Ààrẹ́ Israel ní ìkọlù ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, bí èèyàn mẹ́tàlá míì ṣe kú lásìkò ìkọlù sí Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O to eeyan mẹtala to tun ti padanu ẹmi wọn latari ikọlu tuntun ti Israel ṣe si orilẹede Gaza ni afẹmọju oni lẹyin ti Israel ni wọn ti pada si ogun jija pẹlu agbegbe Palestine.
Araalu meji ni wọn ṣekupa, ti eeyan marun un mii si farapa nigba ti ado oloro Israel kọlu ile kan ni tosi al-Mawasi, ileeṣẹ iroyin abẹle Wafa ṣalaye.
Ileeṣẹ Ologun Israel ni wọn ti n kọlu awọn ibudo Hamas.
Ikọlu yii lo waye lẹyin ti olootu ijọba Israel, Benjamine Netanyahu kede pe ogun ti bẹrẹ pada, to si jẹ ko di mimọ pe "A ṣẹṣẹ bẹrẹ."
Ado oloro naa ko to eyi to bu gbamu lọjọ Isẹgun eyi ti ajo eleto ilera ti kede pe eeyan irinwo lo padanu ẹmi wọn.
Ileeṣẹ iroyin Wafa ni obinrin kan ati ọmọde kan padanu ẹmi ni apa ariwa Khan Younisl lọjọ Iru
Ajọ eleto ilera Gaza ko ti kede pato iye eeyan to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu tuntun yii.
Israel ni Hamas si ni awọn eeyan to jẹ apapọ eeyan mọkandinlọgọta, ti wọn si gbagbọ pe eeyan mẹrinlelogun si wa laaye.
Bakan naa ni orilẹede Egypt ti bu ẹnu atẹlu ikọlu naa, ti wọn si fẹsun kan Israel pe wọn hu iwa tako ofin dida ọwọ ogun duro.
Hamas ni ọpọ awọn olori ẹgbẹ naa lo padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye lọjọ Isẹgun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Israel rọ òjò àdó olóró sí Gaza lásìkò tí wọ́n ń jí sààrì, èèyàn 400 dèrò ọ̀run
Saaju lati mu iroyin wa fun yin pe ileeṣẹ Ologun Israel sọ pe awọn ti bẹrẹ ikọlu to lagbara ni ẹkun Gaza, bi ileeṣẹ eto ilera eyi ti Hamas n ṣe amojuto rẹ ṣe sọ pe awọn ọmọ Palestine irinwo ni Israel ti ṣekupa ninu ikọlu ọtun naa.
Ileeṣẹ Ologun Israel, iyẹn Israel Defense Forces (IDF) sọ pe awọn ibudo awọn agbẹṣumọmi to jẹ ti ikọ Hamas ni awọn n ṣe ikọlu si.
Niṣe ni ikọlu naa n tẹsiwaju ti IDF si ti fi lede pe kawọn araalu ko kuro lawọn agbegbe kan.
Igbakeji minisita fọrọ abẹle ni Gaza, Mahmoud Abu Wafah ati ẹṣọ aabo ti ipo rẹ ga julọ fun Hamas wa lara awọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ọtun yii.
Ni ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Kiini, ọdun 2025 ni Israel ati Gaza fẹnuko lati dawọ ogun duro amọ ti o ti fori sọpọn bayii bi wọn ko ṣe gbọ ara wọn lori ifẹnuko naa.
Israel fẹsun kan Hamas pe wọn kọ lati tu awọn ọmọ Israel mọkandinlọgọta (59) to wa ni ahamọ wọn silẹ. Wọn ni gbogbo awọn eeyan yii ni Hamas fi si ahamọ nigba ti wọn ṣe ikọlu si Israel lọjọ Keje, oṣu Kẹwaa, ọdún 2023
Ṣaaju ni ijọba Hamas, to n ṣakoso Gaza Strip ti sọ pe ọọdunrun eeyan ati ọgbọn lo ti padanu wọn bayii lẹyin ado oloro ti Israel ju si ọdọ awọn lorumọju.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Israel, (IDF) sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi kan to n ba Hamas ṣiṣẹ loun n doju ija kọ pẹlu awọn ado oloro naa.
A gbọ pe lara awọn to ku ninu ikọlu ado oloro naa ni Mahmoud Abu Wafah, to jẹ igbakeji minisita fun ọrọ abẹle Gaza, to tun jẹ ọkan gboogi lara awọn adari Hamas.
Ikọlu yii ni eyii to tobi julọ ninu ikọlu Israel si Gaza lati igba ti won ti tọwọ bọ iwe adehun jogunomi lati ọjọ kọkandilogun, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii.
Amọ ṣa, gbogbo igbiyanju lati ṣe afikun ọjọ iye jogunomi naa lo ja si pabo laarin ikọ mejeji.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ pe asiko ti awọn fẹ bẹrẹ saare wọn, gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe ninu oṣu Ramadan ni ado oloro naa bẹrẹ si n rọ bii ojo.
O le ni ogun ọkọ ofurufu ileeṣẹ ologun Israel to n fo loke to si n ju ado oloro si aarin ilu Gaza City, Rafah ati Khan Younis.
Aarọ ọjọ Isẹgun ni olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu minisita eto abo, Israel Katz paṣẹ ki wọn bẹrẹ ikọlu ọhun.
Wọn ni Hamas kọ lati tẹle awọn ilana ti aṣoju aarẹ Amẹrika, Steve Witkoff la kalẹ lati ri pe ogun naa sinmi.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede, wọn ni "A gbe igbesẹ yii lẹyin ti wọn kọ lati lati jọwọ awọn eeyan wa to wa lakata wọn ati bi wọn ṣe kọ lati gba imọran alaafia ijọba Amẹrika.
"Lati akoko yii lọ, ileeṣẹ ọmọ ogun Israel yoo tẹsiwaju lati maa kọju ija si Hamas."
Aṣoju ijọba Israel si ajọ UN, Danny Danon, sọ pe "A ko ni fi oju aanu wo awọn ọta wa," lẹyin naa lo kilọ fun Hamas ko tu gbogbo awọn eeyan Israel to fi si ahamọ silẹ.
Amọ Hamas ti fẹsun ṣiṣe eke kan ijọba Israel latari bo ṣe kọ lati naani adehun jogunomi ti wọn fẹnuko le lori.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ile ijọba Amẹrika sọ fun ileeṣẹ iroyin Fox News pe ijọba Israle kan si Aarẹ Donald Trump ko to bẹrẹ si n ju ado oloro si Gaza.















