Ikú kan náà ló pa Abacha àti Abiola, ọkàn àwọn méjèèjì wú ni kí wọ́n tó jáde láyé - Al-Mustapha

Aworan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi orilẹede Naijiria ṣe n ṣe ayẹyẹ ijọba awarawa to ma n waye ni Ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdọọdun, Ọgagun Hamza Al- Mustapha to jẹ olori awọn ẹṣọ alaabo fun fun Aarẹ Ologun tẹlẹri lorilẹede Naijiria, to di oloogbe, Ọgagunagba Sani Abacha, ti sọ pe ọpọ nnkan lo waye ni ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdun 1993 ti oun yoo sọ sita lọjọ iwaju.

Bakan naa lo tun wọgile gbogbo ẹsun ti wọn ka si ọga rẹ lẹsẹ pe o lọwọ ninu laasigbo to bẹ silẹ lẹyin eto idibo ọdun 1993.

Ninu iwe rẹ, aarẹ Ologun tẹlẹri, Ọgagun Ibrahim Badamasi Babangida, fẹsun kan Ọgagun Sani Abacha pe o lọwọ ninu awọn ohun to fa wahala lasiko eto idibo aarẹ ọdun 1993.

Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC Hausa, eyi ni awọn ọrọ ti Ọgagun Hamza Al-Mustapha ba BBC sọ lori eto idibo June12 ọdun 1993 ati awọn nnkan mi to rọ ijọba awarawa.

Fifi ẹsun kan Abacha

Nigba ti BBC Hausa bi Ọgagun Hamza Al-Mustapha nipa ohun ti o le sọ nipa ẹsun ti Ọgagun Ibrahim Badamasi Babangida fi kan ọga rẹ Sani Abacha ninu iwe rẹ, o ni:

"... Nigba ti wọn gbe iwe naa sita, wọn ko fi iwe pe mi. N ko ti ka iwe naa, fun idi eyi n ko ni ohunkohun lati sọ. Boya lọjọ iwaju."

"Ọrọ June 12 le ju bi awọn eeyan ṣe ro lọ nitori wọn ko mọ ohun to waye. N ko ni sọ ohunkohun bayii," Al-Mustapha ṣalaye.

Ki lo ṣẹlẹ lasiko iṣejọba Abacha?

Nigba ti wọn bi Ọgagun Hamza Almustapha pe bawo ni ọga rẹ se jade laye, o ni:

"Ọrọ nla yii ni mo ti sọ ni igbimọ oluwadi Oputa. Bi Abiola ṣe ku naa ni Ọgagun Abacha ṣe ku, iyẹn ni pe ọkan wọn kan bẹrẹ ma wu kọja idanimọ."

Ẹsun jiji owo ilu ti wọn fi kan Abacha

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amugbalẹgbẹ tẹlẹ naa ni ko si nnkan to jọmọ pe Abacha lo ko owo kan pamọ si oke okun.

"Lasiko naa, ọpọ nnkan ni o waye ti a si dari ijọba pẹlu rogbodiyan ati wahala, ti ko dẹ tun si owo. A lọ si orilẹede Libya pẹlu ọpọ eeyan lati lọ wo bi wọn ṣe yanju ọrọ wọn nitori ofin ti de Libya fun igba pipẹ. Odindi ọdun mọkanla ni ofin fi mu Libya.

"Ọkan ninu ohun ta ṣe ni ka wa awọn ileeṣẹ aladani ti ijọba le ko owo fun lati ra ọja ti wọn ta fun araalu ni owo kekere, bi o ṣe wa ni Libya.

"A ṣe awọn nnkan wọnyi, a si dupẹ pe orilẹede Naijiria ko daru.

"Ṣugbọn nigba ti Abacha ku, to yẹ ki wọn da owo naa pada, ọpọ nnkan waye. Wọn bẹrẹ si ni ma fẹsun kan. N ko gbagbọ pe gbogbo awọn owo ti wọn gba pada ni wọn gba pẹlu orukọ Abacha.

"Ọpọ awọn araalu ni wọn fi owo wọn ṣowo lati mu irọnu ba Naijiria. Awọn kan gba ti wọn pada, ti awọn kan si ṣa pamọ.

"Ibeere to yẹ ka beere ni pe, n jẹ Abacha lo si oke okun ri? N jẹ owo ti wọn gba pada wa pẹlu orukọ Abacha? Rara," Al-Mustapha ṣalaye.

'Ero mi lori ijọba awarawa ni Naijiria'

Ọgagun Hamza Al-Mustapha ti ilọsiwaju ti ba ijọba awarawa nitori o ti wa fun ọdun mẹrindinlọgbọn bayii.

Ẹwẹ, o ni ko si ayipada kankan ninu igbeaye awọn araalu, pẹlu eto aabo to mẹhẹ, isẹ ati osi ti awọn araalu n koju.

"Ijọba awarawa wa ṣugbọn fifi eyi fiya jẹ araalu ni ko ni itumọ, to si jẹ asilo ijọba awarawa," Al-Mustapha sọ.

N jẹ Al-Mustapha yoo jade dupo?

Ọgagun Hamza Al-Mustapha ṣalaye, "Insha Allah. Mo gbiyanju nigba kan ri ṣugbọn bayii mo tun ṣa ipa. Eyi ni idi ti a fi ba awọn orilẹede kan sọrọ pe ki wọn fi oju inu wo Naijiria paapa nipa eto idibo. Nitori gbogbo esi idibo lo jẹ mọdaru."

N jẹ Al-Mustapha yoo ṣe iṣopọ ẹgbẹ oṣelu?

"N ko ni nkankan ṣe pẹlu eyi nitori o jẹ ohun ti mo ri pe o tapa si igbagbọ mi. Ti mo ba ri nnkan ti ko dara to, n ko ni lọwọ ninu rẹ tabi ṣe ohun itiju ti yoo ba orukọ rere wa jẹ.

" Awọn eeyan to ni APC n lo awọn eeyan wa lati ma fun wọn ni anfani lati darapọ iṣopọ ẹgbẹ oṣelu, lagbara Ọlọrun , n ko ti ẹnikẹni ti yoo ṣe bẹ tabi lo mi ṣe bẹ fun orilẹede mi.

"Ko si iye owo ti wọn le gbe wa ti yoo mu mi ṣe ibi fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

Nigba ti a bi pe n jẹ yoo juwọ lẹ fun Atiku Abubakar, o ni, "N ko ro pe a le jọ irin ajo papọ, ẹ ko ni idi lati bere."