Ẹlẹ́rìí ní kò sí àkọsílẹ̀ $400,000 tóun gbé fún Emefiele, ó pè fún ìwádìí

Ẹlẹrii lori igbẹjọ gomina banki apapọ Naijiria, CBN, tẹlẹ ri, John Adetola ti sọ fun ile ẹjọ wi pe ko si akọsilẹ fun $400,000 toun gbe fun Godwin Emefiele, gomina banki CBN tẹlẹ.
Adetola to jẹ oluranlọwọ fun Emefiele tẹlẹ fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko ti amofin Olalekan Ojo, to jẹ agbẹjọro Emefiele n fọrọ wa a lẹnu wo nile ẹjọ niluu Eko.
Emefiele n jẹjọ lori ẹsun onikoko mọkandinlogun to da lori gbigba ẹbun lọna ti ko ba ofin mu ati oniruuru iwa ibajẹ to hu nigba to wa lọfiisi gẹgẹ bii gomina banki CBN ti ajọ EFCC fi kan an.
Henry Omoile to n jẹjọ pẹlu Emefiele n jẹjọ lori ẹsun onikoko mẹta to da lori gbigba ẹbun lọna to lodi sofin gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba.
Adetola sọ pe loootọ loun kuna lati fun ajọ EFCC ni ẹri to ni ṣe pẹlu ọrọ to waye lori WhatsApp tabi foonu to le fidi rẹ mulẹ pe loootọ loun gba owo naa fun Emefiele.
O ni lọdun 2018 ni ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Eric Odoh fi atẹjiṣẹ ranṣẹ soun lori WhatsApp wi pe koun lọ gba owo lowọ John Ayoh ki oun si gbe owo naa fun Emefiele ti o ba ti de si ilu Eko.
Adetola ni oun lọ ile Ayoh lagbegbe Lekki nibi ti o ti foun ni apo iwe kan, eyi ti oun fi le Emefiele lọwọ ni ọfiisi rẹ.
O ni oun ko gbimọ pọ pẹlu EFCC lati jẹrii tako Emefiele ki wọn le fi oun silẹ ninu igbẹjọ naa.
Adetola ni ajọ EFCC gan an lo fi risiiti owo naa lori WhatsApp ṣọwọ si oun.
Nigba ti Rotimi Oyedepo to jẹ agbẹjọro EFCC beere lọwọ Adetola wi pe ki lo de ti ko fi ṣe akọsilẹ owo naa, o dahun pe oun ko ni idi lati ṣe bẹẹ.
Lẹyin naa ni adajọ Rahman Oshodi paṣẹ wi pe ki Adetola maa lọ, o si sun igbẹjọ naa siwaju.
Emefiele pe fun akọṣẹmọṣẹ lati ṣayẹwo ẹri atẹjiṣẹ WhatsApp lori ẹsun jibiti $17m
Ẹwẹ, gomina banki apapọ Naijiria CBN tẹlẹ ri, ti sọ fun ile ẹjọ to n ri si awọn ẹsun ọdaran kan lati lo akọṣẹmọṣẹ to le ṣe iwadii lori foonu ti wọn lo fun atẹjiṣẹ WhatsApp gẹgẹ ẹri lori ẹsun jibiti $4.5bn ati N2.8bn ti wọn fi kan an.
Ti ẹ o ba gbagbe, ajọ EFCC fẹsun kan Emefiele wi pe o gba $17,100,000 lọwọ oniṣowo kan nipasẹ Monday Osazuwa to ṣe alarina, gẹgẹ bi ẹbun fun bi o oniṣowo naa ti ri owo ilẹ okeere gba ni CBN.
Oṣiṣẹ EFCC kan, Alvan Gurumnaan fẹsun kan Emefiele pe o gba $17.1m nipasẹ Osazuwa laarin oṣu kẹsan an ọdun 2020 si osu Kẹfa ọdun 2023, o ni eyi waye ni ọjọ diẹ si asiko ti wọn da a duro lẹnu iṣẹ.
Gurumnaan ni ile Emefiele ni Osazuwa ti gbe owo naa fun Emefiele.
Agbẹjọro EFCC pe fun mimu ẹri ori WhatsApp naa wa sile ẹjọ, Ojo to jẹ agbẹjọro Emefiele ko tako aba naa ṣugbọn o ni agbẹjọro Emefiele lẹtọọ lati ṣayẹwo foonu ti wọn lo lati fi atẹjiṣẹ naa ranṣẹ.
O ni awọn agbẹjọro Emefiele ni lati fidi rẹ mulẹ bo ya lati ori foonu Emefiele ni wọn ti ri atẹjiṣẹ ori WhatsApp loootọ.
Ninu ọrọ rẹ, Adajọ Oshodi paṣẹ pe kawọn olujẹjọ kọwe lati pe fun akọmọṣẹ to le ṣayẹwo foonu ti wọn tẹ atẹjiṣẹ lori ọrọ owo naa jade.
Gurumnaan tun sọ fun ile ẹjọ wi pe oriṣiiriṣii ẹsun aṣilo ọfiisi, gbigba ẹbun lọna ti ko tọ ati gbigbe igbe aye to ju owo oṣu eeyan lọ ni iwadii ti han eyi to jẹ ki ajọ EFCC gbe e lọ sile ẹjọ.















