Ta ló gbé Adura, àbúrò Mohbad lọ lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ní kóòtù?

Iya Mohbad, Yomi Fabiyi ati aburo Mohbad

Oríṣun àwòrán, Collage

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Adura Aloba to jẹ aburo fun Oloogbe Ilerioluwa Aloba (Mohbad), ni iroyin sọ pe awọn kan ti gbe lọ bayii, lẹyin igbẹjọ kan to waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2025.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbegbe kootu Majisreeti to wa l'Ogba, nipinlẹ Eko ni awọn to gbe Adura ti gbe e.

Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro ni wọn lo gbe aburo Mohbad, iya rẹ, Abosede Aloba, figbe bọnu pe Yomi Fabiyi, oṣere tiata ati ajafẹtọọ ọmọniyan lo gbe oun lọmọ lọ.

Yatọ si Adura, wọn tun gbe ọrẹ rẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ibrahim Koleosho( King White) naa lọ.

Nipa ohun to gbe aburo Mohbad de kootu, foonu kan ti wọn lo ta fun ẹnikan to n jẹ Damola Ayinde lo di ẹjọ ti Adura n jẹ naa.

Báwo ni bi ọlọpaa se gbe Adura ṣe kan Yomi Fabiyi?

Lati ibẹrẹ iku Mohbad ni Yomi Fabiyi ti n lewaju ninu bi wọn yoo ṣe ri idajọ ododo fun un, ti wọn yoo si fi oju ẹni to pa a han.

Ninu ilakaka rẹ naa lo ti ni Adura ba oun sọrọ loju opo Instagram lọjọ Kẹtala, oṣu Kejila ọdun 2024.

Yomi Fabiyi sọ pe ọrọ ti Adura ba oun sọ ni pe fidio bi Mohbad ṣe ku wa lọwọ oun (Lọwọ Adura).

O ni aburo Oloogbe n beere miliọnu mẹta naira nilana owo ori ayelujara ti a mọ si Bitcoin, ko too le fi fidio naa silẹ.

Ṣugbọn Adura sọ pe irọ ni Fabiyi pa mọ oun, o ni Damola Ayinde toun ta foonu fun lo n ba Yomi sọrọ nigba naa, kii se oun.

Ọrọ naa lo di wahala loṣu Kin-in-ni ọdun yii laarin Iya Mohbad ati Fabiyi.

Iya Mohbad pariwo le Yomi lori nibi ipade oniroyin agbaye kan to waye lori iku Mohbad, o ni ko ma tun jẹ ki Adura bọ mọ oun lọwọ bii ẹgbọn rẹ o.

Oloogbe Mohbad ati iya rẹ, Abosede Aloba

Oríṣun àwòrán, Mohbad/Facebook/Instagram

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Mohbad ati iya rẹ, Abosede Aloba

Yomi Fabiyi ló gbé ọmọ mi lọ, ọmọ Naijiria, ẹ gbà mí -Iya Mohbad

Ninu fidio kan to gun ori afẹfẹ l'Ọjọruu ti wọn gbe Adura lọ, Iya rẹ n ke lohun rara ninu mọto ayọkẹlẹ kan.

'' Ẹ gba mi gbogbo ẹyin tẹ n pe Ọlọrun, ẹ gba mi o, Yomi Fabiyi ni o.

Yomi Fabiyi ti gbe ọmọ mi lọ o, mi o mọ ibi ti wọn gbe ọmọ mi lọ o, Yomi Fabiyi ni o.

Yomi Fabiyi ni ati Sam Jojo, wọn ti gbe ọmọ mi lọ o, ọmọ mi o ṣe nnkan kan o.

Ẹyin ọmọ Naijiria, wọn o gbọdọ na ọmọ mi, wọn o gbọdọ fọwọ kan an o, ara rẹ o ya o, ẹ gba mi o.''

Bẹẹ ni Iya Adura n sunkun, to si n kigbe ninu fidio naa.

Bakan naa lo sọrọ nipa Damola ti wọn lo ra foonu lọwọ Adura.

O ni ọmọkunrin naa lo ko oun si wahala, nigba ti iya tiẹ wa nile, to n sun jẹjẹ.

Mọlẹbi awọn Mohbad kan naa fidi ẹ mulẹ, pe awọn ko ri Adura latigba ti wọn ti gbe e lọ.

O ni awọn ko si mọ ibi to wa lati Ọjọruu ti wọn ti gbe e lọ.

Atẹjade ti Yomi Fabiyi fisita

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram

Àlàyé rèé láti ẹnu Yomi Fabiyi

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n fesi si ẹsun ti Iya Mohbad fi kan an, Yomi Fabiyi ninu atẹjade to fi si oju opo Instagram rẹ, ṣalaye pe ki ẹnikẹni ma ṣe da obinrin naa lohun rara.

Yomi sọ pe ọna lati ba oun lorukọjẹ, ki iwadi ọlọpaa si kuna lati kẹsẹjari ni Iya Mohbad n wa to fi n pariwo ninu mọto.

O ni ọna lati da oju idajọ ododo bolẹ ni Iya Adura n wa.

'' Adura Aloba, Damola Ayinde ati Habeeb Damilare Koleosho lẹjọ lati jẹ tẹlẹ lori ẹsun iku ti ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2 n ṣe.

''Wọn ti kọwe pe Adura ati Damola lẹmẹẹta ti wọn ko yọju, Damilare Koleosho lo n ba ọlọpaa to wa nidii ẹjọ naa sọrọ to si n sọ idi toun ko fi ni i yọju. Awọn yooku wọn ti sa lọ.

''Awọn ọlọpaa ba kootu sọrọ, wọn gba iwe aṣẹ lati le mu wọn, wọn si mu wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta 2025 lai tẹ ofin kootu loju, wọn ko mu wọn ninu ọgba kootu''

Bẹẹ ni apa kan atẹjade Fabiyi wi.

O fi kun un pe Adura tiẹ figba kan sa sinu kootu titi, ti ko jade ki wọn ma baa mu un. Igba to jade sita naa ni awọn ọlọpaa gbe e bi Yomi Fabiyi ṣe ṣalaye.

Oṣere tiata naa tẹsiwaju pe iṣẹlẹ naa ṣoju Iya Adura, awọn ọlọpaa si fi aaye gba a lati maa tẹle mọto keji bọ bi wọn ṣe n gbe ọmọ rẹ lọ.

Yomi Fabiyi sọ pe Iya Adura mọ nipa mimu ti awọn ọlọpaa waa mu ọmọ rẹ.

O ni wọn gba ki mọto ti iya Mohbad wa ninu rẹ maa bọ lẹyin eyi ti ọmọ rẹ wa pẹlu awọn ọlọpaa.

Fun idi eyi, Fabiyi ni ki araalu ma ṣe gba Iya Mohbad to fẹẹ ba oun lorukọ jẹ gbọ, to si tun fẹẹ ko ba iṣẹ iwadii ti awọn ọlọpaa n ṣe.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀dọ́ méjì tó já bàálù gbà torí ìbò June 12 bá BBC sọ̀rọ̀

Baba Mohbad pe ẹjọ́ tako ìtúsílẹ̀ Naira Marley, Sam Larry àti Prime Boy lórí ikú ọmọ rẹ

Mohbad

Oríṣun àwòrán, iammohbad

Ọgbẹni Joseph Aloba, baba to bi olorin kasufe to di oloogbe Ilerioluwa 'Mohbad' Aloba, ti gba ile ẹjọ lọ lati wọgile aba olori ikọ olupẹjọ nipinlẹ Eko, DPP, lori iku ọmọ rẹ.

Aloba n pe ẹjọ naa lorukọ ara rẹ ati lorukọ mọlẹbi rẹ.

Agbẹjọro baba Mohbad, Ọmọwe Wahab Shittu (SAN), bẹ ile ẹjọ giga to wa ni Ikeja, lati da aba naa nu latari pe ko fun awọn ti ọrọ naa kan lafaani lati sọ ti ẹnu wọn nile ẹjọ gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin Naijiria.

Ọkunrin naa sọ ninu iwe ipẹjọ rẹ pe ọpọ eeyan lo gbagbọ pe iku lati ọwọ Ọlọrun ni ọmọ oun ku lọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan an ọdun 2023, lo jẹ ki oun pe fun iwadii iku lati mọ ohun gan to gbẹmi rẹ n pato.

Baba Mohbad ni eyii lo fa a ti wọn ṣe bẹrẹ ẹjọ niwaju adajọ T.A.Shotobi ninu oṣu kan naa lọdun 2023 ọhun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbẹjọ naa ko tii ni iyanju titi di asiko yii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, adajọ Ejiro Kubenhe to jokoo nile ẹjọ majistreeti Ikeja ti dajọ awọn afurasi mẹrin gboogi ninu igbẹjọ naa Abdulazeez 'Naira Marley' Fashola, Samason Balogun 'Sam Larry' Eletu ati Owoduni Ibrahim ti ọpọ mọ si Prime Boy ko ni ẹjọ kankan lati jẹ.

O ni "Awọn afurasi ti wọn ni wọn ko ni ẹjọ kankan lati jẹ ọhun ni ọrọ lati sọ, wọn ti fi iwe pe wọn, o si yẹ ki won farahan lati sọ ohun ti wọn mọ ninu iku Mohbad."

Baba Mohbad sọ pe ọlọpaa ẹka CID, ASP Mohammed Yusuf, to ṣewadii ẹsun naa ni agọ ọlọpaa to wa Panti kopa ninu ayẹwọ oku ọmọ ọun, awọn agbẹjọro awọn ti wọn tu silẹ naa si mọ nipa rẹ pẹlu, nitori naa wọn ṣi ni ọrọ lati sọ.

Ọgbẹni Aloba sọ pe ile ẹjọ ni ki awọn afurasi ọhun maa lọ sile wọn lai jẹjọ lai naani iwadii iku ọmọ oun to n lọ lọwọ.

O wa ke si ile ẹjọ ọhun fun iranlọwọ ki kulẹkulẹ ohun to ṣekupa ọmọ rẹ le foju han faraye ki oloogbe naa le ri idajọ ododo gba.