Wo àpẹẹrẹ àti ìgbésẹ̀ tí o lè gbé bí ọmọ̀ rẹ bá ń kojú ìdúnkokò níle ẹ̀kọ́

Aworan ọmọkunrin kekere to karibọnu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹbun pataki ni ọmọ jẹ, eyi lo fi jẹ dandan fun obi to bimọ ati awọn olukọ ti yoo kọ ọmọ naa nileẹkọ lati maa ṣe akiyesi ọmọ daadaa.

Idunkooko mọni ti oloyinbo n pe ni 'bullying', maa n saba waye nile ẹkọ ju ibikibi lọ fun awọn ọmọde.

National Center of Education, ninu akọsilẹ wọn lọdun 2016, ṣalaye pe ida ogun awọn ọmọde lo n koju idunkooko nileewe.

Awọn ẹgbẹ wọn naa ni wọn yoo deede maa ko wọn layajẹ, dẹru ba wọn tabi fi iya jẹ wọn.

Ọpọ igba ni ibẹru ẹni to n dunkooko mọ wọn naa ki i jẹ ki wọn le sọ ohun ti wọn n koju.

Wọn yoo si maa dakẹ sinu ibanujẹ ati idaamu.

Iwadii fi han pe awọn ọmọ ti wọn jẹ akanda ẹda ni wọn tun maa n koju idunkooko mọ ni bayii, bẹẹ lawọn mi-in n ko tiwọn lori ayelujara.

Idunkooko mi-in n gba ọna ibalopọ waye, ti wọn yoo maa ba ọmọ naa laṣepọ lai le sọ fun ẹnikẹni.

A ti ri awọn ọmọde ti wọn ko iku ojiji nileewe latari eyi, ti obi ko si fura afi igba to ja siku.

Láti dènà ìjàmbá, ìbànújẹ́ tàbí ikú ọmọ, wọ̀nyi ni àwọn ohun ti olùkọ́ gbọ́dọ̀ ṣe

Bi o ba jẹ tiṣa to n kọ ọmọ lẹkọọ, ẹkọ naa ko pari sibi iwe nikan.

Kọ wọn ni aanu ati ifọrọ-ro-ara ẹni wo

Iwadii fi han pe nigba ti awọn akẹkọọ ba loye nipa nini aanu ọmọlakeji loju, fifi ọrọ ro ara ẹni wo ka too huwa, wọn ko ni i huwa ika si akẹkọọ ẹgbẹ wọn.

Susan Patterson, adari lẹka to n ri si idunkooko mọni ni Lesley University, sọ pe olukọ ni lati ko awọn akẹkọọ papọ, ko si fi ẹkọ nipa bi a ṣe n ba ẹlomi-in gbe nirọrun, kọ wọn.

  • *Jẹ ki wọn ba ara wọn sọrọ ni yara ikawe
  • *Kọ wọn lati sọ ẹdun ọkan wọn jade
  • *Ṣe akiyesi awọn iṣesi to lodi lara akẹkọọ bii
  • Yiyi eyinju kiri
  • Titẹju mọ nnkan kan fun igba pipẹ
  • Kikọ ẹyin si kilaasi
  • Ki ọmọ maa rin ẹrin iyangi ko si maa ni kawọn ẹgbẹ oun maa maa ṣe bẹe.
  • Pipe awọn ẹgbẹ rẹ ni inagijẹ buruku
  • Yiyago fun awọn ọmọ yooku
  • Ṣiṣe wọn ni jamba
  • Ki ọmọde maa ṣọ́ awọn ẹgbẹ rẹ.

Àpẹẹrẹ fún òbí tí ọmọ rẹ̀ ń kojú ìdúnkokò

Aworan apa isalẹ ọmọbinrin kan to kawọ bọ itan

Oríṣun àwòrán, AFP

Oriṣi ọna ni idunkooko mọni ati ifiyajẹni le gba ṣẹlẹ si ọmọ

*Aṣọ rẹ le ya lati ileewe wale, o le maa sọ iwe nu, tabi bata ati awọn nnkan elo miran.

*O le gbe àpa tabi egbo ti ko ni lati ile pada sile lati ileewe.

*O le ma ni ọrẹ to n ba ṣere.

*Ẹru ile ẹkọ le maa ba a, o le maa fẹẹ wọ mọto ti awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ wa.

*Iwe le ma wu u ka mọ, o si le bẹrẹ si i gba odo wale.

*O le maa ṣaroye pe ori n fọ oun lọpọ igba, o le maa kigbe inu rerun tabi ailera mi-in.

*O le ma le sun daadaa, o si le ma le jẹun daadaa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn apẹẹrẹ yii le jẹ mọ nnkan mi-in naa, idunkooko mọni ni awọn oluwadii sọ pe o maa n fa a ju.

Ọna abayọ

Aworan iya ati ọmọ rẹ kekere ti wọn n rẹrin-in lori ibusun pẹlu ẹrọ ayarabiaṣa lọwọ iya naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • *Maa ba ọmọ rẹ sọrọ deede nipa ohun to n ṣẹlẹ nileewe rẹ.
  • *Jẹ ki o mọ pe iwakiwa bẹẹ maa n ṣẹlẹ nileewe.
  • *Sọ fun un pe o ko fẹ ki iru nnkan bẹẹ ṣẹlẹ si i.
  • *Beere boya awọn kan n daamu rẹ nile ẹkọ.
  • *Beere boya o ni ẹnikan to yan laayo ati ẹnikan ti ki i fẹẹ ri.
  • Ki lo de ti ki í fẹẹ ri ẹni naa?
  • Ta a ni wọn jọ n jẹun, jokoo pọ ni kilaasi ati ninu ọkọ ileewe?
  • Lọ sọdọ olukọ ọmọ rẹ ki o beere bo ṣe n lọ.
  • Bi ti tiṣa ko ba yá, ba awọn agbani-nimọran (counsellor) to maa n wa nileewe sọrọ.
  • Bi ọmọ rẹ ba ti wọnu ironu latari iṣoro yii, mu un lọ sọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ to n dani lẹkọọ lori ọrọ ọkan ati ọpọlọ.