Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tún wọ́ VDM lọ ilé-ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, VDM
Ileeṣẹ Ọlọpaa ti wọ Martins Otse, ẹni tí ọpọ mọ si VDM lọ ile ẹjọ lẹyin ti wọn fẹsun pe o wọ aṣọ Ọlọpaa lai gba aṣẹ.
Saaju ni Agbẹjọro VDM, Deji Adeyanju kede pe ileeṣẹ Ọlọpaa ti VDM mọle ni alẹ Ọjọbọ.
Adeyanju ni ileeṣẹ Ọlọpaa ti VDM mọle lẹyin ti o jẹ ipe wọn.
"Onibaara mi, VDM ni Ọlọpaa ti tí mọle lẹyin to jẹ ipe ileeṣẹ Ọlọpaa niluu Abuja.
"VDM gbagbọ pe ọrẹ wa ni Ileeṣẹ Ọlọpaa bo ti lẹ jẹ pe wọn ko ki n ṣe ọrẹ wa."
Ninu atẹjade tí ileeṣẹ Ọlọpaa gbe sita, Ileeṣẹ Ọlọpaa ni awọn n se gbogbo nnkan lati ma jẹ ki abuku ta ba Ileeṣẹ Ọlọpaa paapa ni ọna ti ko ba ofin mu.
Bakan ni wọn rọ awọn araalu lati mọ nipa Igbẹjọ naa.
Ni ọsẹ to kọja, ileeṣẹ Ọlọpaa bu ẹnu atẹlu lu lilo aṣọ Ọlọpaa ni ọna ti ko ba ofin mu paapa bi VDM ṣe lo aṣọ naa ninu fọnran to gbe sori ayelujara.
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post












