Bí Trump ṣe wọlé ìbò ààrẹ Amẹ́ríkà, wo ipa tí yóò ní lórí Naijiria àti Áfíríkà
Donald Trump ti fitan balẹ lẹẹkeji pẹlu aṣeyọri rẹ to sọ ọ di aarẹ America lẹẹkan si i bayii.
O ti fi ẹyin Kamala Harris janlẹ ninu ibo aarẹ.
Ninu ọrọ aṣeyọri rẹ kan to sọ ni Florida, Trump sọ pe awọn eeyan America ti fun oun ni "agbara ti ko siru rẹ ri"
“ Igba ọtun gan-an ree fun America".
Trump lo sọ bẹẹ fun ọpọ ero ti wọn n ṣugbaa rẹ lalẹ ọjọ ibo, leti okun West Palm to wa ni Florida.
Gbogbo eeyan lo ti mọ pe ipadabọ Trump sile ijọba America lẹẹkeji yii yoo yi eto to wa fun awọn ajoji pada.
Eyi ri bẹẹ nitori Trump funra rẹ ti leri awọn ayipada ti ko ṣẹlẹ ri, ẹru si ti n ba awọn orilẹede kan lagbaaye.
Donald Trump polongo ibo rẹ pẹlu ileri pe ilẹ America ni yoo ṣaaju ninu ohun gbogbo.
O ni ko si aaye fun ayọjuran okoowo ti awọn orilẹede kan n ba kiri. "America ni akọkọ. "
Bi Trump ṣe waa wọle yii, awọn amoye ti ṣe alakalẹ itumọ America ni akọkọ ti ọkunrin naa wi, ati ohun to le ba de fun Naijiria.
'America ni àkọ́kọ́'
Awọn amoye to ba BBC sọrọ lori ohun ti Trump sọ yii, ṣalaye pe itumọ rẹ le jẹ pe ki ọlọmu da ọmu iya ẹ gbe.
Wọn ni o le tumọ si pe ko ni i si iranlọwọ owo, atilẹyin ati aabo mọ fun awọn orilẹede mi-in.
Ki kaluku tọju ara wọn funra wọn.
Loootọ ni ilẹ Africa le ma jẹ awọn oludije ipo aarẹ America logun, ṣugbọn ibo America maa n wa lọkan ọpọ ilu kaakiri ni.
Koda, Aarẹ Bola Tinubu gan-an sọ fun Trump ninu iṣe ikini ku oriire rẹ, pe oun fẹ ki ajọsẹpọ America ati Naijiria nipọn si i.
Tinubu ni oun fẹ ki ajọṣepọ ti yoo mu ọrọ aje wa dagba waye, ki alaafia si wa.
Trump ko wa silẹ Africa ni saa rẹ akọkọ titi to fi tan, eyi si jẹ kawọn eeyan maa sọ pe ko fẹẹ ba ilẹ Adulawọ ṣe.
Bakan naa lo pe ilẹ Africa lorukọ abuku (Shitholes) ni 2018. Ṣugbọn o pada sọ pe oun ko lo iru ede bẹẹ fun ilẹ naa.
Ṣugbọn ni bayii ti Trump tun ti ni anfaani lati di aarẹ pada, ireti awọn to n woye rẹ ni pe yoo yi nnkan pada lẹka okoowo, ilera, aabo, ọrọ aje ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Pẹlu akọsilẹ awọn ọrọ ti Trump ti sọ lati 2017 de 2021, eyi ni awọn ohun to ṣee ṣe ki ijawe olubori rẹ ni fun Naijiria ati Africa lapapọ

Oríṣun àwòrán, Getty image
Dídá àwọn èèyàn tí kò ní àṣẹ láti gbé America padà sí orílẹ̀èdè wọn:
Trump ti kede lasiko ipolongo ibo rẹ, pe oun yoo le awọn eeyan ti ko ni aṣẹ lati gbe America pada si ilu wọn.
O loun yoo le wọn to bẹẹ ti iru rẹ ko ni i si ninu itan.
Naijria gbọdọ mọ pe ofin to de irinna wọ America yoo le si i pẹlu Trump to gbajọba yii.
Ofin to de awọn arinrinajo ni Trump fi lewaju, gẹgẹ bo ṣe ṣe ni 2016, nigba ti ọrọ akọmọna rẹ jẹ, “Build di wall”. Iyẹn fi ààlà si i.
O leri lati di aala to so America ati Mexico pọ, iyẹn lasiko iṣakoso rẹ akọkọ.
Bakan naa ni Trump ti sọ pe ọmọ awọn arinrinajo ti ko lorukọ lọdọ ijọba America ko ni i le di ọmọ oniluu
Nigba to n ṣalaye ọrọ yii, Ọjọgbọn Toba Alabi, lati ile iwe ẹkọṣẹ Ologun, Nigerian Defence Academy, sọ pe o tọ ki ẹru maa ba awọn ọmọ Naijiria ati awọn ọmọ orilẹede miran ti wọn ko ba ni iwe igbelu l’America.
Ọjọgbọn Alabi sọ pe wiwọle pada Trump to ohun ti yoo ko wọn lọkan soke.
O ni ofin Trump ko ni itumọ meji fun ọmọ Africa, ju ki wọn jokoo si ilu wọn lọ.
Ki wọn tun ilu tiwọn naa ṣe, ki wọn si maa gbe nibẹ, nitori America ko si fun ẹlomi-in ju awọn ọmọ America lọ.
Ọrọ̀ ajé:
Ọjọgbọn Alabi ṣalaye pe aṣeyọri Trump yoo nipa lara ilẹ Africa to ṣẹṣẹ n gunke agba.
O ni eyi yoo ri bẹẹ nitori ero America ko jọ ti ilẹ Africa.
Bi apẹẹrẹ, bi Naijiria ba n pese ọkọ ayọkẹlẹ, ẹrọ amohumaworan ati awọn nnkan mi-in, ta a ni yoo ra mọto ni awọn apa ibo miran mọ? Ọjọgbọn Alabi lo beere bẹẹ.
" Idagbasoke ilẹ Africa tako ohun ti awọn ilu to ti gunke agba n fẹ" Ọjọgbọn Toba Alabi lo fi kun un bẹẹ.
O ni awọn ti wọn n sọ nipa BRICS le pada kabaamọ rẹ, nitori ko si orilẹede ti yoo fi tiẹ silẹ, ti yoo maa ba ilu oniluu gbero bi yoo ṣe dide.
Ọjọgbọn Alabi ni ki awọn ọmọ Naijiria ma reti nnkan gidi lọwọọ Trump, nitori ero rẹ ko ba ti Africa mu.
" Awọn ajọ ayanilowo bii IMF ti awọn ọmọ ilẹ Adulawọ n sa tọ fun iranwọ, imunisin lati ọdọ awọn ilu to ti gunke agba naa ni. ‘’Wọn o le ran orilẹede kankan lọwọ lati dide.
‘’Ẹyin naa ẹ wo o gbogbo ilana ti wọn n la kalẹ, bii ki wọn pin orilẹede, bii ki wọn yọ sọbsidi lori awọn nnkan to ṣe pataki, bii ki wọn sọ ẹka ijọba di aladaani.
‘’Ìṣẹ́ atio oṣi to wa niluu ni wọn n gbe soke, ki i ṣe ọrọ aje."
Bayii ni Ọjọgbọn Toba Alabi wi.
Ṣaa, Donald Trump ṣeleri lati mu ẹka agbara gbooro si I, lati ṣi ọna epo si i, eyi to ni yoo mu owo rẹ walẹ.
Okòòwò:
Ohun kan to tun jẹ gbogbo agbaye logun bayii ni owo ti Trump yoo fi kun owo ori to n wọle lori awọn ọja to ba wọle.
Ki I ṣe awọn orilẹede bii China nikan, bi ko ṣe gbogbo ẹka ti wọn ti n pese nnkan eelo bii ẹrọ ifọṣọ kaakiri, pẹlu awọn nnkan eelo miran.
Donald Trump leri lati fi owo ori kun gbogbo nnkan ni gbogbo ẹka.
Yoo ṣe eyi gẹgẹ bo ṣe wi lati koju China, ki nnkan kan ma si le ṣe agbara dọla.
" Owo ori ni ọrọ to rẹwa ju, irinṣẹ ni, ọna ati ba ẹgbẹ pe ni. "
Trump lo sọ bẹẹ. O si ni oun yoo lo o ninu iṣakoso oun.
Donald Trump ti gbe aba owo ori kalẹ, lati ida mẹwaa si ogun lori awọn ọja ilẹ okeere, pẹlu eyi to ba wa lati China, ti owo ori rẹ yoo pọju, ti yoo jẹ ida ọgọta (60%)
Trump sọ pe ọna toun fẹẹ gba lati gbe awọn onileeṣẹ labẹle ga ree, yatọ si keeyan ṣẹṣẹ maa wa nnkan ilẹ okeere kiri.
Ìbáṣepọ̀ akọ sí akọ, abo sí abo (LGBTQ+)
Orilẹede Naijiria ko faramọ ibalopọ ọkunrin ati ọkunrin, tabi obinrin si obinrin.
Trump naa sọ ni saa akọkọ rẹ, pe oun ko faramọ ohun to ba jọ bẹẹ.
Bakan naa lo sọ ninu fidio kan to ṣe lasiko ipolongo ibo rẹ ni 2024 yii.
O loun yoo fopin si ajọṣepọ yoowu to ba kan akọ si akọ, abo si abo, tabi ki eeyan jẹ ọkunrin, ko sọ ara rẹ di obinrin.















