Màmá gbajúgbajà olòótú eré Kunle Afolayan jáde láyé lẹ́ni ọdún 81

Kunle Afolayan ati mama rẹ to doloogbe

Oríṣun àwòrán, KUnle Afo/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu mama Omoladun Afolayan ti i ṣe iya gbajugbaja olootu ere ati oṣere tiata n ni, Kunle Afolayan, lọ lẹni ọdun mọkanlelọgọrin.

Kunle Afolayan fun ra rẹ lo kede iku mama loju opo Instagram rẹ lọjọ Abamẹta.

Oriṣiiriṣii fọto ni gbajugbaja olootu ere naa fi kede iku mama rẹ to fi mọ aworan ti mama ya pẹlu awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ.

Ọgbẹni Afolayan sọ loju opo Instagram rẹ pe ‘’o nira lati gba wi pe mama ti lọ ibi agba re, amọ, mama gbe igbe aye rere.

Mama wa, maami Omoladun Ayanladun ti lọ sinmi.

Ọpọ ọmọ ati ọmọ-ọmọ lo gbẹyin mama,’’ Kunle Afolayan wa rọ awọn eeyan lati fi ẹbi wọn sinu adura lasiko ti mama fi ẹbi naa silẹ yii.

O tun gbadura wi pe ọmọ rere ni yoo gbẹyin ‘’gbogbo wa.’’

Aburo rẹ, Gabriel Afolayan, naa ṣedaro mama wọn to ti re iwalẹ asa, o ni ‘’a ti padanu mama wa ọwọn.

Mama, a o maa ṣafẹri yin, Iya Oyo, gbogbo wa ni a nifẹ ẹ yin.

Sun re o, maami, o digba o.’’

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post