Awakọ̀ èrò dáná sún òṣìṣẹ́ LASTMA l‘Eko, ọ̀rọ̀ di bóòlọ yàgò fún mi

Aworan lati ninu fọnran to wa lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iṣẹlẹ a gbọ yanu waye nipinlẹ Eko nigba ti awakọ bọọsi ero danu sun oṣiṣẹ ajọ to n mojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA atri bọọsi rẹ.

Ninu fọnran kan to gba ori ayelujara ni ati ri bi ina se mu awakọ bọọsi, oṣiṣẹ LASTMA ati bọọsi ero naa.

Ohun to fa ariyanjiyan laaarin awakọ naa ati oṣiṣẹ LASTMS ni a ko le fidi rẹ mulẹ sugbọn LATMAS ti fi atẹjade sita lori opo ayelujara X pe otitọ ni iṣẹlẹ naa waye .

“Oṣiṣẹ LASTMA farapa yanayana, tawọn akẹgbẹ rẹ si gbe lọ si ile iwosan fun itọju”

Gẹgẹ bii atẹjade naa ṣalaye, LASTMA ni iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Cele lọ ọna Mile 2 lẹyin ti awọn oṣiṣẹ LASTMA da ọkọ ero naa duro fun ayẹwo.

“Iroyin nipa iṣẹlẹ to waye to de ọdọ wa, ti a si ti ri fọnran bi awakọ bọọsi Volkswagen T4 pẹlu nọmba idanimọ LSD355 CK se dana sun ọkọ rẹ ati oṣiṣẹ LASTMA nigba to n gbiyanju lati ma jẹ ki wọn mu oun.

“Isẹlẹ yii waye ni Ọjọ Karun un Oṣu kẹrinla ọdun 2024. A da ọkọ naa duro nitori o ti tapa si ofin oju opopona ni agbegbe Mile 2.

“Nigba ti a fẹ mu, awakọ naa bẹrẹ si ni lo agidi , to si da epo bẹntiroolu si ara oṣiṣẹ LASTMA, to si gbana.

“Oṣiṣẹ LASTMA naa farapa yanayana , ti awọn akẹgbẹ si sure gbe lọ si ile iwosan fun itọju.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post