Ìjàmbá ọkọ̀ pa eléré ìdárayá bí ogún lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Gateway Games 2025

Oríṣun àwòrán, KANO STATE GOVERNMENT
Ijọba ipinlẹ Kano ti ransẹ ibanikẹdun si mọlẹbi awọn aṣoju ipinlẹ naa ninu idije ere idaraya ti orilẹede Naijiria to waye nipinlẹ Ogun kẹdun lori awọn eeyan wọn to ku ninu ijamba ọkọ.
Eeyan mọkanlelogun lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ naa to waye lẹyin ti wọn kuro nipinlẹ Ogun.
Kọmisana fun ọdọ ati ere idaraya nipinlẹ Kano, Hon. Mustapha Rabiu Kwankwaso, ni iṣẹlẹ ibanujẹ gba a ni eyi fun gbogbo ipinlẹ Kano.
Lati ọsẹ bii meji sẹyin ni idije ere idaraya ọhun ti wọn pe ni Gateway Games 2025, ti n waye, to si pari ni Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un.
Ninu atẹjade to fi lede , Kwankwaso, to gba ẹnu ijọba ipinlẹ Kano sọrọ, rọ awọn eeyan ipinlẹ ọhun lati ṣe pẹlẹ lori iṣẹlẹ paapaa awọn mọlẹbi ti ọrọ kan.
"Asiko yii le pupọ fun wa. Inu wa bajẹ pupọ lori iroyin to ni awọn eeyan wa to lọ ṣoju wa nibi ere idaraya to wa nipinlẹ Ogun padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ. Ero wa pẹlu awọn mọlẹbi oloogbe lasiko yii."
O ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyi to sọ ipinlẹ naa sinu ibanujẹ, to si jẹ ko di mimọ pe ijọba yoo gbe gbogbo igbesẹ lati duro ti awọn mọlẹbi.
Kwankwaso dupẹ lọwọ gbogbo eleto ilera to dide si awọn eeyan naa, to si fi da araalu loju pe ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ yoo jade laipẹ.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Ọkọ akero to n gbe awọn elere idaraya ati olukọni lati ipinlẹ Kano bọ pada wa si ile lati ipinlẹ Ogun lo ṣadeede ni ijamba, ti eeyan mọkanlelogun si padanu ẹmi wọn.
O ku diẹ ki awọn eeyan naa wọ ipinlẹ Kano ni iṣẹlẹ naa waye lọjọ Ṣatide.
Adele fun alaga ajọ ere idaraya nipinlẹ Kano, Ibrahim Umar Fage, lo fidi iroyin naa mulẹ fun ikọ BBC.
"Awọn eeyan sun niluu Abuja,ti wọn si gbera lati ma bọ lonii. Wọn ni ijamba ọkọ ni Aakatsalle, ti ọkọ wọn si kuro lori afara Ciromawa.
"O to ogun eeyan to padanu ẹmi wọn, ti awọn mii si wa ni ile iwosan bayii."















