JAMB kéde ṣíṣe ìdánwò UTME fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó forúkọsílẹ̀ àmọ́ tí kò ríbi kópa níbi èyí tó kọjá

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìdánwò

Oríṣun àwòrán, JAMB

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Àjọ tó ń rí sí ètò ìdánwò sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, Joint Admissions and Matriculation Board ti kéde ṣíṣe ètò ìdánwò UTME míì fáwọn tí kò ríbi kópa níbi ìdánwò tí wọ́n ṣe kọjá.

Ìdá márùn-ún nínú àwọn tó yẹ kó jókòó fún ìdánwò ni kò ríbi kópa níbẹ̀ fún ìdí kan tàbí òmíràn.

Adarí àjọ JAMB, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq Oloyede ló kéde èyí lọ́jọ́rú níbi ìpàdé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ tó wáyé nílùú Abuja níbi tó ti sọ pé gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ọ̀rọ̀ kàn ni àwọn máa fún ní àǹfàní láti kópa níbi ìdánwò náà láì fi ìdí tí wọn kò fi kópa ṣe.

Ó ní gbogbo àwọn tí wọn kò ríbi kópa níbi ètò ìdánwò náà lákọ̀ọ́kọ́ ni wọ́n máa ní àǹfàní Láti kópa ètò náà.

"Kìí ṣe ohun tuntun, ní gbogbo ibikíbi ní àgbáyé, tí àkẹ́kọ̀ọ́ kò bá ní àǹfàní láti kópa níbi ìdánwò, wọ́n máa ń fún láàyè léti tun ṣe nígbà tí wọn kò bá ti ṣi àǹfàní náà lò."

Oloyede tẹmpẹlẹmọ pé ìdánwò UTME kìí ṣe ìdánwò láti fi mọ bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe dáńtọ́ tó bíkòṣe láti fi rí sí ọ̀rọ̀ gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sílé ẹ̀kọ́ gíga èyí tí kò lè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tán.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn kan ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìdánwò náà, Oloyede ní báwọn kan ṣe ń sọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti bu ẹnu àtẹ́ lu ètò àjọ náà kò dára tó.

Ó ní òun gba gbogbo kùdìẹ̀kudiẹ tó wáyé níbi ètò ìdánwò náà mọ́ra nítorí ohun tó yẹ kí adarí rere ṣe nìyẹn, kìí ṣe pé nítorí òun kùnà.

"Mi ò mọ̀ pé àwọn le máa fojú ẹlẹ́yàmẹ̀yà wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìdánwò ọdún yìí. A nílò láti kọjá ipele bẹ́ẹ̀."

Bákan náà ló kan sáárá sáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe ìdánwò náà àtàwọn òṣìṣẹ́ JAMB fún ìforítì wọn lásìkò ìpèníjà náà.

Ó sọ pé kò sí àkókò fún àwọn àti pé tí àwọn kò bá tètè kojú ìpèníjà náà ní kíákíá, ó ṣeéṣe káwọn pàdánù àkókò náà.

Ó fi kun pé láìpẹ́ ni ètò ìdánwò náà máa wáyé àti pé JAMB ní ìfarajìn sí ṣíṣe ètò ìgbaniwọlé sílé ẹ̀kọ́ gíga tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀.

Lónìí ni èsì ìdánwò JAMB táwọn akẹ́kọ̀ọ́ 379,000 tún ṣe yóò jáde

Aworan awọn akẹkọọ to n ṣedanwo JAMB

Oríṣun àwòrán, JAMB

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lonii ni ajọ JAMB to n ṣagbatẹru idanwo UTME ati wọle si ile ẹkọ giga fasiti atawọn ile ẹkọ giga mii ni Naijiria yoo gbe esi idanwo tọdun 2025 yii tawọn akẹkọọ ẹgbẹrun lọna ọrinlelọọdunrun o din mẹta,379,997 tun ṣe jade.

Ṣaaju ni ajọ JAMB kede iye awọn akẹkọọ naa wi pe wọn yoo tun idanwo wọn ṣe nitori aṣiṣe to waye lati ọwọ JAMB eyi to ṣakoba fun esi idanwo akọkọ ti wọn ṣe.

Awọn akẹkọọ ẹgbẹrun lọna ọrinlelọọdunrun o din mẹta, 379,997 yii lo tun idanwo ọhun ṣe nipinlẹ marun un lẹkun ila oorun guusu Naijiria ati nipinlẹ Eko lọjọ kẹrindinlogun si ọjọ kejidinlogun ọsẹ to kọja.

Ajọ JAMB kede igbesẹ lati tun idanwo naa ṣe lẹyin ti ajọ naa gba wi pe ọwọ awọn ni aṣiṣe eyi to jẹ ki ọpọ akẹkọọ gba maaki to kere ninu idanwo naa ti wa.

Ti ẹ o ba gbagbe, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, to jẹ ọgagba JAMB tọrọ aforijin lọwọ araalu pẹlu omije loju lori aṣiṣe to waye.

Ọjọgbọn Oloyede ni oun loun jẹbi gbogbo aṣiṣe ati kudiẹ-kudiẹ to waye ninu esi idanwo ti JAMB gbe jade.

Ṣaaju ni ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa awọn ti esi idanwo naa kan gbọngbọn, ti bọ sori ayelujara lati fi ẹdun ọkan wọn han.

Ọpọ akẹkọọ lo ni esi idanwo tawọn gba kọja gan-an ko buru to ti 2025 yii.

Akọle kan ti i ṣe #thisisnotmyresult, ni awọn eeyan naa lo lati fi aidunnu wọn han, ti wọn si pe fun atunyẹwo esi idanwo yii.

Esi ti JAMB fi sita kede pe bii miliọnu kan aabọ akẹkọọ (1.5 million candidates), ni ko gba to maaki igba (200) ninu idanwo naa.

Itumọ eyi ni pe ida ọgọrin (80%) akẹkọọ ni ko gba maaki igba ninu irinwo (400).

Iṣẹ mẹrin ti maaki ọkọọkan jẹ ọgọrun-un (100) ni awọn akẹkọọ naa jokoo ṣe ninu UTME, apapọ rẹ lo jẹ irinwo (400).

Ẹwẹ, awọn obi atawọn akẹkọọ kan to ṣe idanwo UTME naa ti kepe ajọ JAMB tẹlẹ lati fagile gbogbo esi idanwo ti wọn gbe jade lẹyin ti ajọ naa sọ pe aṣiṣe wa ninu esi idanwo naa.

Awọn eeyan yii tun tako igbesẹ ajọ JAMB lati tun idanwo naa ṣe nipinlẹ Eko ati lawọn ipinlẹ ẹkun ila oorun guusu Naijiria nikan.

Awọn obi atawọn akẹkọọ naa ni ko dara fawọn akẹkọọ kan lawọn ipinlẹ perete ni Naijiria da idanwo naa tun ṣe papaa julọ pẹlu kudiẹ kudiẹ ti ajọ naa sọ pe o waye lati ọwọ wọn.