Trump ní ààrẹ Russia ti "ya wèrè gidi" pẹ̀lú àdó ikú tó jù sílẹ̀ Ukraine, tó pa èèyàn bíi 1000

Awọn panapana n pana nibi iṣẹlẹ ado oloro

Oríṣun àwòrán, @Ukraine government

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump, ti kede pe "inu oun ko dun" rara si bi aarẹ ilẹ Russia, Vladimir Putin, ti se ikọlu to lagbara julọ si orilẹede Ukraine.

Lasiko to n kọju oro, eyi ti ko fi bẹẹ wọpọ tẹlẹ, si ilẹ Russia, Trump ni "Ki lo n sẹlẹ si na? O n pa ọpọlọpọ eeyan o".

Lẹyin eyi lo wa se apejuwe aarẹ ilẹ Russia, Vladimy Putin gẹgẹ bii "ẹni to ti ya were gidi".

Saaju ni aarẹ ilẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti ke gbajare saaju pe aifọhun ilẹ Amẹrika lori awọn ikọlu ti Ukraine n se si orilẹede oun lo n se iwuri fun aarẹ Putin lati maa tubọ se ikọlu naa siwaju.

O wa n rọ ilẹ Amẹrika lati seto ijiya to gbopọn fun orilẹede Russia, ko le dẹkun ikọlu to n se si Ukraine naa.

Ado oloro ti oju ọrun bọ lati Russia sori Ukraine, araalu to to ẹgbẹrun kan dero ọrun

Pẹlu bi ija ajaku akata ṣe n waye laaarin orilẹede Russia ati Ukraine, Aarẹ Volodymyr Zelensky, ti Ukraine, ti sọ pe didakẹ ti orilẹede America dakẹ si ija naa lo n fun Russia lagbara lati maa kọlu awọn lọ.

Yatọ si America, Aarẹ Zelensky tun sọ pe aifọhun awọn orilẹede agbaye yoku naa tun n fun Aarẹ Russia, Vladimir Putin, lagbara ikọlu si Ukraine si i.

Zelensky sọrọ yii lẹyin ti ado oloro ti oju ọrun jabọ lati Russia, to sọlẹ si Ukraine, pẹlu òkò iku to to irinwo (400) niye.

O kere tan, araalu ẹgbẹrun kan (1,000) ni iroyin sọ pe ado oloro naa pa.

Aarẹ Zelensky sọ pe Russia ko ni i yee ta ẹjẹ awọn alaiṣẹ ọmọ orilẹede Ukraine silẹ, afi bawọn ba le koju Moscow ti i ṣe olu ilu Russia.

Ikọlu oru mọju ti Russia se si Ukraine fi han pe wọn fẹ pa ilu naa run pata ni - EU

Ninu alaye Kaja Kallas to n ri si ọrọ ilẹ okeere fun 'European Union', o ni ikọlu oru mọju ti Russia kọlu Ukraine, fi han pe wọn fẹẹ pa ilu naa run pata ni.

O rọ awọn to n ranṣẹ ado oloro lati Moscow lati dẹkun ikọlu si Ukraine.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji ọdun 2022 ni Russia fipa wọ Ukraine ninu ogun to le ju ninu itan ilẹ Europe latigba ti ogun agbaye keji ti waye.

Bo tilẹ jẹ pe ọdun 2014 ni aigbọra ẹni ye kọkọ bẹ silẹ laaarin awọn orilẹede meji yii, ti ija si ti wa nilẹ, 2022 ni gbogbo ẹ burẹkẹ titi di asiko yii.