Àdo olóró bú gbàmù nínú ọkọ̀ tó kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́, márùn-ún nínú wọn kú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan, marun-un ninu awọn akẹkọọ kan ti wọn wa ninu ọkọ bọọsi ile-ẹkọ wọn ni wọn ti di oloogbe bayii, lẹyin ti ado oloro bu gbamu ninu ọkọ naa lorilẹede Pakistan.
Agbegbe Khuzdar, ni Balochistan ni iṣẹlẹ naa ti waye, gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe ṣalaye fun BBC .
Bi wọn ṣe wi, mẹta ninu awọn akẹkọọ to di oloogbe naa ni wọn jẹ ọmọde.
Wọn fi kun un pe o to ogoji akẹkọọ ti bọọsi naa ko, ati pe awọn to farapa pọ.
Aworan ijamba naa to n lọ lori ayelujara, ṣafihan bi bọọsi yii ṣe jona, ati baagi ikowesi awọn akẹkọọ to fọn kalẹ kiri.
Ta ló wà nídìí ìkọlù yìí?
Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe ko sẹni ti yoo fi ọbẹ to nu jẹsu, bẹẹ naa ni ko ti i si ẹgbẹ kankan ninu awọn onijagidijagan agbegbe naa to jẹwọ pe oun lọwọ si ikọlu yii.
Ohun ti ọpọ mọ agbegbe Balochistan yii fun ni pe ibẹ ki sinmi ogun.
Ilu to wa ni Guusu-Iwọ Oorun yii ni a gbọ pe o pẹ ti wọn ti n koju ikọlu ati ifiyajẹni.
Minisita ọrọ abẹle ni Pakistan, Mohsin Naqvi, koro oju si ikọlu yii. O ni ohun ti ko ṣe e gbọ rara ni.
"Awọn ẹranko to n dọdẹ ọmọde lati ko idaamu ba orilẹede."
Minisita ọrọ abẹle naa lo ṣapejuwe awọn to ṣekọlu ọhun bẹẹ.
Ni ti awọn ṣọja Pakistan, India to jẹ alamuleti wọn ni wọn n naka aleebu si, bo tilẹ jẹ pe ko si ẹri kankan lati fidi ẹ mulẹ pe, awọn ni wọn wa nidii ikọlu naa.
Tẹ o ba gbagbe, Pakistan ati India ṣẹṣe n bọ́ ninu ikọlu ọlọsẹ meji kan ti wọn ba ara wọn fa ni.
Eyi waye nigba ti awọn ṣọja kọlu awọn arinrinajo afẹ kan nibi ti wọn n pe ni India-administered Kashmir.
Bo tilẹ jẹ pe Pakistan ni oun ko mọ nipa awọn ikọlu yii, India ri i daju pe oun da ikọlu tirẹ pada fun Pakistan ati agbegbe rẹ.
Nibẹrẹ oṣu Kẹta, araalu mọkanlelogun ati ṣọja mẹrin ni wọn pa lasiko ti wọn dọdẹ wọn ni Balochistan, nibi ti a mọ si ẹkun-un Sibi.
Ikọ kan ti wọn n pe ni Balochistan Liberation Army (BLA), ajijagbara to n ja fun ominira, lo ṣeto ikọlu ọhun.
Orilẹede Pakistan ati awọn ilu mi-in bii UK ati US ti fi ontẹ agbesunmọmi lu ẹgbẹ BLA .
Ṣugbọn awọn Baloch naa ti fẹsun kan awọn ologun Pakistan pe wọn n ṣọṣẹ pẹlu.
Wọn ni ẹgbẹrun eeyan Baloch ni awọn ologun Pakistan ti sọ di awati lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin.
Wọn ni wọn fi wọn si ahamọ lai gbe wọn de kootu. Awọn eeyan naa sọ pe Pakistan ji awọn eeyan ilu awọn kan gbe, wọn fiya jẹ awọn mi-in, wọn si pa awọn kan nitori wọn n beere ominira.














