oun.