Kí ló mú kí òkè Iya Mopo nílùú Igbeti máa ya lulẹ̀, tó tún n ṣí èèpo? Nnkan tí a mọ̀ rèé

Aworan oke Iya Mopo niluu Igbeti

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ni ki awọn eeyan ilu Igbeti, nijọba ibilẹ Olorunsogo, ma ṣe ko aya soke lori Apata Iyamọpo to n yọ eruku lala.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣọna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọọba Dotun Oyelade, fi sita, lo ti ṣalaye pe ijọba ti bẹrẹ ayẹwo nipa ohun to ṣẹlẹ si apata naa.

O ni ko to ohun ti awọn eeyan Igbeti le maa bẹru le lori.

Gẹgẹ bi Oyelade ṣe wi, awọn akọṣẹmọṣẹ lati ajọ OYSMIDA to n ri si alumọni inu ilẹ nipinlẹ Oyo, labẹ akoso olori wọn, Ọgbẹni Biodun Oni, ti lọ sibi okuta naa.

"Ayipada to n ba apata yii ni i ṣe pẹlu ooru buruku to mu lati oṣu keji si ikarun-un ọdun yii, tutu lo si tẹle e.

"Eyi lo fa a ti apata naa fi n san, to n ṣi eepo, ti apa kan rẹ si n ya.

Iyẹn ni idi abajọ ti apata naa fi n gbọn rìrì,'' Kọmiṣọna eto iroyin ipinlẹ Oyo lo ṣalaye bẹẹ.

'Ijọba ti fi ọrọ to awọn onimọ nipa okuta lati fasiti UI n'Ibadan létí'

Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Oyo fi kun un pe ijọba Gomina Seyi Makinde tun n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ ninu imọ nipa apata, ti wọn wa lati Yunifasiti UI niluu Ibadan lori iṣẹlẹ naa.

O ni iṣẹ tijọba gbe fun wọn ni lati mọ ohun to n ṣẹlẹ gan an, ati bi wọn yoo ṣe dena rẹ lọjọ iwaju.

Bakan naa lo ni wọn yoo tun wa ọna ti wọn yoo fi da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan agbegbe naa.

Ọmọba Oyelade ni ki awọn olugbe agbegbge naa fi ọkan balẹ, nitori ko si akọsilẹ iku ẹnikẹni latari ohun to n ṣẹlẹ lara apata Iyamọpo.

Ṣugbọn lati dena ijamba, Oyelade rọ awọn olugbe agbegbe apata yii lati fi ibẹ silẹ fun igba diẹ na, ti wọn yoo fi wa ojutuu si ohun to n ṣẹlẹ patapata.

O ni bi ohun gbogbo ba ṣe n lọ lori ọrọ Apata Iyamọpo ni ijọba yoo maa fi to araalu leti.

''Kii ṣe 'volcano' lo ṣẹlẹ lori oke Iya Mopo, iyoro apata ni''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ eeyan lo ti n sọ pe ijamba 'volcano' lo ṣẹlẹ lori Oke Iya Mopo, amọ, onimọ ijinlẹ kan nipa nnkan to maa n ṣẹlẹ ninu ilẹ, Taofeeq Adebayo, ti ṣalaye wi pe ohun to ṣẹlẹ lori oke naa kii ṣe ''volcano'' rara.

Adebayo to jẹ olukọ ni fasiti ipinlẹ California lorilẹede Amẹrika sọ pe iyoro apata tawọn oloyinbo n pe ni 'weathering' ni nnkan to ṣẹlẹ lori oke naa.

''Eyi jẹ bi ayipada ṣe maa n ba awọn apata latari awọn igbesẹ arigbewọn bii nnkan to fori sọ apata tabi lilo kẹmika lori apata.

O tun tumọ si bi omi ṣe maa n yoro mọ apata lọna ati mu un yinrin ati igbesẹ abẹmi bii ki gbongbo igi wọ inu apata lọ eyi to le mu ki apata fọn ka.

Oriṣii iyoro apata meji lo wa, akọkọ ni lilo kẹmika lati jẹ ki apata yoro ati iyoro ẹlẹkamẹka eyi to tumọ si pe awọn ẹka kan ni wọn n ṣiṣẹ pọ,'' Adebayo lo sọ bẹẹ.

Adebayo ṣalaye pe iyoro apata ẹlẹkamẹka pin sọna mẹrin ọtọtọ.

O ni ''ọna kinni ni gbigba ẹyin yin to ni ṣe pẹlu bi yinyin ṣe maa n gbẹ apata.

Ọna keji ni bi awọn apata kekeke ṣe maa n ya danu kuro lara apata nla.

Igbesẹ iyadanu yii ni wọn maa n pe ni ibọ awọ, bi ejo ṣe maa n bọ awọ ni apata naa maa n bọ awọ.

Ọna kẹta ni idagbasoke iyọ onipato ihun, nigba ti iyoro apata ẹlẹkamẹka tun maa n waye pẹlu ọna abẹmi bii ki awọn igi oko na gbongbo sinu apata tabi kawọn ẹranko maa gbẹ iho sinu apata.''

Adebayo ni iyoro apata lọna iyadanu ni nnkan to ṣẹlẹ si oke Iya Mopo niluu Igbeti nipinlẹ Oyo.

O ni wọn tun maa n pe eyi ni ibọ awọ apata.

Adebayo sọ pe ''bi agbara ojo ṣe n wọ yeepẹ to wa lori Oke Iya Mopo fun ọpọ ọdun wa lara nnkan to ṣokunfa bi awọn apata kekeke ṣe n ya danu lara oke naa.

Yeepẹ atawọn apata kekeke to wa lori oke yii tẹlẹ lo n ki apata naa mọlẹ.

Awọn onimọ ijinlẹ ti kọkọ sọ tẹlẹ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ooru lo maa n mu kawọn apata ya lulẹ.

Amọ, iwadii ti fi han pe awọn alumọni amọ to n ṣara jọ ninu apata lo maa n fa eyi.

Adebayo sọ pe iwadii lori iṣẹlẹ to waye lori oke Iya Mopo lo le sọ gboogi nnkan to fa a gan an.