Òbí sọ ọ̀gá ilé-ẹ̀kọ́ di èèrò iléèwòsàn lẹ́yìn tí kò jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ jìwèé wò nínú ìdánwò WAEC l'Akure

Oríṣun àwòrán, Leke Adegbite
Igbakeji ọga agba ile-ẹkọ girama Complete Child Development College, to wa ni Aule, niluu Akure, ipinlẹ Ondo, ti di eero ileewosan lẹyin ti awọn janduku kọluu.
Iroyin sọ pe obi akẹkọọ kan lo ko awọn afurasi janduku lọ sile-ẹkọ ọhun, ti wọn si lu Ọgbẹni Alexander Rotifa ni alubami, nitori pe ko faaye gba ọmọ naa lati jiwe wo pẹlu foonu rẹ lasiko idanwo WAEC to n lọ lọwọ.
Iwadii BBC Yoruba ṣafihan pe akẹkọọ naa, Elisha Wisdom n gbiyanju lati lo foonu rẹ ti Ọgbẹni Rotifa si ka a. Lẹyin naa ni ọga agba naa gba foonu lọwọ rẹ, eyi to mu ki inu bi iya ọmọ ọhun gidigidi nigba to de ile.
Ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun ni Ọgbẹni Alexander Rofifa wa bayii gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.
Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé gan-an?

Lasiko to n salaye bi iṣu ṣe ku bi obẹ ṣe bu u, ọga agba ile ẹkọ naa, Chioma Avbayeru sọ pe wahala yii bẹrẹ lasiko ti Ọgbẹni Rotifa gba foonu lọwọ Elisa Wisdom lasiko idanwo WAEC ni ọsẹ to kọja.
Avbayeru sọ di mimọ pe, wọn ko faaye gba lilo foonu layika ile-ẹkọ naa paapaa julọ lasiko idanwo.
Ninu ọrọ rẹ o ni "gbogbo igba ti awọn akẹkọọ ba ti n to wọle fun idanwo, a maa n ṣayewo ara wọn lati ri daju pe wọn ko mu ohunkohun wọle.
"Ni ọjọ naa, Ọgbẹni Rotifa ri ẹrọ ibanisọrọ kan lọwọ Elisha to si mu u wa si ọọfisi mi ti mo si fi pamọ ni ibamu pẹlu ilana wa."
"Ọmọ naa wa si ọọfisi mi lati gba foonu rẹ pada, mo sọ fun pe o di ẹyin idanwo NECO ki n to fun ni ibamu pẹlu ofin ati ilana ile-ẹkọ."
Avbayeru salaye pe iṣẹlẹ naa di wahala ni Ọjọbọ to kọja lẹyin ti wọn jade ile-ẹkọ, iya ọmọ naa yabo ọgba ile-ẹkọ ọhun to si beere fun foonu ọmọ rẹ.
O tẹsiwaju pe oun salaye fun un pe wọn ko faaye gba awọn akẹkọọ lati ṣamulo foonu lasiko idanwo ni ko jẹ ki oun fun un.
Ibinu yii mu ki obi ọmọ naa koju Ọgbẹni Rotifa eyii to mu rogbodiyan waye, ti awọn alaṣẹ ile-ẹkọ si ni ki wọn da foonu naa pada.
Arabinrin Avbayeru sọ pe bo tilẹ jẹ pe wọn da foonu naa pada, obi ọmọ yii lọ si ile Ọgbẹni Rotifa ni aago mẹjọ aṣalẹ pẹlu awọn janduku, ti wọn si lu u ni alubami.
Kíni ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo sọ?
Ileeṣẹ to n mojuto eto ẹkọ nipinlẹ Ondo ti ṣalaye pe iwadii ti wọn se ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni pe obi akẹkọọ naa ati awọn janduku kọlu olukọ ọhun.
Ẹka naa fi ọrọ yi lede ninu atejade ti wọn fi sọwọ sawọn akọroyin.
Wọn ṣalaye pe Ọgbẹni Rotifa gbe igbesẹ ti o yẹ nitori pe ipinlẹ Ondo ko faaye gba magomago lasiko idanwo.
Wọn ṣalaye pe wọn ti bẹrẹ iwadii, ti wọn yoo si ri daju pe wọn fi panpe ọba mu gbogbo awọn ti igba ọrọ naa si mọ lori.
Ẹka naa fi da ile-ẹkọ ọhun loju pe wọn yoo dari awọn agbofinro lọ sibẹ fun abo to peye titi ti wọn yoo fi pari idanwo ti wọn n se lọwọ.
Kìni ọlọ́pàá sọ?
Kọmisọna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Wilfred Afolabi ti paṣẹ fun awọn ikọ ileeṣẹ naa lati fi panpẹ ọba mu gbogbo awọn to lọwọ ninu aṣemaṣe yii.
Kọmisọna naa to koro oju si igbese obi ọmọ ọhun pasẹ fun igbakeji kọmisọna to n bojuto irufẹ iṣẹlẹ yii lati ri daju pe iru iṣẹlẹ naa ko pada waye ni ile ẹkọ naa mọ.
O wa rọ gbogbo awọn ara ilu lati maa ṣe isẹ oojọ wọn laisi ibẹru kankan, pẹlu ileri pe abo to peye wa lori gbogbo olugbe ipinlẹ Ondo.















