Aṣemáṣe tí gbajúmọ̀ akọrin, Speed Darlington, ní òun ṣe nílé ìtura ń fa awuyewuye, àjọ NAPTIP àti DSVA dá sọ́rọ̀ náà

Oríṣun àwòrán, Speed Darlington/Instagram
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu fọnran ti akọrin takasufee, Darlington Okoye tawọn eeyan mọ si Speed Darlington ṣe ninu eyi to ti ṣalaye pe oun ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹẹdogun ni ibalopọ nile itura kan.
Darlington ṣalaye ninu fidio naa wi pe oun ko le ṣiṣẹ fun eeyan laye oun.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, Darlington ni oṣiṣẹ ile itura toun gbe ọmọbinrin ọdun mẹẹdogun naa lọ lo nu ẹjẹ to da sori aṣọ bẹẹdi toun ti ba ọmọ naa sun tori ko tii mọ ọkunrin ri tẹlẹ.
Speed Darlington sọ ni ede Igbo ninu fidio ọhun pe oun ni lati san N2,000 ki wọn to wa tun aṣọ bẹẹdi tawọn lo ṣe.
Akọrin takasufee naa sọ pe o ri bakan ki eeyan sọ fun agbalagba lati wa nu ẹjẹ nu lori aṣọ.
Darlington ni idi gan an niyii toun fi sọ pe oun ko le ṣiṣẹ fun ẹnikankan bi ko ṣe fun ara oun.
Ajọ DSVA sọrọ lori fidio ti Speed Darlingson ṣe
Ẹwẹ ajọ DSVA to n gbogun ti iwa ipa nipa ibalopọ sawọn obinrin nipinlẹ Eko ti kede pe awọn ti ri fidio ti Speed Darlington ṣe ninu eyi to ti sọ pe oun ba ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹẹdogun sun.
Ajọ DSVA sọ ninu atẹjade to fi lede loju opo X rẹ pe bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ko sọ ibi ti iṣẹlẹ ọhun waye ninu fidio ti o ṣe, ajọ naa ni ipinlẹ Eko nikan ni agbara awọn mọ.
Amọ, ajọ DSVA sọ pe awọn ti fi iṣẹlẹ naa to ajọ NAPTIP to n gbogun ti fifi eeyan ṣe owo ẹru tabi kata-kara leti.
Ajọ DSVA ni ijọba ipinlẹ Eko ko ni beṣu bẹgba lati tẹsiwaju ninu gbigbogun ti oniruuru iwa ipa nipa ibalopọ sawọn obinrin.
Bakan naa ni ajọ DSVA sọ pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa daabo awọn ọmọde ni Naijiria.
Ajọ naa wa rọ ẹnikẹni to ba mọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii lati kan sawọn lori nọmba ẹrọ ibanisọrọ yii - 08000-333-333, tabi ki wọn kan sawọn loju opo ayelujara DSVA.
Ajọ DSVA ko ṣai dupẹ lọwọ awọn to sọ fawọn nipa iṣẹlẹ yii, nigba ti wọn rọ araalu lati ma dẹkun sisọ iru iṣẹlẹ bayii fawọn agbofinro bakan naa.
Ẹwẹ, ajọ NAPTIP ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori fidio to n ja ran-in ran-in lori Instagram naa.
Bakan naa tun ni NAPTIP tun sọ loju opo X rẹ pe awọn yoo tun ṣe iwadii lori awọn fidio mii ti Datlington fi lede loju opo Instagram rẹ.
Ajọ naa ni awọn ko ni kaarẹ lati ri pe awọn daabo ba awọn ọmọde lọwọ oniruuru iwa ipa tawọn eeyan kan le hu si wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2















