Ẹ fura o! Ìpínlẹ̀ Eko ló ń léwájú nínú àrùn Diphtheria, níbi tí èèyàn ogún ti kó o - NCDC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹka to n ri si ikapa ati idena arun lorilẹede yii, 'Nigeria Centre for Disease Control and Prevention (NCDC), ti kede pe ipinlẹ Eko lo n lewaju ninu ibi ti arun Diphtheria ti n ja ju ni Naijiria bayii.
Bakan naa ni NCDC fi kun un pe, eeyan mẹtalelogun mi-in ni wọn tun ti lugbadi arun naa ni Naijiria.
Gẹgẹ bi atẹjade ti NCDC fi sita loju opo wọn bii abọ iwadii arun naa lọsẹ kẹwaa, wọn ni o foju han pe ogun eeyan (20) ni Diphtheria ti kọlu l'Ekoo.
Ipinlẹ Katsina ni wọn ni eeyan mẹta lo tun ti lugbadi arun naa, eyi to mu apapọ rẹ jẹ mẹtalelogun.
Kí ló fa àjàkálẹ̀ àrùn Diphtheria lójijì?
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii ni iroyin gbode, pe arun Diphtheria bẹ silẹ nileewe King's College, nipinlẹ Eko, akẹkọọ kan di oloogbe latari rẹ.
Yatọ si ọmọ to ku naa, awọn mẹrinla mi-in tun balẹ sileewosan, nibi ti wọn ti gba n itọju.
Lẹyin eyi ni ijọba Eko bẹrẹ eto fifun awọn akẹkọọ ati awọn oṣiṣẹ ileewe naa ni abẹrẹ ajẹsara to le dena arun ọhun.
Ọga agba ileewe naa, Mogaji Zakaria, sọ pe awọn alaṣẹ ti gbe igbesẹ to le kapa Diphtheria, wọn si ti kan an nipa fun awọn eeyan lati maa lo ibomu.
Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Eko, Dokita Akin Abayomi, rọ awọn ara Eko lati fi ọkan balẹ.
O ni ohun gbogbo wa labẹ akoso, bẹẹ ni awọn ọmọ to wa nileewosan yoo too gba itusilẹ pẹlu alaafia ara.
Bí Diphtheria ṣe ti ṣọṣẹ́ ní Naijiria:
Akọsilẹ NCDC bo ṣe maa n jade lọsọọsẹ, tọka pe lati oṣu Karun-un ọdun 2022, si oṣu Kẹta ọdun 2025 yii, eeyan ẹgbẹrun kan ati okoolelọọdunrun o din kan (1319) ni Diphtheria pa ni Kano, Yobe, Katsina, Bauchi, ati Borno.
Laaarin ọsẹ kọkandinlogun, 2022, ati ọsẹ kẹwaa 2025, eeyan 42,642 ni wọn ni arun naa mu kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji, ati ijọba ibilẹ marun-din ni irinwo (350LGAs.)
Kano lo ti kọkọ n lewaju, eeyan 24,239 lo lugbadi ẹ nibẹ.
Yobe lo tẹle e, awọn ni 5,330, Katsina :4,237, Bauchi: 3,066 ati Borno: 3,058.
Àwọn wo ni Diphtheria ń mú jù?
Gẹgẹ bi alaye awọn onimọ nipa ilera, awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn wa laaarin ọdun kan si mẹrinla ni wọn wa ninu ewu arun Diphtheria ju.
Pẹlu eyi, iwadii sọ pe ida 19.3% ninu 4,981, nikan lo ti gba abẹrẹ ajẹsara pipe to le dena arun yii.
Ida 5.1% ni wọn ni iku to n ti ara diphtheria wa bayii ni Naijiria.
Diphtheria jẹ arun kan to maa n tete ràn.
Kokoro aifojuri Corynebacterium diphtheria, lo n ṣokunfa rẹ, o si maa n ran lati ara itọ́, kẹ̀lẹ̀bẹ̀, ikọ, fifi ọwọ kan ohun ti kokoro naa ti wa lara rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn apẹẹrẹ ti eeyan yoo maa ri ti Diphtheria ba kọ lu u ni:ki ọna ọfun maa dun eeyan, iba, ki ọrun wu, o si le di ona atẹgun ti eeyan n gba mí.
Bi eeyan ko ba tete karamaasiki arun yii, o le ṣe akoba fun kindinrin, ọkan, o si le mu iku wa.
Ọna abayọ bi awọn dokita ṣe wi ni : Imọtoto, yiyago fun ibi ti ero ba pọ si, gbigba abẹrẹ ajẹsara, gbigba itọju lasiko ati bẹẹ bẹẹ lọ.














