Mo tọrọ àforíjì lórí ọ̀rọ̀ tí mo sọ pé Eko ń rùn - Àgùnbánirọ̀

Oríṣun àwòrán, NYSC/X
Àgùnbánirọ̀ tó ṣe fídíò láti bu ẹnu àtẹ́ lu ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lórí ipò tí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà wà ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko fún ọ̀rọ̀ tí òun sọ pé ìpínlẹ̀ Eko ń rùn.
Lójú òpó Instagram rẹ̀ ni ọmọbìnrin náà ti sọ pé òun kò sọ pé ìpínlẹ̀ Eko ń rùn láti fi tàbùkù àwọn olùgbé Eko.
Ó ní gẹ́gẹ́ bí àlejò tí òun jẹ́, òun kàn sọ ìwòye òun nípa ìpínlẹ̀ Eko, tí òun kò mọ̀ pé àwọn tó ń rí ìpínlẹ̀ Eko bíi ilé máa gba ọ̀rọ̀ náà sódì.
Ó ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ òun yìí jẹ́ ojúnà láti pe àkíyèsí àwọn èèyàn sí nǹkan tí ó ń lọ ní orílẹ̀ èdè Naìjíríà fún ogúnjọ́.
Ó sọ pé òun gbèrò láti máa sọ̀rọ̀ nípa bí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ṣe dẹnu kọlẹ̀, tí òun sì ń fẹ́ káwọn ọmọ Nàìjíríà bá òun dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Àgùnbánirọ̀ náà sọ pé òun kò mọ̀ pé àwọn èèyàn máa tètè bá òun tẹ́wọ́gba fídíò tí òun ṣe ní ọjọ́ àkọ́kọ́ nítorí ogúnjọ́ ni òun fẹ́ fi ṣe fídíò.
Ó ní ìgbé ayé tó rọrùn ni òun ń wá fún ara òun àti pé tí òun bá wo ìpèníjà táwọn èèyàn ń kojú ń da omi tútù sọ́kàn òun.
Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa bèèrè fún ìgbé ayé rere, èyí tó rọrùn ju bí orílẹ̀ èdè yìí ṣe wà lọ.
Sowore, àwọn agbẹjọ́rò tẹ̀lé àgùnbánirọ̀ tó fòkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Tinubu lọ rí LGI

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore/Facebook/NYSC
Gbajúmọ̀ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó tún jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú African Action Congress, AAC, Omoyele Sowore ti kéde àtìlẹyìn rẹ̀ fún àgùnbánirọ̀ tó ṣe fídíò kan láti sọ̀rọ̀ nípa bí gbogbo nǹkan ṣe wọ́n ní Nàìjíríà.
Sowore nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sójú òpó X rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé sọ pé òun ti lọ bá ọmọbìnrin náà àti pé òun àti àgùnbánirọ̀ náà ni àwọn jọ lọ máa rí adarí ìjọba ìbílẹ̀ tó wà tó ránṣẹ́ pè é.
Ó ní òun àtàwọn agbẹjọ́rò kan ni àwọn jọ ń tẹ̀lé àgbùnbánirọ̀ náà láti lọ yọjú sí LGI rẹ̀.
Sowore sọ pé àwọn kò bá LGI náà ní ọ́fíìsì ní gbogbo àsìkò tí àwọn fi dúró dè é, tó sì jọ wí pé ó sá fún àwọn ni.
Ní òpin ọ̀sẹ̀ ni fídíò kan gba orí ayélujára níbi tí àgùnbánirọ̀ kan ti ń sọ̀rọ̀ lórí bí ọ̀wọ́ngógó ṣe ń ṣàkóbá fún òun tó sì ń mú ìpalára bá òun.
Àgùnbánirọ̀ tó fi òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ìṣèjọba Tinubu lẹ́ka ọrọ̀ ajé, figbe ta pé NYSC ń dúnkookò mọ́ òun

Oríṣun àwòrán, NYSC
Ọdọbinrin kan to n ṣe agunbanirọ lọwọ niluu Eko, ti di gbajumọ ọsan gangan lori ayelujara Naijiria lẹyin to ke gbajare sita lori bi eto ọrọ aje Naijiria ṣe dẹnukọlẹ.
Ninu fidio kan to ṣe lẹnu ọjọ mẹta yii ni agunbanirọ naa ti sọ pe gbogbo nnkan ti gbowo lori ati pe ko rọrun fun araalu lati ra ẹyin atawọn ounjẹ mii mọ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, Aarẹ Bola Tinubu ko ṣe daadaa to nibi to ba eto ọrọ aje Naijiria de, gbankọgbi iya lo si n jẹ araalu.
"Bi awọn kan ṣe n kan sara si agunbanirọ naa, ni ọpọ awọn mii n bu pe ko lẹtọọ lati maa sọrọ kobakungbe si ijọba tori pe o ṣi sin ilu lọwọ"
Agunbanirọ naa ni "Aarẹ Bola Tinubu, ijọba yin ko san araalu rara, Aarẹ buruku ni yin, Tinubu, Aarẹ buruku ni ọ.
"Ilu Eko n run gidi, ko si ibi ti eeyaan lọ niluu Eko ti kii run, ojo ni wa bi a ṣe kọ lati sọrọ soke lori awọn ohun ti ijọba n ṣe ti ko tẹ awa araalu lọrun."
Lẹyin to ṣe fidio naa tan ni ọpọ araalu bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori rẹ.
Bi awọn kan ṣe n kan sara si ọdọbinrin ọhun ni ọpọ awọn mii n bu ẹnu atẹ lu u pe ko lẹtọọ lati maa sọrọ kobakungbe si ijọba to wa lode latari pe o ṣi sin ilu lọwọ gẹgẹ bii agunbanirọ.
"Ajọ NYSC n dunkoko mọ mi lori fidio ti mo ṣe"
Ọjọ keji ti fidio naa jade lori ayelujara tan lo kede pe awọn alaṣẹ NYSC ipinlẹ Eko n dunkoko mọ oun ati pe wọn paṣẹ fun oun pe ki oun lọ yọ fidio naa kuro loju opo oun.
O ni "Ẹyin ọmọ Naijiria, ajọ NYSC ti n dunkoko mọ mi pe ki n má mẹnuba ọrọ naa mọ, laarin wakati mẹrinlelogun pere, ijọba ti n halẹ mọ mi bẹrẹ lati ọdọ awọn alaṣẹ NYSC.
"Ẹyin ọmọ Naijiria, wọn mọ orukọ mi o, wọn si mọ ibi ti mo n gbe, ẹ jọọ ti ẹ ko ba gburo mi mọ, ẹ mọ awọn ti ẹ maa di ẹbi ọrọ naa le lori, mi o ṣe ohun ti buru o!"
Agunbanirọ naa fi ohun obinrin kan lede ti obinrin naa si n pariwo mọ lori foonu pe ko lọ yọ fidio naa.
Yatọ si obinrin ọhun, awọn akẹgbẹ rẹ mii tun jabọ fun pe awọn alasẹ NYSC n wa latari fidio to ṣe nitori o lodi si ofin ki agunbanirọ maa sọrọ lodi si ijọba.
Amọ ṣa, ọdọbinrin naa sọ pe ohun ti ajọ NYSC sọ ni pe ki awọn ma darapọ mọ oṣelu, wọn ko sọ pe oun ko lẹtọ lati sọ ohun to n dun oun lọkan.
Mo gboriyin fun agunbanirọ naa fun igboya rẹ – Atiku Abubakar
Wayi o, lara awọn to ti gboriyin fun ọdọbinrin naa ni igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, to juwe rẹ gẹgẹ bii akinkanju ati ọmọ Naijiria rere.
Atiku lo fi ọrọ naa lede loju opo X rẹ.
Atiku sọ pe "Ori mi wu fun igboya ati oye rẹ - bi ko ṣe bẹru lati sọrọ soke lai ro ohun ti awọn alagbara yoo ṣe.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ PDP naa sọ siwaju si pe ni ṣe lo yẹ ki ijọba ṣatilẹyin fun agunbanirọ naa dipo ko maa halẹ mọ.
O ni "Dipo idunkokomọni, niṣe lo yẹ ki wọn ṣugba rẹ nitori o jẹ apẹrẹ rere fun ọjọ ọla.
"Ohun to ṣe n fi han pe awọn adari wa lọla ti wa laarin wa lonii, won si ṣetan lati tun ọjọ ọla wa ṣe.
Agunbanirọ to bu ijọba ko ṣisọ, ara n ni araalu lootọ - Ẹgbẹ oṣiṣẹ
Lara awọn mii to tun n ṣegbe lẹyin agunbanirọ naa ni ẹgbẹ oṣiṣẹ, TUC.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Festus Osifo, sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels pe bi ilu ṣe ri ti sun ọdọbinrin na lo mu ko sọrọ soke, nitori naa, ni ṣe lo yẹ ki ijọba kọ bo ṣe le fara da irufẹ ọrọ bẹẹ dipo ko maa halẹ mọ ẹni to ba sọrọ si.
O ni "Ẹ wo ọmọde to n ṣe agunbanirọ lọwọ, agbara wo lo ni lati doju ijoba bolẹ? Nitori naa, ohun to n dun un lọkan lo sọ sita."
Olori ẹgbẹ oṣiṣẹ ọhun tun sọ siwaju si pe bo tilẹ jẹ pe ko buru ti araalu ba fi ọrọ ranṣẹ si ijọba, ko yẹ ki wọn ti aṣeju bọ ọ.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ajọ NYSC ko tii sọ nnkankan lori ọrọ naa.
















