Afurasí agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ girama, èèyàn mẹ́wàá kú

Awọn eeyan to n daro

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn mọlẹbi n di mọ ra wọn lẹyin ti ori ko eeyan wọn yọ ninu ikọlu naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ko din ni eeyan mẹwaa to padanu ẹmi wọn lẹyin ti awọn kan ṣina ibọn bolẹ nile ẹkọ girama kan niluu Graz, lorilẹede Austria.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ibẹ ṣe fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, wọn ni awọn akẹkọọ ati agbalagba kan wa lara awọn to ku naa.

Bakan naa ni iroyin sọ pe afurasi agbebọn kan naa wa lara awọn to di oloogbe naa, bẹẹ ni ọpọ farapa yanna-yanna.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ile ẹkọ girama Dreierschützengasse High School, ni ibọn yinyin ọhun ti waye ni nnkan bii aago mẹwaa asiko ọdọ tiwọn.

Ni bayii, awọn ọlọpaa sọ pe awọn ti gba akoso gbogbo agbegbe naa.

'Ọ̀fọ̀ orilẹede leyi'

Aworan awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/Shutterstock

Nigba to n ṣapejuwe iku eeyan pupọ yii, ọga ile ẹkọ naa, Christian Stocker, sọ pe ọfọ ati ajalu ni iṣẹlẹ jẹ fun orilẹede Austria.

O ni ko sohun ti eeyan le fi ṣapejuwe adanu naa.

Nnkan bii aago kan kọja iṣẹju mejila ọsan oni, ni ireti wa pe ijọba yoo fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ naa bi wọn ṣe sọ

Minisita Ọrọ abele, Gerhard Karner ati ti eto ẹkọ, Christoph Wiederkehr, naa wa lara awọn ti afojusun wa pe wọn yoo sọrọ nibi ipade oniroyin ti yoo waye laago mẹta ọsan oni, eyi ti i ṣe aago mẹrin nilẹẹ Gẹẹsi.

Iroyin abẹle Austria ṣalaye pe o kere tan, eeyan ọgbọn lo wa nileewosan bayii.