Israel ṣèkọlù sí Iran, pa olórí ológun IRGC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Lana Lam
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Orílẹ̀ èdè Isreal ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Iran ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ẹtì.
Israel ní oríkò ohun ìjà olóró Iran ni àwọn ń gbìyànjú láti ṣe ìkọlù náà sí.
Àdó olóró Israel náà ṣekúpa olórí ológun Iran Islamic Revolutionary Guards Corps (IRGC) – tó jẹ́ ẹ̀ka ológun Iran tó lágbára - Hossein Salami.
Ní ìrètí ìkọlù padà láti Iran, Israel ti kéde ìlú ò fararọ ní orílẹ̀ èdè rẹ̀, tí wọ́n sì ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn láti lọ sí ibi tí ààbò wà.
Oílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní àwọn kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù yìí.
Ìkọlù ọ̀hún ṣàkóbá sáwọn ibi tí Iran ń kó àwọn nǹkan ìjà ogun sí.
Ìgbà àti àsìkò wo ni ìkọlù náà wáyé?
Ní nǹkan bíi aago méjì òru ọjọ́ Ẹtì ni àdó olóró ń dún lákọlákọ ní olú ìlú Iran, Tehran.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní Iran sọ pé àwọn ilé ìgbé wà lára àwọn ibi tí àwọn àdó olóró náà ṣe lọ́ṣẹ́ débi pé wọ́n gbọ́ ìkọlù náà ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Tehran. BBC kò lè fìdí èyí múlẹ̀ lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí ìkọlù àkọ́kọ́ wáyé ni wọ́n tún gbọ́ ìró àdó olóró míì ní agbègbè tí iléeṣẹ́ àdó olóró Natanz wà gẹ́gẹ́ bí iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé Iran ṣe sọ.
Ní Israel, ariwo ni wọ́n fi jí àwọn èèyàn dìde láti fi ta wọ́n lólobó lórí ìjàmbá tó le wáyé lẹ́yìn ìkọlù náà.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Kí ni Israel ti sọ?
Olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ pé ìkọlù náà, tó pè ní Operation Rising Lion jẹ́ ojúnà láti fi tẹ ìdúnkokò Iran rì láti mú kí Israel dúró dédé.
Ó ní ìkọlù náà yóò tẹ̀síwájú fún iye ọjọ́ tí yóò bá gbà wọ́n láti fi mú ìdúnkokò Iran kúrò.
"Láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ni Iran ti ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí wọn kò gbé rí, ìgbésẹ̀ láti mú kí uranium di ohun ìjà olóró.
"Tí a kò bá dá wọn lẹ́kun, Iran le pèsè àdó olóró tó lágbára láàárín ìgbà péréte. Ó le jẹ́ ọdún kan, àárín oṣù díẹ̀, tí kò ní tó ọdún kan. Èyí jẹ́ ohun tó léwu, tó sì lè ṣàkóbá fún Israel."
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Netanyahu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump fún bó ṣe kojú ètò nuclear weapon Israel.
Ọmọ ogun Israel kan sọ fún BBC pé Iran tin í àwọn ohun ìjà olóró tó lágbára tí wọ́n fi lè pèsè àdó olóró "nuclear bombs" láàárín ọjọ́ péréte.
Kí ni Iran sọ?
Agbẹnusọ fún iléeṣẹ́ ológun Iran kan sọ pé Amẹ́ríkà àti Israel yóò san ohun tí wọn kò rà lórí ìkọlù náà, gẹ́gẹ́ bí Reuters ṣe sọ.
Agbẹnusọ Iran, Abolfazl Shekarchi sọ pé àwọn máa dáhùn sí ìkọlù náà.
Kí ni Amẹ́ríkà sọ?
Akọ̀wé ìjọba Amẹ́ríkà, Marco Rubio sọ pé Amẹ́ríkà kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà àti pé àwọn kò ṣe àtìlẹyìn kankan fún Israel lórí rẹ̀.
Ó ní ohun tó jẹ àwọn lógún jùlọ báyìí ni báwọn ṣe máa dá ààbò bo àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó wà ní ẹkùn náà.
Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump kò ì tíì sọ ohunkóhun lórí ìkọlù náà.
Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè ní Australia, Penny Wong sọ pé àwọn ti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí lórí ìkọlù náà àti pé ìkọlù Israel yìí le ṣokùnfà ìdàrúdàpọ̀ ní ẹkùn tí nǹkan kò ti fararọ níbẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Kí ni ètò àdó olóró "Iran nuclear programme"?
Iran ní ètò nuclear programme náà wà fún ìlò aráàlù nìkan. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ káàkiri Iran èyí tí Israel ti ṣe ìkọlù sára wọn báyìí.
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè, tó fi mọ́ àjọ International Atomic Energy Agency ni kò gbà pé ilò abẹ́lé nìkan ní ètò náà wà fún.
Ní ọ̀sẹ̀ yìí, àjọ náà sọ pé kéde pé Iran tẹ òfin àjọ náà lórí ìpèsè àdó olóró náà mọ́lẹ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ láàárín ogún ọdún.
Wọ́n ní Iran kọ̀ láti fèsì lórí àwọn ohun èlò àdó olóró náà ti wọ́n kò kéde àti kíko uranium pamọ́.
Ìjábọ̀ àjọ ọ̀hún kan sọ pé Iran ní uranium tó le pèsè àdó olóró nuclear bomb mẹ́sàn-án.














