Iran sọ onírúurú àdó olóró sí Israel, èèyàn mọ́kànlélógún farapa

Israel lẹyin ado oloro Iran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iro ado oloro ti dun lakọlakọ lorumọju laarin awọn ọmọ ogun Israle ati Iran.

Ṣaaju ni Israel ti kọkọ ju awọn ado oloro kan si awọn agbegbe ti Iran ti n ṣe awọn ohun elo alagbara nuclear ki Iran naa to tun da pada.

Awọn aworan lati Israel ṣafihan pe oniruru ado oloro lo n fo loke lorilẹede Isreel, eyii ti Iran fi ranṣẹ silẹ naa lẹyin ti Israel ti kọkọ kọlu u.

Lorumọju lawọn fere pajawiri bẹrẹ si n dun ni Israel, eyii to n ṣafihan pe ewu n bẹ loko longẹ, ti ọpọ awọn olugbe Israel si bẹrẹ si n lọ fi ori wọn pamọ.

Amọ ṣa, bi awọn ado oloro Iran ṣe n wọ Israel ni awọn ado oloro idaabobo Israel naa n pade wọn loju ofurufu lati ba awọn ado oloro naa jẹ ko to balẹ.

Ẹwẹ, bi Israel ṣe n ba lara awọn ado oloro ti Iran fi ranṣẹ jẹ loju ofurufu naa ni diẹ lara rẹ n balẹ si Israel.

Oniruru aworan ori ayelujara lo ṣafihan bi awọn aarin adugbọ se ri lẹyin ti awọn ado oloro naa balẹ tan.

Ileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Israle, MDA, ti sọ pe ko din ni eeyan mọkanlelogun to ti farapa lẹyin ikọlu Iran.

Israel lẹyin ado oloro Iran

Ninu atẹjade kan ti ileee naa fi lede loju opo X rẹ, o ni ọkan ninu awọn to farapa naa lo wa ni ẹsẹ ni kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Wayi o, ileeṣẹ eto abo Israel, Israel Defense Forces (IDF) ti sọ pe oun yoo tẹsiwaju ninu akọlu oun si Iran.

Ninu atẹjade kan, IDF sọ pe oun yoo tẹsiwaju lati kọlu Iran titi ti orilẹede naa ko fi ni lanfani lati maa dunkoko mọ Israel mọ.

Atẹjade naa tẹle awọn fidio ikọlu wọn ti wọn ya lati oju ofurufu.

Ọrọ yii lo n jade lẹyin ti Israel kọkọ kọlu Iran, ninu eyii to ti ṣekupa ọgagun Iran mẹta.

Amọ ṣa, titi di aarọ oni ọjọ Abamẹta ni Iran n fi ado oloro ranṣẹ si Israel.