Bàbá yìnbọn pa ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn tó rò pé ọ̀bọ ni òun rí nínú oko l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbẹ kan ti wọn ko fi orukọ rẹ lede ti yinbọn pa ọmọ rẹ ọkunrini nipinlẹ Ekiti.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Joseph Eribo lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan.
Bo tilẹ jẹ pe Eribo ko darukọ ọkunrin naa, o ni ilu Iye Ekiti, ni ijọba ibilẹ Ilejemeje ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Kọmiṣanna ọlọpaa sọ pe niṣẹ ni ọkunrin naa ṣeeṣi yinbọn pa ọmọ rẹ ọhun to jẹ ọmọ ọdun marundinlogun latari bi awọn ọbọ ṣe maa n da a lamu ninu oko rẹ.

Oríṣun àwòrán, Ekiti Police Command
O ni "Ọkunrin naa lọ si oko toun ti ọmọ rẹ ọkunrin to jẹ ọmọ ọdun marundinlogun lati lọ ṣiṣẹ.
"Nigba ti wọn de oko, o bẹrẹ si n binu pe awon ọbọ maa n yọ oun lẹnu ni gbogbo igba ti wọn ba ti n ṣiṣẹ.
"Bi wọn ṣe n ba iṣẹ lọ, o ṣakiyesi pe awọn ewe kan mi lori igi to si ro pe awọn ọbọ naa lo tun pada wa bo tilẹ jẹ pe o mọ pe oun ati ọmọ rẹ ni wọn jọ lọ si oko lọjọ naa.
"Bo ṣe gbe ibọn rẹ niyẹn lai wo oke, lo ba ṣina ibọn bolẹ, lẹyin naa ni ọmọ rẹ jabo lati ori igi ọhun."
Eribo ṣalaye siwaju si pe wọn gbe ọmọdẹkunrin naa digbadigba lọ sile iwosan amọ o pada jade laye.
O pari ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe aṣiṣẹ ni arakunrin naa fi gbẹmi ọmọ, yoo foju wina ofin.















