'Afurasí tó pa Mojisola Awesu ti láwọn ẹ̀sùn ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ lọ́dọ̀ ọlọ́pàá, ìgbà àkọ́kọ́ rẹ̀ kọ́ yìí'

Àwòrán Mojisola Awesu àti àwọn agbẹjọ́rò nílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Mojisola Oluwafunmike/TikTok/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ Aje, ọjọ Kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2025 ni igbẹjọ tun waye lori iku ọdọbinrin, Mojisola Awesu, akẹẹkọ, Health Tech Offa, ti wọn ba oku rẹ lori akitan ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.

Nibi igbẹjọ naa to n waye ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara to fi ikalẹ si ilu Ilorin ni awọn ẹlẹrii ti n sọrọ lori ohun ti wọn mọ lori iku ọmọbinrin naa.

Ọkan lara awọn olujẹrii ni ọlọpaa Gbadeyan Yinka, to ṣe ọrikiniwin iwadii lori iku Mojisola Awesu, sọ pe awọn ti mọ Happiness Adebayo ti o jẹ afurasí akọkọ lori iṣẹlẹ naa fun iwa ọdaran tẹlẹ.

Gbadeyan sọ fun ile ẹjọ pe wọn o ṣẹṣẹ maa gbe ẹsun ole jija nipa afurasi naa wa si agọ ọlọpaa ni ilu Offa.

O fi kun pe ẹsun ipaniyan to n lọ lọwọ yii ni ẹsun elẹẹkẹta ti oun yoo se lori Happiness Adebayo.

Happiness fi WhatsApp míì sórí fóònù láti dínbọ́n pé òun sin Mojisola wọ ọkọ Offa lẹ́yìn tó fi òkú rẹ̀ kalẹ̀ sí ilé ìtura - Ẹlẹ́rìí

O sọ eyi nigba to duro gẹgẹ bi ẹlẹrii kẹta ni ile ẹjọ giga Ilorin to si n salaye fun ileẹjọ naa bi oun se gba ọrọ ẹnu rẹ kalẹ ni Ileesẹ awọn.

Lẹyin ti ẹlẹrii naa ti salaye bi Blessing, ọrẹ Mojisọla ṣe mẹjọ wa si agọ ọlọpaa wi pe awọn n wa a, wọn mu Happiness wa si ọdọ oun lati bẹrẹ iwadii to peye.

Gbadeyan sọ fun ile ẹjọ pe lara ohun ti awọn ṣe awari rẹ nigba ti awọn n ṣe iwadii ni pe Happiness ṣe ayederu WhatsApp sori foonu rẹ lati fi si awọn eniyan lọna pe oun sin Mojisola kuro lọdó oun nigba to wa lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ni oun ba ara rẹ sọrọ lori WhatsApp keji to wa lori foonu naa bi iwi pe oun n ba Mojisola sọrọ, to si n sọ ọ lori WhatsApp naa pe Mojisola ti kuro lọdọ oun, to si lọ wọkọ lati pada si ilu Offa.

O ṣalaye pe WhatsApp meji lo wa lori foonu Happiness, o wa se ọkan ninu rẹ bii WhatsApp oloogbe, eleyii to fi n ba sọrọ lori rẹ fun ara rẹ lati fihan pe Mojisola ti kuro lọdọ rẹ, bẹẹ si ni o fi oku rẹ kalẹ si ile itura ti o gba.

Gbadeyan ni eyi lo mu ki o maa yẹ foonu rẹ wo lọ toun si ri atẹjisẹ ti baba rẹ, Adebayo Adeniyi, ti oun naa wa lara awọn olujẹjọ fi ranṣẹ si i.

Atẹjisẹ naa ka pe, "A wa ni ile ẹkọ rẹ lati gba ọ, emi nikan ni o le gba ọ, ma ṣe sa fun mi. Sa tọ mi wa ni ibẹrẹ ọrọ naa bayii ki o to fẹ kọja agbara rẹ nitori ogun ti o gbọdọ bori leleyii"

Eyi lo mu ki n lọ ba ọga mi, DPO wi pe ki a ṣe iwadii (location tracking) ibi ti foonu Mojisola wa, o si gba si mi lẹnu.

"Nigba ti a se tan, ibi tí o gbe jade ni agbegbe Oguse lẹyin ile ẹkọ Health Technology Offa.

"Lẹyin eyi ni DPO gbe ẹjọ naa lọ ẹka CID fun iwadii to peye.

Àwọn agbẹjọ́rò nílé ẹjọ́

Ọwọ́ ìyá Happiness ni a ti rí síìmù Mojisola - Ẹlẹ́rìí

Sugbọn ni ọjọ Kẹrinlelogun, osu Kẹjọ ọdun 2024, mo gbọ pe wọn mu arábìnrin kan, Bukọla Adeniyi, ti o jẹ mama Happiness, níbi to ti n fi sim Glo kan pamọ si inu iho ogiri alabaagbe rẹ.

"Igba ti mo mu obinrin lọ agọ wa, o jẹwọ fun mi pe oun yọ sim naa ninu iPhone toun ri ninu moto ọkọ oun.

"Moto naa ni wọn fi ko ẹru Happiness ọmọ wọn ni Summit University Offa, a ya si ile wọn lati mu foonu naa, foonu naa jẹ iPhone 11pro funfun.

"Igba ti a de agọ wa, mo fi sim naa si inu foonu kan mo si rii pe, sim naa jẹ ti oloogbe Mojisola.

"A gbe obirin naa ati awọn ẹri yii lọ si ẹka CID.

"Ohun ti mo ri ni pe, iya Happiness n gbiyanju lati bo ohun to le ran wa lọwọ gẹgẹ bi ẹri mọlẹ, ẹsẹ tirẹ ni èyí" ẹlẹri naa salaye.

Lẹyin awọn alaye Gbadeyan yii ni Adajọ Ile ẹjọ naa, Ibrahim Yusuf gba awọn ẹri yii wọle, to si sun igbẹjọ si ọjọ Kejidinlogun osu yii.