'Gbogbo ìpèníjà ètò ààbò yóò di ìgbàgbé nílùú Owo tá a bá rí irinṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ'

Àkọlé fídíò,
'Gbogbo ìpèníjà ètò ààbò yóò di ìgbàgbé nílùú Owo tá a bá rí irinṣẹ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ'

Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Wilfred Olutokunbo Afolabi, ti ba BBC sọrọ lori ibi tie to aabo de duro nipinlẹ naa.

Ipinlẹ Ondo fẹ ẹ jẹ ọkan lara awọn ibi ti ipenija aabo ti pọ, paapaa bi awọn ajinigbe ati agbebọn ṣe n ṣiṣẹ nibẹ.

Lara awọn iṣẹlẹ ibanujẹ to ti ṣẹlẹ ni ikọlu to waye niluu Owo lọdun 2022, ati awọn miran to tun ti waye.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Kọmisanna Afolabi ṣalaye pe awọn aṣeyọri ti ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe nipinlẹ Onod, ko ṣẹyin iranlọwọ lati ọdọ awọn araalu, ileeṣẹ Ologun ati ajọ Civil Defence.

O ni laarin oṣu kan ninu oṣu Karun un , awọn ajinigbe mọkanlelọgbọn ni ọwọ tẹ, ti mọkanlelogun ninu wọn si bọ si gbaga ni agbegbe ilu Owo.

Kọmisanna ọlọpaa, Wilfred Olutokunbo Afolabi

Bakan naa ni ọga ọlọpaa naa sọ pe ti ileeṣẹ ọlọpaa ba le ni anfaani si awọn irinṣẹ imọ ẹrọ bii ẹrọ ayaworan to n fo loju ofurufu, drone, ati awọn irinṣẹ ti awọn le maa fi tọpinpin awọn ajinigbe.

"Ti a ba le ni iru awọn irinṣẹ bẹẹ, gbogbo ijinigbe ati ipenija eto aabo ni Owo, yoo dopin.

"Iṣẹ ọlọpaa ojukoroju nikan ko le mojuto ipenija eto aabo lasiko yii."

Lara awọn ọdaran gboogi ti ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti mu, gẹgẹ bi Ọgbẹni Olutokunbo Afolabi ṣe sọ, ni awọn ikọ to ma n ja ọkọ epo gba nipinlẹ naa, ti wọn ma n ji awọn awakọ gbe tabi ki wọn o pa wọn.

Bakan naa lo ni ọwọ tẹ ikọ to ma n ji ọkọ gbe nipinlẹ naa

"Ki n to o de si Ondo gẹgẹ bi kọmisanna, iwa jiji ọkọ pọ, amọ lati igba ti ọwọ ti tẹ baba isalẹ ikọ naa, eyi ti dawọ duro."

Lori ipenija eto aabo to n waye ni ilu Owo, Afolabi sọ pe gbogbo ọjọ Aiku ni ọlọpaa ma n pọ si niluu naa lati pese aabo fun awọn olujọsin kaakiri awọn ṣọọṣi to wa niluu Owo.

Tẹ o ba gbagbe, o le ni ogoji eeyan to padanu ẹmi wọn, ti ọpọ si farapa lẹyin ti awọn agbebọn kọlu ile ijọsin St Francis Catholic Church.

Laipẹ yii naa ni iroyin kan tun jade pe, awọn agbebọn kan kọ lẹta si ilu naa pe awọn tun n bọ lati kọlu wọn.

Lori iroyin kan ti awọn eeyan kan n gbe kaakiri pe o ṣe e ṣe ki kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo maa ṣiṣẹ fun awọn oloṣelu, Ọgbẹni Olutokunbo Afolabi sọ pe irọ patapata ni eyi.

"Irọ ni pe oloṣelu n lo mi, otitọ nikan ni mo duro fun gẹgẹ bi ọga ọlọpaa."