Bobrisky ṣàlàyé ìdí tó fi kúrò ní Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bobrisky
Ọkunrin to n mura bi obinrin, Idris Okuneye, ẹni ti ọpọ mọ si Bobrisky ti kuro lorilẹede Naijiria lẹyin ọjọ diẹ to gba itusilẹ kuro ni ọfisi ajọ to n gbe ogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC.
Bobrisky gbe fọnran bi o se n kuro lorilẹede Naijiria sori ayelujara, to si n se idagbere fun awọn ololufẹ rẹ.
“Mo ma ri yin pada laipẹ. Mo ti ra tikẹẹti toto milọnu ọna ọgbọn naira.”
Ninu fọnran mi, Bobrisky ṣafihan iwe irinna rẹ lọ

Oríṣun àwòrán, Bobrisky/Instagram
Bẹẹ ba gbagbe, Ajọ EFCC fidi rẹ mulẹ pe awọn tun ti fi ṣikun ofin mu Idris ‘Bobrisky’ Okuneye lọsẹ to kọja.
Awọn iroyin kan gbode pe EFCC mu Bobrisky ni papakọ ofurufu ilu Eko lasiko to fẹ rinrinajo lọ soke okun.
Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale, lo sọ fun BBC pe lootọ ni awọn ti mu Bobrisky.
Lẹyin o rẹyin ni Ajọ EFCC gba beeli ‘Bobrisky’ lẹyin to ni oun ko fun eyikeyi ninu oṣiṣẹ rẹ ni riba owo ti iye rẹ to miliọnu marundinlogun naira.
“Igba mẹta ọtọọtọ ni mo ra tikẹẹti pe mo fẹ rin irinajo, igba kan pere ni mo ni anfani lati lọ"
Nigba to n ṣalaye idi to fi kuro lorilẹede Naijiria, Bobrisky ni oun nilo isinmi lọwọ gbogbo ohun ti oun ti lakọja lọwọ awọn ẹsọ alabo.
“Bẹẹ ni, mo le fi idi rẹ mulẹ pe mo ti kuro ni Naijiria fun igba diẹ. Mo ni lati mojuto ilera mi.”
Bakan naa ni Bobrisky rọ ileeṣẹ baalu KLM pe ki wọn da owo tikẹẹti ti oun san, eyi to pe N9.8m ni igba mẹta pada.
“Awọn oṣisẹ alabo kan fẹ fi aye su mi sugbọn mo ni Ọlọrun.
“Igba mẹta ọtọọtọ ni mo ra tikẹẹti pe mo fẹ rin irinajo, to si jẹ pe igba kan ni mo ni anfani lati lọ.
“KLM, mo lero pe ẹ da owo mi tikẹẹti igba meji ti n ko lo pada . Mo mọ pe ki n ṣe ẹjọ yin.”















