Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, wọ́n dáná sun ilé torí ọmọkùnrin tí wọ́n lù pa lórí ẹ̀sùn pé ó jí 'Power bank'

Awọn obi Chinonso Amadi
Àkọlé àwòrán, Awọn obi Oloogbe Chinonso Amadi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọdọkunrin kan, Chinonso Amadi, ni wọn ti lu pa bayii ni ilu Owaelu Uratta, nijọba ibilẹ Ariwa Owerri, ipinlẹ Imo.

Iroyin sọ pe awọn ọdọ kan niluu naa ni wọn lu Chinoso pa l'Ọjọruu, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un ọdun 2025.

Ẹsun ti wọn fi kan ọmọdekunrin naa ni pe o ji ẹrọ ti wọn fi n ro foonu lagbara, Power bank.

BBC gbọ pe igi ni wọn dajọ fi lu u pa.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe wọn gbe ọdọkunrin naa lọ sibi kan ti wọn n pe ni ibudo ìyà, ibẹ ni wọn si ti lu u pa.

Lẹyin ti wọn lu u pa tan ni wọn gbe e lọ si ile baba rẹ, nibi ti a gbọ pe wọn sin oku rẹ si.

Wọn pada ri ẹrọ arofoonu lagbara naa, ṣugbọn wọn ti lu ọmọ ti wọn ro pe o ji i pa.

Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, wọ́n dáná sun ilé

Iku oro ti wọn fi pa Chinonso naa pada di rogbodiyan, gẹgẹ bi alaye awọn eeyan agbegbe naa.

Wọn ṣalaye pe awọn eeyan fi ẹhonu han, wọn si sọ ina si awọn ile ati ṣọọbu lagbegbe naa.

Ṣugbọn ṣa, awọn ẹbi Oloogbe Chinonso ti fi ẹsun naa to ọlọpaa leti.

Iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun, awọn ọlọpaa si ti nawọ gan awọn afurasi kan ti wọn ni wọn lọwọ ninu iku naa.

Wọ́n kórira ọmọ mi ni wọ́n ṣe pa á - Baba Chinonso

Nigba to n ṣalaye fun BBC nipa iku ọmọ rẹ, Ọgbẹni Collins Amadi, sọ pe awọn to korira ọmọ oun ni wọn lu u pa.

Amadi sọ pe ọkan ninu awọn to lu Chinonso pa ti nija pẹlu rẹ tẹlẹ,nibi ti ọmọ naa ti n ṣiṣẹ nileeṣẹ kan.

"Ọrọ power bank to ṣẹlẹ yii, aarin ọmọ mi ati ọrẹ rẹ kan lo wa, ṣugbọn awọn ẹṣọ ileeṣẹ naa gbe e lọ siwaju igbimọ ibilẹ.

"Ti ẹ ba wo fidio ibi ti wọn ti n lu ọmọ mi, ẹ maa gbọ ti ẹṣọ ibẹ n sọ pe oun ti n wa ọmọ mi tipẹ, ati pe anfaani ree foun lati mu un."

Baba Oloogbe Chinonso lo ṣalaye bẹẹ.

Baba naa darukọ ẹnikan, Chiazo, o ni oun lo pa ọmọ oun.

Amadi fi kun un pe ogbologboo apaayan ni Chiazo, ki i ṣe ọmọ oun lo kọkọ pa.

O ni gbogbo ọna loun yoo gba lati ri i pe oun gba idajọ ododo lori iku Chinonso Amadi.

Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, igbiyanju lati ba ileeṣẹ ọlọpaa Imo sọrọ ko kẹsẹjari.