Èyí ni bí ìbò ilẹ̀ America se lè ní ipa lóríi gbogbo àgbáyé

Nigba ti Aarẹ ilẹ America, Joe Biden, lọọ ṣabẹwo ojiji si ojugba rẹ, Volodymyr Zelensky ni Ukraine loṣu keji ọdun 2023, eyi to fi kede atilẹyin fun aarẹ naa, niṣe ni awon ọkọ to tẹle e n ke tantan. Abewo naa ni itumọ, Biden funra rẹ si pada sọ pe “America ni imọlẹ aye. ”
Ni bayii, gbogbo agbaye lo n reti ẹni ti yoo dari imọlẹ ọhun, bi awon eeyan America ṣe fẹẹ yan aarẹ tuntun ninu ibo ti wọn yoo di lọsẹ to n bọ yii. Ṣe Kamala Harris yoo maa tẹle ilana Biden lọ ni, pẹlu idaniloju to ni pe America ko le pada lẹyin oun, abi Trump to gbagbọ pe America lo ṣiwaju ko too kan gbogbo aye ni yoo di aarẹ?
Ohun to wa nilẹ bayii ti mu kawọn eeyan maa beere pe se agbara ti America ni lori gbogbo agbaye tẹlẹ naa ṣi wa nibẹ saa?
Awon alagbara ẹkun kọọkan ti n da lo agbara wọn, awọn apaṣẹ waa ti n da ẹgbẹ silẹ, bẹẹ ni ogun apanirun to n lọ lọwọ ni Gaza, Ukraine ati awọn ibo mi-in ti n jẹ kawọn eeyan maa beere ipa ti Washington n ni . Ṣugbọn ni ti America to ni ọrọ aje to daa ati ikọ ologun to duro rẹgi, o yẹ ka wo bi ibo wọn yii yoo se lo agbara lori aye, gẹgẹ bi awọn amoye ṣe ṣalaye rẹ.
Agbára ológun

“ Ki i ṣe asọdun, idaamu ni Donald Trump jẹ fun Europe, pẹlu bo ṣe n ke tantan si wa leti pe oun yoo pada lẹyin Nato”. Igbakeji akọwe tẹlẹ fun ẹgbẹ Nato,Rose Gottemoeller, lo sọrọ yii nipa Trump.
Owo ti ikọ alaabo Washington n na jẹ ida meji ninu eto iṣuna awọn Nato ati ọmọ ẹgbẹ mọkanlelọgbọn miran(31).
Yatọ si Nato, ilẹ America n nawo lori awọn ọmọ ogun ẹ gidi, debi pe bi a ba pa orilẹede mẹwaa mi-in pọ, titi kan China ati Russia, owo ti wọn n na lori ologun wọn ko to ti America nikan.
Bi Kamala Harris ba bori ninu ibo yii, Gottemoeller gbagbọ pe nnkan yoo ṣe ẹnu ire fun Nato lati ọdọ Washington. Ṣugbọn o fi ikilọ kan ti i, iyẹn naa si ni pe, o loun yoo ṣi maa ba Nato ṣiṣẹ ati ajọ European Union, ki iṣẹgun le waye ni Ukraine.
Ṣugbọn ikọ Harris nile ijọba yoo ni lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ile igbimọ, eyi to ṣee ṣe ko bo sọwọ awọn Republican laipẹ, ti ko si ni i fẹẹ maa ti ogun okeere lẹyin mọ bii alatako rẹ ti i ṣe Democrat.
Arabinrin Gottemoeller, sọ pe labẹẹ bo ti wu ko ri, “Emi o gbagbọ ninu ki Nato tuka, Europe ni yoo ni lati bọ siwaju dari.”
Ta a ni olùlàjà?
Ẹni to ba jẹ aarẹ America tuntun yoo ni lati koju ogun abẹle .
“Ilẹ America lo ṣi ni ẹnu ju lori aabo ati alaafia agbaye, ṣugbọn agbara rẹ lati ṣẹgun ọtẹ ati ogun ti dinku”. Comfort Ero, Aarẹ ati adari 'International Crisis Group,' lo ṣalaye bẹẹ.
“Ogun ki i pari kia mọ bayii, awọn ogun apanirun ko ṣee bori, nigba ti awọn alagbara agbaye n figa gbaga lati fi ajulọ han ara wọn. Awọn iṣi wẹwẹ agbara naa n lo tiwọn bo ṣe mọ,” Ogun bii ti Ukraine yẹn, awon agbara oriṣiiriṣii lo ko mọra, bẹẹ ni ti ọgbun Sudan naa, gbogbo wọn ni wọn n nawo s'ogun jura wọn lọ.
“Bi Kamala Harris ba wọle ibo yii, ilana iṣakoso to n lọ lọwọ naa ni yoo maa ba lọ. O loun ko fẹ ipaniyan, palapala bẹẹ gbọdọ duro.
To ba jẹ Trump lo wọle, o le fun Israel lagbara si i lorii Gaza atawọn ibo mi-in. O ti sọ ọ tẹlẹ pe oun le kọyin si Ukraine koun si ran Moscow lọwọ”
Bakan naa ni Trump pẹlu ti ni asiko ti to bayii ti alaafia yoo jọba, ti wọn yoo dẹkun ipaniyan. Ṣugbọn iroyin tun sọ pe o ti figba kan sọ fun Aarẹ Israeli, Benjamin Netanyahu, lati ṣe ohun to ba yẹ ko ṣe.
Trump n kede ara re bii olulaja, olufẹ alaafia. “ Mo maa ri i pe alaafia wa laaarin Ila-Oorun laipẹ,” Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu tẹlifiṣan Al Arabiya, ni Trump ti sọrọ yii lalẹ ọjọ Aiku.
O ṣeleri lati mu imugbooro ba adehun alaafia Abraham ti wọn ṣe ni 2020.
Adehun yii wa fun ki alaafia le wa laaarin Israel ati awọn orilẹede Arab kan, ṣugbọn oye foju han pe wọn yọ Palestine kuro lara awọn Arab naa, wọn si lọwọ si ogun to n lọ nibẹ ti ko sinmi.
Nipa Ukraine, Trump ki i fi bo pe oun fẹran awọn akikanju ọkunrin bii Vladimir Putin ti orilẹede Russia. O ti fi han gedegbe pe oun fẹẹ ki ogun pari ni Ukraine, pẹlu atilẹyin awon ṣọja to kaju ẹ lati America, pẹlu owo.
Trump sọ nipa Russia laipẹ yii nibi ipolongo rẹ kan pe, “Mo maa gba ẹ la, a gbọdọ jade ninu eyi” .

Ni idakeji, Kamala Harris ni tiẹ sọ pe: “ O wu mi lori lati duro ti Ukraine. Emi yoo maa tẹsiwaju lati ṣatilẹyin fun Ukraine. Ma a si ṣiṣẹ lati ri i pe Ukraine bori ogun yii.”
Ṣugbọn iwoye Arabinrin Ero, ni pe ẹni yoowu to ba bori ninu Harris ati Trump, nnkan ṣi le buru si i lagbaaye nipasẹ wọn.
Okòòwò pẹ̀lu Beijing
Ibudo okoowo agbaye ni Beijing ni China, gẹgẹ bi America ṣe jẹ alagbara.
Iwoye awọn Democrat ati Republican ni pe Beijing fẹẹ gba agbara lọwọ America lẹka okoowo
Ṣugbọn Ọgbẹni Mitter, ọmọ ilẹ Gẹẹsi, sọ pe oun ri iyatọ diẹ lara Harris. O ni ajọṣepọ America pẹlu China yoo daa si i bi Kamala ba bori ibo naa.
O ni ṣugbọn ti Trump ba wọle ibo yii, o le ma ri bẹẹ, nitori Trump ti sọ ọ ri pe oun lko e ṣatilẹyin fun erekuṣu to jinna si America.
Ni ti awọn olori China, igbagbọ tiwọn ni pe ati Harris ati Trump, awọn mejeeji ni yoo le.
Adarí tó ń fi ti ọmọnìyàn ṣe
Ẹni ti yoo fi ero ọmọlakeji sọkan bo ṣe n dari, ti yoo ni aanu awọn araalu ati agbaye, ti yoo si maa fi ti ọmọniyan ṣe ni awọn eeyan n wa pẹlu ibo yii. Ṣugbọn ta a ni ninu wọn .
Martin Griffiths, awoye awujọ to ṣẹṣẹ fipo akọwe ẹgbẹ UN silẹ, sọ pe oun ri imọlẹ yii bi Kamala Harris ba yege. O ni ireti ifọmọniyan ṣe wa.
Bi wọn ba dibo fun Trump gẹgẹ bi Griffiths ṣe wi, adanikanṣe ile aye ni yoo jẹ fun awọn eeyan America. O ni eyi yoo ko ba ọrọ aje gbogbo agbaye pẹlu.
Orilẹ ede America lo n fi owo silẹ ju fun ajọ UN lagbaaye, ni 2022, $18.1bn ni America nikan fun wọn (£13.9bn).
Ṣugbọn nigba ti Trump n ṣe saa rẹ akọkọ , o ki ọbẹ bọ bi wọn ṣe fun ajọ iṣọkan agbaye naa lowo, o ge e ku, o si yọ kuro ninu ajọ ilera agbaye( World Health Organisation). Awọn ẹlẹyinju aanu yooku ni wọn daamu lati maa fowo ranṣẹ si awọn ajọ yii, ohun ti Trumo fẹ ko ṣẹlẹ gan-an si niyẹn.
Ṣugbọ Griffiths tun sọ pe ijọba Biden ko karamaasiki wahala to n ṣẹlẹ ni aarin Ila-Oorun. O koro oju si ipaniyan Hamas ati ikọlu ọjọ keje, oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Bi America yoo ṣe ran awọn ti ogun n pa ni Gaza ati Lebanon lọwọ ni ohun ti jẹ awọn ajọ to n pe fun alaafia logun bayii.















