Ilé ẹjọ́ kan gógó bí ìyá tó ta ọmọ rẹ̀ ṣe gbà ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére

Kelly Smith, iya to gbadajọ ẹwọn gbere

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Kelly Smith, iya to gbadajọ ẹwọn gbere
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Racquel "Kelly" Smith, obinrin ọmọ orilẹede South Africa kan ni ile ẹjọ ti ju si ẹwọn gbere bayii, lori ẹsun pe o ji ọmọ bibi inu rẹ gbe, o si ta a soko ẹru nitori owo.

Yatọ si Racquel to gbadajọ yii, kootu tun ju ọrẹkunrin rẹ, Jacquen Appollis ati ẹnikẹta wọn; Steveno van Rhyn, si ẹwọn kan naa pẹlu.

Ojiji ni Joshlin Smith, ọmọ ọdun mẹfa ti wọn ni iya rẹ lo ta a naa di awati nita ile wọn to wa ni Saldanha Bay, nitosi Cape Town.

Oṣu keji ọdun 2024 ni wọn ko ti ri i mọ bi wọn ṣe wa a to pẹlu ikede karikari.

Alaye awọn agbefọba lori ẹjọ naa ni pe iya rẹ lo ta a soko ẹru, bo tilẹ jẹ pe wọn ko ri eyi fidi ẹ mulẹ.

Awọn agbefọba naa sọ pe awọn gbagbọ pe iya rẹ ti ko le maa mu oogun oloro lo ta a, ko le ba a ri owo naa lo.

Nigba ti igbẹjọ bẹrẹ, ọsẹ mẹjọ to milẹ titi ni South Africa lo fi waye, bẹẹ lawọn ẹlẹrii ati agbefọba n tu awọn aṣiri ikọkọ jade.

Joshline Smith,ọmọ ti wọn ni iya rẹ lo ta a

Oríṣun àwòrán, Executive Mayor Andrè Truter/Facebook

Àkọlé àwòrán, Joshline Smith,ọmọ ti wọn ni iya rẹ lo ta a

Àwọn tó jẹ́rìí takò ìyá ọmọ náà lé ní ọgbọ̀n

Ṣaaju idajọ kootu, ẹlẹrii to tako Kelly Smith pe oun lo ta ọmọ rẹ le ni ọgbọn.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣugbọn Kelly ati awọn ti wọn jọ n jẹjọ kọ lati pe ẹnikẹni pe ko waa jẹrii gbe awọn.

Atako to le ju wa lati ọdọ ọrẹ Smith ti wọn jọ jẹ alajọgbele, Lourentia Lombaard, ni orukọ ọrẹ to di agbẹnusọ kootu naa.

Lombaard sọ fun ile ẹjọ pe Smith sọ fun oun pe oun ti huwa agọ kan, pe oun ti ta Joshlin fun oniṣegun ibilẹ kan, eyi ti wọn n pe ni "sangoma" ni South Africa.

"Ẹni to mu Joshlin lọ nilo oju ati awọ ara rẹ ni." Arabinrin Lombaard lo sọ bẹẹ fun kootu.

Bakan naa ni pasitọ kan lagbegbe wọn, ṣalaye fun ile ẹjọ pe oun gbọ ti Smith to bimọ mẹta, n sọ ni 2023 pe oun fẹẹ ta awọn ọmọ naa ni 20,000 rand ($1,100; £850) ọmọ kọọkan.

O ni iya yii sọ pe oun le gba $275 paapaa.

Tiṣa to n kọ ọmọ ti wọn ko ri mọ ọhun naa jẹrii tako Kelly Smith.

O ni iya rẹ sọ foun lasiko ti wọn n wa Joshline, pe ọmọ naa ti wa ninu ọkọ oju omi, ninu kọntena, wọn si ti n lọ si ẹkun-un Iwọ-Oorun Africa ( West Africa).

Oṣiṣẹ igboro kan naa tako, Smith, o ni ki I ṣe aṣiṣọ ti eeyan ba sọ pe Smith lo wa nidii tita ọmọ rẹ silẹ ibomi-in.

Ẹri Arabinrin Lombard ati ti pasitọ ni wọn ṣamulo ju lati gbe idajọ kalẹ.

Lasiko igbẹjọ naa, Adajọ ṣapejuwe Smith bii alagabangebe eeyan to n pa irọ ti ko bo rara, ti ko si tun Bikita boya awọn toun n parọ naa fun mọ pe irọ gbuu ni.

Ki Adajọ too dajọ, iya to bi Smith, Amanda Smith-Daniels, rọ ọ lati sọ ibi ti Joshlin (ọmọ-ọmọ rẹ) wa.

O ni ki Smith yee bu awọn ẹlomi-in lori airi Joshline mọ, nitori funra rẹ lo ṣeto bi ọmọ inu rẹ ṣe dẹni ti wọn n wa kiri.

Ìdájọ́ kóòtù

Iya to bi Kelly Smith

Oríṣun àwòrán, Reuters

Adajọ Nathan Erasmus, ninu idajọ rẹ, sọ pe:

"Lori ẹsun tita ọmọ soko ẹku, a ju yin si ẹwọn gbere. Lori ijinigbe, a ju yin si ẹwọn ọdun mẹwaa."

Bi Adajọ ṣe wi bẹẹ ni awọn ero kootu patẹwọ.

Adajọ Erasmus sọ pe iya ọmọ ati awọn igbimọ iwa aburu rẹ ko tiẹ ṣe bii ẹni to kabaamọ iwa ti wọn hu.

O loun ko le fun wọn ni ijiya to kere rara.

Ninu ọrọ awọn ọlọpaa, wọn ni awọn yoo ṣi maa wa ọmọ to sọnu naa, kọda, kọja awọn ẹnu ibode South Africa.

"A o ni I sinmi titi ta a maa fi mọ ohun to ṣẹlẹ si Joshlin. Tọsan-toru la n wa a."

Kọmiṣanna ọlọpaa Western Cape, Thembisile Patekile, lo sọ bẹẹ fun awọn ẹka iroyin abẹle.

Bakan naa ni ajọ National Prosecuting Authority (NPA), to n ri si igbẹjọ, gboriyin fun idajọ yii.

Wọn gboriyin fun ikọ to ni wọn ta Joshlin, wọn si fa a le ẹni ti yoo ra a fun ẹru ṣiṣe lọwọ ni.

Ṣaa, lasiko igbẹjọ naa, wọn ko fi oju ẹni ti wọn lo ra ọmọ yii han.

BBC beere lọwọ NPA fun alaye kikun, ṣugbọn agbẹnusọ wọn ko wi nnkan kan.

Ki wọn too dajọ naa ni awọn eeyan ti n sọ pe awọn afurasi mẹta naa ko gbọdọ ria anu kankan gba, afi ijiya to nipọn.