"Saheed Osupa ló mú ẹ̀bùn orin jáde lára mi, bí mo ṣe mú tóònù orin rẹ̀, inú ẹgbẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ ni mo wà"

Àkọlé fídíò, Oosa Fuji: Ohun orin Saheed Osupa nìkan ni mo mọ̀ọ́ kọ jù, kékeré ni mo ti ń gbọ́ ọ
"Saheed Osupa ló mú ẹ̀bùn orin jáde lára mi, bí mo ṣe mú tóònù orin rẹ̀, inú ẹgbẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ ni mo wà"

Ori ko ba mọ isẹ asela ni ọrọ itan aye gbajumọ akọrin Fuji, Sharafadeen Akanbi, ti gbogbo aye mọ si Oosa Fuji jẹ.

Ilu Ilrin lo fi se ibugbe, ti ko si lero pe oun le di gbajumọ akrin Fuji.

Amọ ayanmọ ko le tase, lo mu ko dara pọ ẹgbẹ ololufẹ Saheed Osupa.

Bi o tilẹ jẹ pe kekere lo wa, to ti n gbọ orin Saheed Osupa amọ ko mọ pe oun ni ohun orin bii ilumọọka akọrin Fuji naa.

Sugbọn oriire, lo gbe alawo re ko Oosa Fuji nigba to se alabapade Saheed Osupa, ẹni se awari ẹbun Fuji jade lara rẹ.

Oosa Fuji ba BBC Yoruba sọrọ lori bo se rinrin aye rẹ ati bi ori se gbe àde oloore.

Sharafadeen Akanbi – Oosa Fuji

"Bi mo se n kọrin ni ọjọ yẹn, Saheed Osupa beere pe ta lo n kọrin ti ohun rẹ dabi ẹni pe oun gangan ni oun n kọrin?"

Oosa Fuji, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye bi ori se gbe pade gbajugbaja akọrin Fuji, Saheed Osupa.

"Nigba ti maa bẹrẹ orin, funra Osupa gan lo sọ fun mi pe ki n maa kọrin, pe maa bẹrẹ orin.

A pade nigba ti mo ri ẹgbẹ awọn ololufẹ Saheed Osupa, eyiun Saheed Osupa Fans Club.

Lẹyin awọn ipade wa, wọn ti ni pe ẹni to ba mọ orin Saheed Osupa kọ, ko dide ko kọ ọ.

Bi mo se n kọrin ni ọjọ yẹn, n ko mọ pe Saheed Osupa gan wa ninu ile, bi wọn se jade niyẹn, ti wọn ni ọmọ wo lo n kọrin, ti ohun rẹ dabi ẹni pe awọn gangan ni awọn n kọrin?

Lati igba yẹn ni wọn ti sọ fun mi pe awọn ri ẹbun yẹn lara mi, pe ki emi naa maa kọrin.

Igba akọkọ ti maa kọkọ pade Saheed Osupa niyẹn."

"Ohun orin Saheed Osupa ti mọ mi lara, orin rẹ nikan ni mo mọọ kọ ju, ti mo maa n kọ daradara"

Oosa Fuji tun salaye bo se nifẹ orin Saheed Osupa lati kekere ati idi to se dara pọ mọ ẹgbẹ ololufẹ akọrin Fuji naa.

"Ohun to mu mi dara pọ mọ ẹgbẹ ololufẹ Saheed Osupa pọ gan, n ko le ka a tan, tori lati kekere, orin Barrister ni baba mi maa n gbọ julọ.

Nigba ti mo wa n dagba bọ diẹ diẹ, mo ri pe wọn ti n gbọ Saheed Osupa, lati igba naa si ni mo ti fẹran Saheed Osupa gan.

Mo ti wa pinnu pe ti mo ba ri ẹgbẹ ololufẹ Saheed Osupa nilu Ilorin, maa dara pọ mọ wọn.

Ohun to si mu mi darapọ mọ ẹgbẹ naa ni pe ọgbọn ti mo n kọ ninu orin Saheed Osupa pọ gan.

Ohun orin Saheed Osupa ti mọ mi lara, orin rẹ nikan ni mo mọọ kọ ju, ti mo maa n kọ daradara.

Tori naa, o wa rọ mi lọrun pe ti emi naa ba mu orin Yoruba kan si meji, ti mo ba jan papọ, ohun orin Saheed Osupa nikan lo rọrun fun mi julọ lati fi gbe orin naa kalẹ.

Ti mo ba lo toonu orin ẹlomiran, ko ni mu, lo fi dabi ẹni pe ohun orin Saheed Osupa nikan ni mo yan laayo, pe ki n maa tẹle."

Oosa Fuji

"Ọpọ eeyan to n wo Saheed Osupa lati ọọkan, maa n ro pe o buru, o ni agidi sugbọn ti ẹ ba sun mọ wọn, iwa rẹ dara gidi."

Oosa Fuji wa salaye iru eeyan ti Saheed Osupa jẹ ati iyatọ to wa laarin orin awọn mejeeji bi o tilẹ jẹ pe ohun wọn jọra.

"O le koko ki eeyan maa wo awokọse ẹnikan tori eeyan lee ma le gbe orin kalẹ bi olorin se gbe kalẹ nitori ẹbun ni orin.

Se ẹ mọ pe ẹbun ni orin amọ mo se oriire pe ẹni ti mo fi se awokọse gan lo ri ẹbun naa lara mi, to si sọ fun mi pe ọna mi ni kinni yii, maa se.

Saheed Osupa jẹ ẹda kan to se pe ti eeyan ba n wo lati ọọkan, ọpọ eeyan maa n ro pe o buru, o ni agidi sugbọn ti ẹ ba sun mọ wọn, iwa wọn dara gidi.

Ọga maa n sọ fun awa pe gbogbo rẹ, eremọde ni

Loni yii, Alhajai Osupa maa n wọnu ile Pasuma, ti Pasuma naa si maa n wọ inu ile ọga wa.

Imọran mi fawọn ololufẹ Fuji ni pe ka se ara wa ni ẹyọ kan

Boya ẹnikan gbe ẹ lati ilẹ, boya o ti wa ri ara rẹ bii ẹi pe o ti to bakan, o pada wa lọ n gara si ẹni yẹn, o nifẹ ẹni naa to ni."

"Mo ti lọ si orilẹede to to marun si mẹfa nidi isẹ orin yii naa ni"

Gbajumọ akọrin Fuji naa wa sọ ọpọ oore ti Oluwa se fun lati ara isẹ orin Fuji to n kọ bii ti Saheed Osupa.

"Lẹnu igba ti a bẹrẹ isẹ orin yii naa, mo ti lọ fun irinajo orin kikọ lawọn orilẹede to wa ni ẹkun iwọ oorun Afrika.

Mo ti lọ si orilẹede to to marun si mẹfa nidi isẹ orin yii naa ni.

Ninu aanu Ọlọrun, a ti ri ẹni to fẹ ran mi rinrin ajo lọ si Ummurah

Wọn n se bẹẹ fun wa, kii se awa ni wọn n fun amọ tori ifẹ ti wọn ni si Alhaji Saheed Osupa, ni wọn n fihan fun wa.

Awọn ti wọ̀n n fẹ Osupa, naa ni wọn n fẹ awa."