''Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé èmi nìkan ni akẹ́kọ̀ọ́ tó dá wà ní kíláàsì láti 100l dé 400l''

Àkọlé fídíò, Mojoyinoluwa, akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣìrò tó dá wà ní kíláàsì láti 100l dé 400l
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pẹlu idunnu ati ayọ ni Adeuyi Rhema Mojoyinoluwa fi wọ ile-ẹkọ Fasiti Bamidele Olomilua University of Education, Science and Technology, ikere-Ekiti lọdun 2020/2021. Ṣugbọn idunnu naa gba ọna miran nigba to kiyesi, to si han gbangba pe, oun nikan ni akẹkọọ ni kilaasi rẹ.

Ẹka eto ẹkọ ti wọn ti n kọ nipa imọ iṣiro fun awọn ileeṣẹ, eyi ti wọn n pe ni Industrial Mathematics, ni Ọdọmọbinrin Rhema, ti kẹkọọ ni fasiti BUESTI.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, o ni oun kọkọ ni ireti pe awọn akẹkọọ miran yoo darapọ mọ oun ti yoo ba fi de ipele 200l, amọ ọrọ ko ri bẹẹ.

Adeuyi Rhema Mojoyinoluwa nikan lo da kẹkọọ lati ipele 100l titi to fi ṣetan ni 400l.

O ni ẹkọ nipa imọ ẹrọ lo wu oun lati kọ, amọ maaki to gba nigba to fẹ wọ fasiti naa lo mu ko pada ṣe imọ nipa iṣiro.

"Inu mi kọkọ dun nigba ti mo wọ ile-ẹkọ, ti mo si ri i pe emi nikan ni. Mo kọkọ ni ifọkanbalẹ, nitori pe iru nnkan bẹẹ ti ṣẹlẹ si mi ri."

Adeuyi Rhema ṣalaye pe oun nikan ṣoṣo ni obinrin laarin awọn akẹkọọ nigba to wa ni ile-ẹkọ girama.

O ni oun ti kọkọ lero pe iriri naa yoo ran oun lọwọ lati da nikan ṣe iṣẹ ni kilaasi rẹ ni yunifasiti.

"O le diẹ fun mi lati jẹ akẹkọọ kan ṣoṣo ni kilaasi mi, paapaa ti ẹkọ mi ko ba ye mi, ti ko si si ọrẹ tabi akẹẹgbẹ mi ti mo le lọ ọ ba lati la a ye mi tabi jọ kawe pọ.

Adeuyi Rhema

Oríṣun àwòrán, Adeuyi Rhema

Ẹni to jẹ olori ẹka eto-ẹkọ Industrial mathematics, Temitayo Emmanuel sọ fun BBC pe iyalẹnu lo jẹ nigabti awọn mọ pe akẹkọọ kan ṣoṣo ni awọn ni ni saa eto ẹkọ 2020/2021.

Ọgbẹni Emmanuel sọ pe ọrọ naa l'agbara lasiko kan deebi pe, Rhema ko fẹ ẹ wa si kilaasi mọ nitori irẹwẹsi ọkan.

O ni ṣugbọn, awọn to jẹ olukọ rẹ lo tun ma n wa a lọ sile lati fa a pada pẹlu ifẹ. O ṣalaye pe aṣeyọri rẹ jẹ nnkan idunnu fun awọn.

Bakan naa lo tun sọ pe ọmọdebirin naa ko hu iwa ibajẹ tabi eyi to tako ti ọmọluabi titi to fi kẹkọọ tan.

Arabinrin Adeuyi Rhema sọ pe iranlọwọ awọn olukọ oun lo mu ki oun pada ṣe aṣeyọri lẹnu ẹkọ.

Ninu erongba rẹ fun ọjọ iwaju, o ni ti yoo ba fi to ọdun marun un si mẹwaa si asiko yii, oun ti fẹ ẹ ni iwe ẹri ipele keji (Masters /Degree) ati Phd.

"Eyi yoo mu mi jẹ nnkan iwuri ati awokọṣe fun awọn ọmọbinrin to n bọ lẹyin mi, paapaa bo sẹ jẹ pe imọ iṣiro ni mo kọ, to si jẹ emi nikan ni mo wa ni kilaasi mi titi mo fi kawe tan."