Aráàlú yabo ọ́fíìsì gómìnà pẹ̀lú òkú èèyàn márùn-ún tí wọ́n ní afurasí darandaran pa l‘Ondo

Ọgọọrọ awọn olufehonuhan lọjọru, ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Kẹta yabo ọfiisi Gomina ipinlẹ Ondo ni Alagbaka n'ilu Akure lori iku awọn agbẹ marun-un kan ti wọn fẹsun kan pe o waye latọwọ awọn darandaran.
Awọn olufehonuhan naa sọ pe iha ko kan mi, ati aibikita ni Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa n hu lori iṣẹlẹ ipaniyan ati ijinigbe to n waye lagbegbe Ala, ijọba ibilẹ Ariwa Akure lati bii oṣu meji sẹyin.
Wọn ni eyi lo mu awọn ṣe ifẹhonuhan lọ si ọfiisi gomina naa.
Awọn olufehonuhan naa gbe oku awọn eeyan marun-un ti wọn fẹsun kan pe awọn afurasi darandaran naa pa dani, lọ si ọfiisi gomina lasiko ifẹhonuhan ọhun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, awọn afurasi darandaran naa ṣekupa awọn agbẹ yii ni idaji ọjọru pẹlu ẹsun pe awọn darandaran naa ti kọkọ ṣekupa agbẹ ogun ni aba mẹrin nijọba ibilẹ kan naa nibi ọsẹ meji sẹyin.

"Ajinigbe tun ji ọmọ wa meji gbe lọ, ti wọn si n beere fun millionu mẹwaa naira fun itusilẹ wọn"
Lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Jayeoba Francis to jẹ ọkan lara awọn olori agbegbe naa sọ pe, wọn wa si ọfiisi Gomina latari awọn ikọlu to n waye ni agbegbe Ala, paapaa julọ bi awọn darandaran tun ṣe pa awọn marun-un miiran lowurọ ọjọru.
O sọ pe awọn gbe oku awọn eeyan naa dani wa si ọfiisi Gomina lati fi han Gomina kí wọn le ri pe ootọ ni awọn n sọ.
Ọgbẹni Jayeoba salaye pe saaju asiko yii, orisirisi ikọlu ni awọn n koju, tí awọn latọwọ awọn darandaran naa, ti wọn si tun n ba awọn nnkan oko wọn jẹ.
O sọ pe Igbakeji Gomina, Olayide Adelami ti seleri pe ni kete ti Gomina ba pade de lati irinajo, wọn yoo gbe igbese lori ọrọ naa
Bákan naa, Oloye Ayọ Fadare sọ pe lati bi ọsẹ meji ni awọn darandaran ti ba Aba awọn jẹ, ti gbogbo awọn olugbe aba Otọpe si ti sa asala fun ẹmi wọn.
Iyaafin Fadare sọ pe ,
O rọ ijọba lati ma ṣe faye gba awọn Fulani lati maa da awọn maalu wọn ni awọn igbo ọba nipinlẹ Ondo ni ibamu pelu igbese ti Gomina ana oloogbe Odunayo Akeredolu gbe.
Ki ni ìjọba àti ileeṣẹ Ọlọpaa sọ?
Lasiko to n ba awọn eniyan naa sọrọ niwaju ọfiisi Gomina n'ilu Akure, Igbakeji Gomina Ipinlẹ Ondo, Olayide Adelami sọ pe iṣẹlẹ Ipaniyan ati ijinigbe lagbegbe naa jẹ eyi ti ko bojumu ti ijọba yoo si ri daju pe opin deba.
Adelami wa pasẹ fun ajọ Amọtẹkun lati sagbekale oriko wọn si agbegbe naa lojuna ati le jẹ ki alaafia o jọba.
Igbakeji Gomina sọ pe awọn yoo ba awọn asoju mẹwaa lati agbegbe naa ṣe ipade lati le wa ojutuu si iṣẹlẹ Ipaniyan ati ijinigbe naa.
Bákan naa Kọmisọna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo Wilfred Afolabi sọ pe wọn ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri daju pe ọwọ tẹ awọn ọdaran to n domi alaafia Ipinlẹ Ondo ru.
Kọmisọna naa salaye pe ki awọn ara ilu fọkanbalẹ ki wọn ma si faye gba awọn kọlọransi ẹda lati raye ṣiṣẹ laarin wọn.
O seleri pe alaafia yoo jọba ni agbegbe naa laipẹ.















