Esie: ibùdó ìkónkan ìṣẹ̀mbáyé sí, níbi tí àwọn ère tí wọ́n bá jí kó ti ń fúnra wọn padà wálé

Àkọlé fídíò, Esie – ibùdó ìkónkan àṣà sí, níbi tí àwọn ère tí wọ́n bá jí kó ti ń fúnra wọn padà wálé.
Esie: ibùdó ìkónkan ìṣẹ̀mbáyé sí, níbi tí àwọn ère tí wọ́n bá jí kó ti ń fúnra wọn padà wálé

Ibudo ikonkan iṣẹmbaye si to wa ni ilu Esie ni ipinlẹ Kwara ni akọkọ iru rẹ lorilẹede Naijiria. Awọn nnkan iṣẹmbaye ti o le ni ẹẹdẹgbẹjọ (1500) lo wa ninu ibudo naa, koda oun ni ọpọ onwoye n wo pe awọn ere inu rẹ pọju lọ lagbaye.

Ni ọdun 1775 ni wọn ṣe awari awọn ere wọnyii, bẹẹni ọpọ awọn onimọ lo n sọ pe awọn ere wọnyi ti wa ṣaaju ọdun 1775 ti wọn ṣe awari wọn.

Ni ọdun 1933, ni oniwaasu kan ti orukọ rẹ n jẹ, H.G Ramshaw pariwo awọn ere naa sita fun aye gbọn.