Obìnrin tí wọ́n gé idọ rẹ̀ lásìkò ìdábẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ láti tún un ṣe
- Author, Bushra Mohamed
- Role, BBC News
- Reporting from, London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ìkìlọ̀: ìròyìn yìí ní àwọn àwòràń tó lè fa ìpòruru ọkàn
Ẹ̀rù ń bà mí nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ míì fún mi bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi náà ni mo fún wọn ní àṣẹ láti ṣe é .
Shamsa Sharaawe ń sọ̀rọ̀ nípa ìpinnu rẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ abẹ fún àtúnṣe idọ rẹ̀ tí wọ́n gé lásìkò tí wọ́n dábẹ̀ fún-un nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà.
Àwọn ẹbí rẹ̀ àti agbẹ̀bí kan ló dábẹ́ náà fún ní ilé wọn lórílẹ̀ èdè Somalia lọ́dún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sẹ́yìn.
Àwọn obìnrin tó lé ní mílíọ̀nù 230 ni wọ́n ti dábẹ́ fún káàkiri àgbàyé gẹ́gẹ́ bí ìjábọ̀ àjọ UNICEF kan ṣe sọ.
Ní ilẹ̀ Áfíríkà nìkan, ìjábọ̀ náà ní obìnrin tó lé ní ogóje mílíọ̀nù ló dábẹ́, èyí táwọn olóyìnbó ń pè ní Female Genital Mutilation (FGM).
Ní Somalia, Guinea àti Djibouti, ìdá àádọ́rùn-ún obìnrin tó wà níbẹ̀ ni wọ́n dábẹ́. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé dídábẹ́ fún ọmọ obìnrin kò ní jẹ́ kó já ìbálé rẹ̀, òhun tó ṣe pàtàkì ní àwọn orílẹ̀ èdè yìí.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló gbàgbọ́ ní Somalia pé ìbálé ọmọbìnrin àti ìdílé tó ti jáde ní àjọṣepọ̀ àti pé yóò kó iyì bá ẹbí rẹ̀.
Wọ́n máa ń rí àwọn obìnrin tí kò bá dábẹ́ bí obìnrin tí kò ní lè mú ara dúró fún ọkùnrin àti pé ó máa kó ìtìjú bá àwọn ẹbí rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Dr Adan Abdullahi
Shamsa sọ pé òun máa ń kojú ìnira lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí òun bá ń ṣe nǹkan oṣù òun lọ́wọ́ tí òun kò sì fẹ́ kojú irú ìnira bẹ́ẹ̀ mọ́.
Ní ọdún 2023, nígbà tó pé ẹni ọgbọ̀n ọdún, Shamsa lọ ṣèwádìí bóyá ó le ṣe iṣẹ́ abẹ láti fi mú àdínkù bá ìnira tó máa ń kojú kù.
Ní báyìí, ó ti ń gbé ní orílẹ̀ èdè UK, tó sì ń tako dídábẹ́ fáwọn ọmọbìnrin lórí ayélujára àti láti mọ àwọn obìnrin tó ń la irú ìṣòro bíi tirẹ̀ kọjá, kí wọ́n lè ṣe ìpolongo fún iṣẹ́ abẹ yìí.
Shamsa wòye pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ wà láti fi ṣàtúnṣe fáwọn obìnrin tí wọ́n dábẹ́ fún àti pé nítorí náà ni òun fi ń ṣe ìpolongo tí òun ń ṣe.
Iṣẹ́ abẹ láti ṣàtúnṣe idọ ọmọbìnrin tí wọ́n ti gé tẹ́lẹ̀ jẹ́ ọ̀nà láti jẹ́ kí idọ náà le lékún nínú iṣẹ́ rẹ̀, mú àdínkù bá ìrora tí obìnrin bẹ́ẹ̀ bá ń ní àti láti ri pé obìnrin bẹ́ẹ̀ ń gbádùn ìbálòpọ̀.
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwádìí, Shamsa ṣàwárí rẹ̀ pé orílẹ̀ èdè Germany ni wọ́n ti le ṣe iṣẹ́ abẹ t'òun, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìkówójọ fún iṣẹ́ abẹ náà lórí ayélujára níbi tó ti rí $31,000 (£25,000) gbà.
Nígbẹ̀yìn, Shamsa ná $37,000 (£30,000) fún ẹni tó bá tọ́jú ọmọ rẹ̀, ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí Germany àti láti ṣe iṣẹ́ abẹ náà.
Ó ṣàlàyé pé gbèsè ṣì wà tí òun máa san fún ilé ìwòsàn tí òun ti ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀hún àti pé òun kò tíì lè padà lọ fún ìtọ́jú lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ náà.

Oríṣun àwòrán, Dr Reham Awwad
Ṣíṣe iṣẹ́ abẹ
Oríṣìí abẹ́ dídá fún obìnrin mẹ́rin ló ní ìpalára tó lágbára. Àkọ́kọ́ ni èyí tí wọ́n bá gé díẹ̀ lára idọ tàbí gbogbo rẹ̀ kúrò. Ìkejì ni gígé idọ àti awẹ́ ojú ara obìnrin mọ́-ọn. Ìkẹta ni èyí tí wọ́n bá di ojú ara obìnrin pẹ̀lú awẹ́ ojú ara tí wọ́n bá gé tí ìkẹrin sì jẹ́ gígé idọ, awẹ́ ojú ara, ojú ara ìbímọ kúró. Ìkẹrin yìí ló burú jùlọ.
Láti ogún ọdún sẹ́yìn ni àwọn onímọ̀ ìlera ti ń gbìyànjú láti wá ọ̀nà tí wọn yóò fi mú àtúnṣe bá ìpalára tí dídábẹ́ ń ṣe fún obìnrin.
Ní ọdún 2004, dókítà Pierre Foldès ló kọ́kọ́ ṣe iṣẹ́ abẹ láti ṣàtúnṣe abẹ́ dídá fóbìnrin tí àwọn onímọ̀ sì ń ṣe ìwádìí nípa rẹ̀ láti ìgbà náà.
Àmọ́ ní ilẹ́ Áfíríkà táwọn obìnrin ti nílò iṣẹ́ abẹ náà jùlọ, ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ni kò ì tíì máa ṣé. Kenya àti Egypt nìkan ni wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà báyìí tó sì jẹ́ pé ẹni tó bá fẹ́ ṣe é ló máa san owó lápò ara rẹ̀.
Ní Yúróòpù, àwọn orílẹ̀ èdè kan ń ṣe iṣẹ́ abẹ náà ní owó péréte tó sì wà lábẹ́ ètò adójútòfò ní àwọn orílẹ̀ èdè bíi Belgium, Germany, France, Sweden, Finland àti Switzerland.
Dókítà Adan Abdullahi tó jẹ́ oníṣẹ́ abẹ ní Nairobi ní ọ̀pọ̀ dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ kọ́ ló ní ìmọ̀ nípa iṣẹ́ abẹ yìí àti pé ara obìnrin yàtọ̀ síra wọn.
Ó ní iṣẹ́ abẹ náà máa ń mú àdínkù bá ìnira táwọn obìnrin máa ń ní lásìkò ìbálòpọ̀ àti lásìkò ìbímọ.

Oríṣun àwòrán, Haja Bilkisu
'Ìnira púpọ̀ ni fún ara'
Hajia Bilikisu tó jẹ́ ọmọ Sierra Leone ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ abẹ láti fi ṣàtúnṣe abẹ́ rẹ̀ tí wọ́n dá ní kékeré. Ó ní ó dára kí èèyàn mọ nǹkan tí iṣẹ́ abẹ náà máa ṣe kí èèyàn tó le ṣe é.
ó ṣàlàyé pé ṣíṣe àtúnṣe idọ nìkan kọ́ ló ṣe pàtàkì, pé ojú ọgbẹ́ abẹ́ tí wọ́n dá fún obìnrin ṣì wà lára obìnrin míì títí tó fi dàgbà.
Ó wòye pé kìí ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ni abẹ́ dídá máa ń ṣe àkóbá fún, pé ó máa ń ní ipa lórí ọmọ bíbí náà.
Hajia Bilikisu ní iṣẹ́ abẹ náà le díẹ̀ nítorí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ni òun kò lè fi rìn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tí òun ṣe àti pé ọ̀pọ̀lópọ̀ ògùn ni òun ní láti máa lò.
Nítorí ìnira tí iṣẹ́ abẹ́ yìí le bí, àwọn dókítà kan ń pè fún lílo àwọn ìtọ́jú tí kò nílò iṣẹ́ abẹ.
Dókità Reham Awwad jẹ́ ọ̀kan lára àwọn dókítà tí wọ́n dá ilé ìwòsàn Restore kalẹ̀ ní Egypt lọ́dún 2020 láti máa ṣe ìtọ́jú àwọn obìnrin tí wọ́n dábẹ́ fún.
Dókítà Awwad ní òun tó mú òun dá ilé ìwòsàn náà kalẹ̀ kò ṣẹ̀yìn ìrírí òun nígbà tí òun ń kẹ́kọ̀ọ́ lórí ṣíṣe iṣẹ́ abẹ fáwọn obìnrin tí wọ́n ti dábẹ́ fún rí.
Ó ní ìgbà náà lòun ṣe àwárí rẹ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ abẹ máa ń mú ìdẹ̀kùn bá àwọn obìnrin kan, kìí ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń ṣiṣẹ́ fún àti pé òun kò rò pé gbogbo obìnrin ló nílò iṣẹ́ abẹ.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ìwòsàn tí àwọn ń ṣe ló jẹ́ pé kò nílò iṣẹ́ abẹ, táwọn sì ń rí dájú pé ẹ̀jẹ̀ ń ṣàn dé ibi tó yẹ.

Ara tuntun
Fún àwọn tó ṣiṣẹ́ abẹ, èsì rẹ̀ jẹ́ nǹkan tó máa ń mú wọn lọ́kàn.
Hajia láti Sierra Leone ní ó gba òun ní àkókó díẹ̀ kí ó tó mọ́ òun lára pé nǹkan ti yàtọ̀ lára òun.
Ó ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nígbà tí òun rí idọ náà fún ìgbà àkọ́kọ́ nítorí kò jọ èyí tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Shamsa náà ní pẹ̀lú gbèsè tí òun jẹ, inú òun dùn pé òun ṣiṣẹ́ abẹ náà.
Ó ní òun máa kọ́ láti gbé pẹ̀lú idọ tuntun tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.
“Nísìn-ín ni mò ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ bó ṣe rí láti jẹ́ obìnrin pípé.”









