CBEX pada dé, ṣùgbọ́n àwọn oníbàárà kò tí ì rí owó wọn gba

Aworan ọwọ to n tẹ kọmputa ati foonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ṣe ẹ ranti ileeṣẹ olokoowo ori ayelujara CBEX to lulẹ loṣu diẹ sẹyin? Iroyin sọ pe wọn ti pada de .

Ipadabọ CBEX bayii ko ṣẹyin bi awọn onibaara wọn ti wọn ko ri nnkan kan loju opo naa mọ tẹlẹ, ṣe n ri owo wọn to wa nibẹ bayii loju opo naa.

Ṣugbọn oju nikan ni wọn fi n ri owo ọhun, wọn ko le ri igba.

Ki lo de?

CBEX sọ pe bi awọn to n ba oun da owo pọ yoo ba gba owo wọn to wa loju opo yii, wọn gbọdọ kọkọ fi igba dọla ($200) pamọ sọdọ awọn.

Wọn ni eyi ni yoo jẹ ki wọn le gba owo to ju ẹgbẹrun kan dọla lọ. ($1,000).

Ileeṣẹ to ko ọpọ eeyan si ipayinkeke naa sọ pe awọn ti wọn ba fẹẹ gba owo to kere si ẹgbẹrun kan dọla yoo kọkọ fi ọgọrun-un dọla (100 dollar) pamọ si apo CBEX na.

Iwadii BBC Pidgin fi han pe CBEX ni ki awọn onibaara wọ oju opo naa bi wọn ṣe n ṣe tẹlẹ ki ijakulẹ too waye, pe wọn yoo ri owo wọn gba.

Ṣugbọn ọkan ninu awọn eeyan to lugbadi gbese lati ọdọ CBEX sọ fun BBC pe oun ko ri owo oun gba jade nibẹ, bo tilẹ jẹ pe oun n ri i to han pe o wa ninu apo ikowosi oun.

O ni awọn to kowo si CBEX ti n fi oju ri i lori ayelujara bayii, ṣugbọn owo naa ko le tẹ wọn lọwọ.

Ẹ o ranti pe ajọ EFCC to n gbogun ti magomago nilẹ yii, mu awọn eeyan kan latari jibiti CBEX.

Iroyin sọ pe o le ni 1.3 trillion naira ($809,000) ti awọn ọmọ Naijiria padanu sinu CBEX.

Lojiji ni CBEX palẹmọ, ti wọn dawọ iṣẹ duro pẹlu owo olowo.

Ṣaa, EFCC ti kede awọn eeyan kan ti wọn ṣi n wa lori ọran yii, wọn si lawọn ti ri awọn owo kan gba pada.

Wo bí o kò ṣe ní í lùgbàdì CBEX lẹ́ẹ̀kan sí i

Bi ileeṣẹ olokoowo ori ayelujara yii ṣe pada de, wọn n wa awọn onibaara tuntun, wọn si tun fẹ ki awọn to ti wa nibẹ tẹlẹ mu owo si i wa.

Ẹka Federal Bureau of Investigation, (FBI), gba awọn eeyan nimọran lati ma ṣe sare tun kowo si CBEX.

O ni ki wọn ṣe iwadii wọn daadaa ki wọn too rọ lu u, nitori awọn ileeṣẹ sọ-ogun-di-ogoji bayii maa n wa onibaara tuntun ti wọn yoo fi owo wọn sanwo fun awọn mi-in ni.

Ẹka ọtẹlẹmuyẹ FBI sọ pe arumọjẹ lasan ti yoo jẹ kawọn eeyan tun mu owo tuntun wa ni CBEX gbe de, pẹlu bi wọn ṣe n jẹ kawọn onibaara maa ri owo wọn wo bayii.

O ni ki wọn ri i pe wọn fi to awọn onimọ nipa okoowo ti ki i ṣe magomago leti, ki wọn too tun ba ileeṣẹ naa da owo pọ.

FBI fi kun un pe ki wọn fi to awọn agbofinro leti, ki wọn le ṣe iwadii boya otitọ ni ipadabọ CBEX tabi ẹtan apa keji.

Bí o ṣe lè gba ara à rẹ lọ́wọ́ okòwò jìbìtì - SEC

Bakan naa ni ileeṣẹ to n ri si paṣipaarọ ati idunaa-dura ni Naijiria (Securities and Exchange Commission), kilọ fun awọn eeyan lori awọn okoowo onijibiti.

Wọnyi ni awọn nnkan ti wọn ni ki ẹ sa fun:

  • *Ibi yoowu to o ba ti n fi owo gba owo.
  • *Ibi ti wọn ba ti n fi nọmba ranṣẹ si foonu rẹ, ti wọn n sọ pe ki o da nọmba naa pada fawọn.
  • *Ibi ti wọn ba ti ṣeleri ọrọ̀ ojiji fun ọ lai daamu rara.
  • *Awọn okoowo to n ṣeleri owo to ṣoro lati gbagbọ pe wọn yoo fun ọ.
  • *Ṣọra fun ibi ti wọn ti n kan ọ loju lati tete ba awọn da owo pọ lai ro o jinlẹ ki o too kowo kalẹ.
  • Ṣọra fun ibi ti wọn ti fẹẹ mọ ohun gbogbo nipa rẹ nitori okowo to da yin pọ.
  • Ṣọra fun ibi ti wọn ti ni awọn yoo sọ ọ di milọnia labẹnu ti ẹnikan ko ni i mọ si i.
  • Awọn ti wọn yoo ni ki o waa gba ẹbun, ṣugbọn ti wọn yoo kọkọ ni ki o mu owo wa na.
  • Ṣọra nibi ti wọn ba ti ni o gbọdọ ko awọn eeyan wa lati fi orukọ silẹ na ki o too le gba ẹbun tirẹ.
  • Awọn ti wọn yoo ni ki o waa gba ogún mọlẹbi ti o ko mọ nipa rẹ.
  • Ṣọra fawọn ti wọn ni dandan ni ki o jere, pe o da awọn loju.
  • Ṣọra fawọn to n gba oju opo crypto nikan sanwo.
  • Ṣọra fun oju opo ti ko jọ tootọ biwọ naa ba n wo o.
  • Ṣọra bi ẹni to n gba owo lọwọ ọ rẹ ko ba fun ọ ni ẹri owo ti o n san wọle.
  • Bi wọn ba n sọ fun ọ pe ki o ma sọ nipa okowo naa fun ẹnikan kan.
  • Ṣọra fun akọṣẹmọṣẹ to ni ki o ma fi ofin kun ibi ti o n kowo si.
  • Mọ ibi ti o fẹẹ ko owo rẹ si daadaa.
  • Mọ ibi ti o fẹẹ ko owo rẹ si, tinu-tẹyin.
  • Ṣọra bi wọn ko ba le ṣalaye okowo to fẹẹ fun o ni èrè gọbọi.
  • Ṣe iwadi boya ọja tabi iṣẹ ti wọn n ṣe nibi ti o fẹẹ ko owo rẹ si ki i ṣe ayederu.
  • Ṣe iwadii boya èrè ti wọn n jẹ n fi gbogbo igba wọle.
  • Okowo ti wọn ko ba ti le ṣalaye fun ọ ko ye ọ yekeyeke, ma ko owo rẹ le e lori.