'Kò sí ibi tí ààbò wà' - Àwọn èèyàn Cameroon há sí àárín àwọn Sọ́jà àti ajìjàgbara
- Author, Nick Ericsson
- Role, BBC Africa Eye
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9
Ngabi Dora Tue, ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́, ni kò lè tíì dá dúró fúnra rẹ̀.
Pósí ọkọ rẹ̀, Johnson Mabia wà láàárín àwọn èrò tí wọ́n ń kẹ́dùn ikú ọkùnrin náà ní Limbe, ẹkùn gúúsù ìwọ̀ oòrùn Cameroon - ẹkùn tó ti ń kojú irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Nígbà tó ṣe ìrìnàjò láti ibiṣẹ́ ni ọwọ́ àwọn alájàǹgbilà tẹ Johnson, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba tó gbọ́ èdè òyìnbó, àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ márùn-ún míì.
Àwọn alájàǹgbilà ọ̀hún tí wọ́n ń jà fún òmìnira ẹkùn méjì tí wọ́n ti ń sọ èdè òyìnbó ní orílẹ̀ èdè Cameroon, tí ìjà yìí sì ti ń sún mọ́ ọdún mẹ́wàá báyìí, tó sì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
Èdè Faransé ni wọ́n ń sọ jùlọ ní Cameroon.
Nígbà tí wọ́n mú Johnson sí àhámọ́ ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, Dora gbìyànjú láti wá ọkó rẹ̀ rí àmọ́ nígbà tí àwọn alájàǹgbilà náà padà kàn si, wọ́n ní kó mú $55,000 (£41,500) láàárín wákàtí mẹ́rìnlélógún láti fi tú ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni Dora tún gba ìpè míì láti ọdọ̀ ẹbí ọkọ rẹ̀ kan tó sọ pé "kí n tọ́jú àwọn ọmọ mi, pé ọkọ mi ti kú. Mi ò mọ nǹkan tó yẹ kí n ṣe. Ọjọ́ Ìṣẹ́gun ló ṣe ìrìnàjò, wọ́n pa á lọ́jọ́ Ẹtì," Dora sọ fún BBC.
Àwọn alájàǹgbilà náà kò kàn ṣekúpa Johnson nìkan, wọ́n gé orí rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ̀, tí wọ́n sì ju òkú ara rẹ̀ tókù sí ẹsẹ̀ títì.

Ìpìlẹ̀ àwọn ìwà àjàngbìlà tó ń wáyé yìí ni ó ṣe é tọpinpin sí ọdún 1961 nígbà tí orílẹ̀ èdè Cameroon gba òmìnira àti ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè kan ṣoṣo fún Cameroon láti ọwọ́ àwọn òyìnbó ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Faransé lọ́dún 1972.
Láti ìgbà náà ni àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Cameroon ti ń fapá jánú lórí ìgbàgbọ́ wọn pé ìjọba fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ẹ̀tọ̀ àwọn. Johns]on jẹ́ aláìṣẹ̀ tó fara kásá ìjà àgbà méjì láàárín àwọn tó ń jà fún ara wọn àti ìgbòyànjú ìjọba láti paná ìjà ọ̀hún.
Ogun tó ń wáyé báyìí ti bẹ̀rẹ̀ láti bíi ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.
Ní ìparí ọdún 2016 ni ìwọ́de àláfíà bẹ̀rẹ̀ lòdì sì lílo ètò ìdàjọ́ àwọn tí wọ́n ń sọ èdè Faransé ní àwọn ilé ẹjọ́ tó jẹ́ ti ẹkùn èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ètò ìdàjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ẹkùn ti Faransé àti Gẹ̀ẹ́sì ń l]o.
Ìwọ́de náà tàn kíákíá, èyí tó ṣokùnfà títi àwọn iléeṣẹ́ àti ṣọ́ọ̀bù nígbà náà.
Bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ṣe dáhùn sí ìwọ́de náà lágbára púpọ̀, tó sì yé – wọ́n lu ọ̀pọ̀ èèyàn, tí wọ́n sì fi àwọn míì sí àhámọ́. Àjọ ìṣọ̀kan Africa, African Union, AU pé ìkọlù ní àìlo ìwà ipá bí ó ṣe yẹ.
Iléeṣẹ́ ètò ààbò Cameroon kò fèsì sí ẹ̀sùn yìí àtàwọn míì tó wà nínú ìròyìn yìí.
Ìgbédìde àwọn ẹgbẹ́ alájàǹgbilà bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ọdún 2017 fi ń parí lọ, àwọn adarí ikọ̀ alájàǹgbilà ti kéde òmìnira fún orílẹ̀ èdè tí wọ́ pè ní Federal Republic of Ambazonia.

Oríṣun àwòrán, AFP
We used to wake up in the morning to dead bodies on the streets. Or you hear that a house has been set ablaze”
Títí di àsìkò yìí, àwọn èèyàn tó tó mílíọ̀nù márùn-ún ni wọ́n tik ó sínú ìdààmú ní ẹkùn tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Cameroon èyí tó jẹ́ ìdá kan nínú ìdá márùn-ún àpapọ̀ òǹkà àwọn èèyàn tó ń gbé Cameroon.
Kò dí ní èèyàn 6,000 tó ti padánù ẹ̀mí wọn, tí ọ̀pọ̀ sì tún ti sá kúrò nílé.
"A máa ń jí bá òkú àwọn èèyàn lójù títì ni," Blaise Eyong, tó jẹ́ akọ̀ròyìn láti Kumba, gúúsù ìwọ̀ oòrùn Cameroon, ẹni tó ti ṣe àkójọ ìròyìn lọrí láàsìgbò náà fún BBC Africa Eye, tó sì tún tis á kúrò ní ilé rẹ̀ pẹ̀lú ẹbí láti ọdún 2019.
"Tàbí kí ẹ gbọ́ pé wọ́n ti dáná sun ilé. Tàbí kí ẹ gbọ́ pé wọ́n ti jí èèyàn kan gbé lọ. tàbí kí wọ́n ti gé ẹ̀yà ara èèyàn lọ. Báwo ni èèyàn ṣe lè máa gbé nínú ìlú tó jẹ́ pé inú fu àyà fu ni èèyàn ń wà lójoojúmọ́ pé ṣé ààbò wà fún àwọn ẹbí ẹni?
Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ti gbà láti parí aáwọ̀ yìí tó fi mọ́ èyí tí ìjọba pè ní "ìjíròrò tó lágbára" lọ́dún 2019.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjíròrò náà bí ipò tuntun fáwọn ẹkùn méjéèjì tó jẹ́ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì èyí tó ṣàfihàn ìtàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọn, síbẹ̀ ohun péréte ni wọ́n rí yanjú.
Felix Agbor Nkongho – agbẹjọ́rò tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó darí ìwọ́de lọ́dún 2016, ti wọ́n padà nawọ́ gán – sọ pé àwọn igun méjéèjì ṣeń hùwà bíi ẹni pé kò sí ẹni tó le báwọn wí lórí ìwà wọn.
"Ìgbà kan wà… tó jẹ́ pé àwọn máa ń lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn alájàǹgbilà tí wọ́n bá nílò ààbò," ó sọ fún BBC Africa Eye.
"Àmọ́ láti bíi ọdún méjì báyìí, mi ò rò pé ẹnikẹ́ni tí orí rẹ̀ bá pé kan máa lọ sọ́dọ̀ àwọn alájàǹgbilà náà fún ààbò. Ṣé gbogbo wa gbọdọ̀ kú tán kí wọ́n tó fún wa ní òmìnira, ta ni wọ́n fẹ́ máa ṣe ìjọba lé lórí gan-an?
Ṣùgbọ́n kìí ṣe àwọn alájàǹgbilà nìkan ni wọ́n ń fẹ̀sùn títẹ ẹ̀tọ́ àwọn lójú mọ́lẹ̀ nìkan kàn.
Àwọn àjọ bíi àjọ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ èèyàn Human Rights Watch ti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ báwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ṣe ń dáhùn sí ìpè fún òmìnira ẹkùn náà. Wọ́n ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jó ìlú, tí wọ́n sì ń fi ìyà jẹ àwọn èèyàn, fífi òfin gbé èèyàn lọ́nà àìtọ́ àti ìpànìyàn nínú ogun tí àwọn ará ìta kò rí .
Àpẹẹrẹ àwọn ìfìyàjẹni tí ìjọba lọ́wọ́ sí kò ṣòro láti rí rárá.

Àwọn ológun Cameroon fi John (kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan) àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ sí àhámọ́ fẹ́sùn pé wọ́n ra ohun ìjà ogun fáwọn alájàǹgbilà.
John ní lẹ́yìn tí wọ́n fi àwọn sí àhámọ́ tán, wọ́n fún àwọn ní ìwé kan láti buwọ́lù tí wọn kò sì fún àwọn láàyè láti kan ohun tó wà nínú ìwé náà.
Nígbà tí wọ́n kọ̀ láti tọwọ́bọ ìwé náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní fìyà jẹ wọ́n gidigidi.
"Ìgbà yẹn ni wọ́n pín wa sí yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n fìyà jẹ ọ̀rẹ́ mi. Ẹ kàn ma ma gbọ́ tí wọ́n ń na èèyàn káàkiri. Níṣe ló dàbí pé èmi ni wọ́n ń nà ni. Wọ́n na èmi náà gidi. Nígbà tó yá ni wọ́n sọ fún mi pé ọ̀rẹ́ mi ti tọwọ́bọ ìwé, àwọn sì ti fi sílẹ̀."
Ṣùgbọ́n irọ́ ni wọ́n pa.
Lẹ́yìn oṣù kan ni wọ́n mú ọkùnrin míì wọ inú yàrá ọgbà ẹ̀wọ̀n tí John wà. Ó sọ fún John pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti kú sí yàrá tí wọ́n ti ń fìyà jẹ ẹ́. Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà ni wọ́n fi John sílẹ̀ láì gbe lọ sílé ẹjọ́ kankan.
"Ìbẹ̀rù ni mo fi ń gbé ayé nítorí mi ò mọ ibi tí mo máa ti bẹ̀rẹ̀ tàbí ibi tí ààbò wà fún mi láti tún ìgbé ayé mi bẹ̀rẹ̀ tàbí báwo," John sọ.
Lára àwọn ìlànà táwọn alájàǹgbilà náà ń lò láti fi kan ìyẹ́ apá ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ni fífi ]ofin de ètò ẹ̀kọ́ èyí tí wọ́n ní ìjọba ń lò láti fi máa parọ́ àti tan àwọn èèyàn.
Ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2020, ìkọlù kan wáyé sí ilé ẹ̀kọ́ ní Kumba. Kò sí ẹnikẹ́ni tó jáde láti sọ pé àwọn ló ṣe iṣẹ́ náà àmọ́ ìjọba di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn alájàǹgbilà náà. Àwọn ọkùnrin fi àdá àti ìbọn ṣe ìkọlù sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ pa ó kéré tán ọmọdé méje.
Ìkọlù náà awuyewuye, fún ìgbà díẹ̀, káàkiri àgbáyé, tí wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà náà.
"Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ni ẹkùn yìí wọ́n ti tìpa," akọ̀ròyìn Eyong sọ.
"Ìran kan ló ń pàdánù lórí ètò ẹ̀kọ́ báyìí. Ẹ wòye ipa tí èyí máa ní lórí agbègbè wa àti orílẹ̀ èdè wa lápapọ̀."

À fi bí ẹni pé làásìgbò tó ń wáyé láàárín ìjọba àtàwọn alájàǹgbilà náà kò tó, àwọn míì tún ti dìde ogun. Àwọn ọmọ ọlọ̀tẹ̀ kan ti dìde ogun ní agbègbè àwọn alájàǹgbilà náà láti gbógunti àwọn Ambazonian lójúnà àti mú Cameroon wà ní ìṣọ̀kan.
Adarí ikọ̀ yìí, John Ewome tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Moja Moja máa ń ṣaájú àwọn ikọ̀ rẹ̀ ní ìlú Buea láti wá àwọn alájàǹgbilà kí wọ́n tó nawọ́ gan nínú oṣù Karùn-ún ọdún 2024.
Wọ́n fi ẹ̀sùn títẹ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ kan òun náà àti fífi ìyà jẹ àwọn ará ìlú tó bá kẹ́fín pé wọ́n ń ṣe àtìlẹyìn fáwọn alájàǹgbilà náà. Ó jiyàn àwọn ẹ̀sùn yìí bí ó ṣe ní òun kò fi ọwọ́ kan aráàlú kankan rí àyàfi àwọn Ambazonians tí òun sì gbàgbọ́ pé àwọn alálẹ̀ wà pẹ̀l;u òun.
Bẹ́ẹ̀, ìwà ìjínigbé àti ìpànìyàn ṣì ń tẹ̀síwájú.
Joe (kìí ṣe orúkọ rẹ̀ gangan), bíi ti Johnson, wọ́n jí òun náà gbé láti gbin ìbẹ̀rù sọ́kàn àwọn èèyàn àti láti máa fi pa owó
"Mo wọ inú ilé, mo ba ìyàwó àtàwọn ọmọ mi nílẹ̀ tí ọ̀gá àwọn ọmọ ogun sì wà nínú yàrá ìdáná mi pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́. Wọ́n ti kó gbogbo àwọn ará àdúgbò, mo mọ̀ pé èmi lókàn bẹ́yẹn," Joe sọ.
Ó ní wọ́n kó òun àtàwọn mẹ́ẹ̀dógún míì wọnú igbó lọ, tí wọ́n sì pa èèyàn méjì lójú òun àmọ́ tí òun padà móríbọ́ nígbà táwọn ọmọ ogun ṣàwárí ibùdó náà.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí wọ́n sìnkú Johnson ni ìròyìn gbòde pé wọ́n rí òkú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ márùn-ún yòókù tí wọ́n jọ jí wọn gbé.
Ọ̀pọ̀ àwọn ẹbí ló máa gba kádàrá lórí àdánù wọn báyìí. Fún Ngabi Dora Tue, tó jókòó pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ lẹ́sẹ̀, ọjọ́ iwájú jẹ́ ẹrù tó wúwo láti gbé fún-un.
"Mo ni ọ̀pọ̀ gbèsè tí mo fẹ́ san, mi ò mọ bí mà á ṣe san wọ́n," ó sọ.
"Mo rò ó láti máa ta ara fún owó àmọ́ nígbà tí mor o ìtìjú tó máa ti ara rẹ̀ jáde mo pinnu láti máa kojú ìṣòro náà bí agbára mi ṣe mọ. Ọjọ́ orí kékeré ni mo fi di opó.

BBC kàn sí ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbò Ambazonia Defence Forces, ADF, fún èsì.
Wọ́n ní ọ̀pọ̀ àwọn olùyapa alájàǹgbilà ló ń ṣiṣẹ́ ní ẹkùn tí wọ́n ti ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì .
ADF ní àwọn ń tẹ̀lé ìlànà òfin àgbáyé láti ṣiṣẹ́ àti pé àwọn kìí ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àtàwọn akọ̀ròyìn.
ADF di ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ru àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn, tí wọn kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ ADF.
Bákan náà ni wọ́n fi ẹ̀sùn kan ìjọba pé àwọn náà ń ṣiṣẹ́ láabi tí wọ́n ń fi ẹ̀sùn rẹ̀ kan àwọn ọmọ ogun Ambazonian nítorí wọ́n fẹ́ kọ ẹ̀yìn aráàlú sí wọn lòdì sí ìjà òmìnira tí wọ́n ń jà.

















