Ọmọ ọdún mẹ́ta rèé, tó ń ṣe irun lóge pẹ̀lú àrà oríṣiríṣi
Ọmọ ti yóò bá jẹ́ àṣàmú, kékeré ló ti máa ń ṣenu ṣámúṣámú.
Èyí ni ọ̀rọ̀ Lordina Nancy, ọmọ ọdún mẹ́ta tó ti yan iṣẹ́ irun ṣíṣe láàyò ní orílẹ̀ èdè Ghana.
Amina Yukubu, ìyá Nancy Lordina sọ fún BBC pé nítorí ọmọ òun ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe máa ń wá ṣe irun ní ṣọ́ọ̀bù òun.
Ó ní tí àwọn èèyàn bá ti rí àrà tí ọmọ náà ń dá pẹ̀lú irun lórí ayélujára ni wọ́n máa ń wá sí ṣọ́ọ̀bù láti wá ṣerun lọ́dọ̀ rẹ̀.

Lára irun tí ọmọ náà lè ṣe ni "rasta" àti ká fọ irun.
Amina Yukubu sọ pé lọ́jọ́ kan tí Nancy dé láti ilé ẹ̀kọ́ tó bá àwọn níbi tí àwọn ti ń ṣerun fún oníbàárà kan ló darapọ̀ mọ́ àwọn níbẹ̀ tó sì ń ṣerun náà lọ.
Ó ní láti ìgbà náà ló ti máa ń ṣerun fáwọn èèyàn láì ṣe wí pé àwọn kọ níṣẹ́.
Ìyá Nancy ní òun ń gbìyànjú láti ri pé iṣẹ́ tí ọmọ náà ń ṣe kò di lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé rárá àti pé yóò ní àǹfàní láti yan iṣẹ́ tó bá wù ú lọ́jọ́ iwájú.



