Nnamdi Kanu ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sun ìgbésùnmọ̀mí bí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́tun níwájú adájọ́ tuntun

Nnamdi Kanu
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi igbẹjọ tuntun ṣe bẹrẹ lọjọ Ẹti fun Nnamdi Kanu, ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra, o ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun igbesunmọmi tijọba Naijiria fi kan oun.

Ileẹjọ giga ilu Abuja ni igbẹjọ naa ti waye, lẹyin ti Kanu ti i ṣe olori ẹgbẹ IPOB ti sọ pe ki Adajọ Binta Nyako ma gbọ ẹjọ naa mọ.

Ṣaaju ni Nnamdi Kanu ti fi ẹsun ṣiṣe ojuṣaaju kan Adajọ Nyako lori igbẹjọ rẹ naa.

Adajọ James Omotosho lo n gbọ ẹjọ naa bayii.

Tẹ o ba gbagbe, ijọba Naijiria lo fẹsun kan Kanu pe o fẹẹ da oju ijọba bolẹ, pẹlu idasilẹ ẹgbẹ 'Indigenous People of Biafra' (IPOB) to n ja fun.

Ẹgbẹ IPOB jẹ ẹgbẹ kan to fẹẹ ya kuro lara Naijiria, ti wọn fẹẹ da duro lapa Ila-Oorun orilẹede yii bii Biafra.

Eyi lo mu ijọba kede ẹgbẹ naa bii agbesunmọmi lọdun 2017

Nnamdi Kanu ni kootu

Kí ló ṣẹlẹ̀ ní kóòtù lónìí?

Lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta ọdun 2025 ti igbẹjọ tun waye, Nnamdi Kanu loun ko jẹbi ẹsun meje to da lori igbesunmọmi ti wọn fi kan oun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Adajọ Omotosho ko fi ọrọ falẹ, nitori ẹjọ yii ti pe ọdun mẹwaa ti wọn ti n ba a bọ.

O sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹrin, ọjọ keji ati ikẹfa oṣu Karun-un ọdun 2025, pe ki igbẹjọ naa bẹrẹ pẹrẹwu.

Bakan naa ni agbẹjọrọ fun Nnamdi Kanu, Kanu Agabi, to ti figba kan jẹ olootu eto idajọ ri lorilẹede yii, tọrọ aforiji lọwọọ Adajọ Binta Nyako, nipa bi Kanu ṣe sọrọ si i pe o n ṣe ojuṣaaju.

O ni ibinu ni Kanu fi sọrọ.

Lọọya Agabi loun tun tọrọ aforiji lọwọọ aṣoju ijọba, Oloye Adegboyega Awomolo, pẹlu awọn lọọya Kanu, nitori Kanu ko yọ ẹnikẹni silẹ lọjọ naa, gbogbo wọn lo sọrọ si.

Nigba to n fesi, Awomolo (SAN), sọ pe oun ti foriji Kanu, nitori oun ki i ṣe ẹlẹyamẹya, oun yoo si ṣe iṣẹ oun bo ṣe yẹ.

Bakan naa ni Adajọ James Omotosho, tọrọ aforiji lorukọ Nnamdi Kanu.

Adajọ sọ pe ẹni ọdun 47 ni Kanu nigba to bẹrẹ ẹjọ yii ni 2015, o si ti pe ẹni ọdun 57 bayii lẹnu ẹjọ kan naa.

O lo yẹ ki Kanu binu bi ẹjọ rẹ ṣe fa nilẹ titi to si ṣe bẹẹ pe ọdun mẹwaa.

Igbẹjọ yii yoo bẹrẹ ni tuntun ni bayii, nitori bi adajọ tuntun ba gba ẹjọ kan, bo ti wu ko ti pẹ nilẹ to, wọn yoo ṣẹṣẹ bẹrẹ rẹ pada ni tuntun ni.

Ẹsun mẹẹẹdogun ni wọn kọkọ fi kan an, Adajọ Binta Nyako lo fagile mẹjọ ninu wọn.

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Díẹ̀ nipa ẹjọ́ náà

Latilẹ ni Nnamdi Kanu to n gbe ni London tẹlẹ ti maa n sọ pe o yẹ ki awọn eeyan apa Guusu-Ila-Oorun Naijiria ya kuro lara orilẹede yii, ki wọn da duro.

Redio Biafra to wa ni London ati oju opo ayelujara rẹ lo ti maa n kede erongba rẹ yii.

Loṣu Kẹwaa ọdun 2015, awọn agbofinro DSS, mu un nigba to wa si Naijiria. Muhammadu Buhari lo wa nipo aarẹ nigba yẹn.

Wọn fi ẹsun iwa ọdaran nla kan an pẹlu awọn mẹrin mi-in.

Wọn lo n fi Redio Biafra kede ohun to le da Naijiria ru.

Wọn sọ Kanu si gbaga ẹwọn Kuje, l'Abuja titi di oṣu Kẹrin ọdun 2017 ti Adajọ Binta Nyako fi aaye beeli silẹ fun un nitori ilera rẹ to n ṣojojo.

Ṣugbọn o paṣẹ pe Kanu ko gbọdọ ba awọn oniroyin sọrọ, ko si gbọdọ si lawujọ ti eeyan ibẹ ju mẹwaa lọ.

N100M ati oniduuro mẹta ni wọn fi faaye beeli silẹ fun un nigba naa.

Ọkan lara awọn oniduuro naa si gbọdọ jẹ eeyan nla ninu ijọba, gomina Anambra bayii, Ṣenetọ Enyinnaya Abaribe, wa lara awọn to duro fun Kanu nigba naa.

Kanu pada kuro nibi ti wọn ti le ri i, o ni awọn ṣọja kan fẹẹ pa oun nigba ti wọn wa sile oun lasiko ti wọn n ṣe 'Operation Python Dance.'

Ikólu naa gẹgẹ bi Kanu ṣe wi, lo fa iku baba ati iya rẹ.

Awọn mejeeji ku tẹle ara wọn laaarin oṣu meji ni, iyẹn oṣu Kẹwaa si Ikejila ọdun 2019.

Loṣu Kẹwaa ọdun 2018 ni Kanu de pada pẹlu awọn aworan ati fidio ibi to ti gbadura nilẹ mimọ ti i ṣe Jerusalem, abala ẹsin Judaism to n ṣe lo fi han sita.

O pada si London o si bẹrẹ si i kede Biafra rẹ pada.

Afi loṣu Kẹfa ọdun 2021 ti awọn agbofinro gbe e ni Kenya, ti wọn si fipa gbe e pada si Naijiria.

Bayii ni ẹjọ rẹ bẹrẹ pada niwaju Adajọ Binta Nyako, ẹni to ti fofin de beeli to fun Kanu lati 2017.

Ijọba fi ẹsun mẹẹẹdogun kan Kanu, eyi to loun ko jẹbi eyikeyi ninu rẹ, ki Adajọ Nayako too ba a ge mẹjọ danu ninu rẹ, to ku meje.

Awọn lọọya Kanu nigba naa, ti Amofin agba Mike Ozekhome n lewaju fun, gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ Ko-tẹ-mi-lọrun, wọn lo yẹ kile ẹjọ kekere fagile ẹjọ ọhun ni.

Kootu Ko-tẹ-mi-lọrun gba bi wọn ṣe wi, o fagile awọn ẹsun naa.

Ṣugbọn ijọba apapọ gba ile ẹjọ to ga ju lọ lọ, nibẹ ni wọn si ti da ẹjọ naa pada sile ẹjọ giga.