APC fẹ́ kí Tinubu kéde ìlú kò fara rọ l‘Osun, Adeleke yarí

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke
Ijọba ipinlẹ Osun ati ẹgbẹ oṣelu PDP ti bu ẹnu atẹ lu ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ti akọwe ẹgbẹ naa, Ajibola Basiru, ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko kede ilu o fararọ ni Osun.
Kọmiṣọna fun iroyin nipinlẹ naa, Kolapo Alimi, juwe ipe ẹgbẹ oṣelu APC fun ilu o fararọ ni Osun gẹgẹ bii iwa imotaraẹni nikan ati eyii ti ko ba ofin mu.
Bakan naa, agbẹnusọ PDD ni Osun, Oladele Bamiji, fi ẹsun kan APC pe ni ṣe ni ẹgbẹ naa n wa ọna lati fi ipa gba agbara ijọba ipinlẹ Osun lọwọ Adeleke.
Ti ẹ ko ba gbagbe, rogbodiyan bẹ silẹ nipinlẹ Osun laarin ọsẹ diẹ sẹyin ṣaaju eto idibo ijọba ibilẹ, nibi ti eeyan mẹfa ti padanu ẹmi wọn ti won si gbe awọn ọọfisi kansu kan tipa nibẹ.
Wayi o, Kọmiṣọna fun iroyin nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi, ti sọ pe iyatọ gedegbe wa laarin ohun to ṣẹlẹ nipinlẹ Rivers ati eyii to waye l'Osun.
O ni ti wọ n ba gbe iṣẹlẹ ipinlẹ mejeji si ẹgbẹ ara wọn, awọn eeyan yoo ri pe kii ṣe nnkankan naa lo n waye nibẹ.
Kọmiṣọna naa gba APC nimọran lati dẹkun igbiyanju lati da omi alaafia ipinlẹ Osun ru latari igbiyanju rẹ lati fi ọna ẹburu gba agbara ijọba.
O ni "Mo ti ka ohun ti ẹni to n fi ipa wa agbara ati ẹni to maa n sorọ ṣakaṣaka, Sẹnetọ Ajibola Basiru sọ pe o yẹ ki Aarẹ Tinubu kede ilu o fararọ ni Osun gẹge bo ṣe ṣe nipinlẹ Rivers.
"Mo fẹ ki a mọ pe kii ṣe Basiru nikan lo ni irufẹ erongba yii lọkan bi ko ṣe gbogbo APC lapapọ atawọn alatilẹyin wọn ni Osun to jẹ pe ojojumọ ni wọn n wa ọna eburu lati gba ipo iṣakoso ijọba.
"Ṣugbọn lagbara Ọlọrun ati atilẹyin araalu fun ijọba Ademola Adeleke, gbogbo igbiyanju wọn yoo ja si pabo."
Lẹyin naa lo ke si Aarẹ Bola Tinubu ko ma naani igbiyanju awọn eeyan to ba n ko orin irufẹ igbeṣe bẹẹ si leti.















