Ijọba Iran ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ láti mú àwọn obìnrin tó kọ̀ láti lo Hijab

Iran

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba Iran ti bẹrẹ si n lo imọ ẹrọ lati kan an nipa fun awọn obinrin laati maa mura gẹgẹ bii ojulowo Musulumi lorilẹede naa.

Awọn oluwadii kan ninu ajọ iṣọkan agbaye, United Nations lo fi ọrọ naa lede.

Wọn ni ẹrọ "drone" ni ijọba naa fi n ṣọ awọn obinrin ti ko ba lo hijab, bẹẹ ni wọn tun gbe aapu kan kalẹ ti araalu le maa lo lati fi ọrọ awọn obinrin to ba kọ lati lo hijab to ijọba leti.

Lara awọn ti wọn n fi ẹjọ wọn sun ijọba ni awọn to wa ninu ọkọ akero igboro atawọn ibomii.

Ilu bii Teran ati agbege ila oorun Iran wa lara awọn ibi ti wọn ti n lo ẹrọ "drone" lati maa ṣofintoto awọn ti ko lo hijab.

A gbọ pe ijiya to tọ ni wọn n fun awọn obinrin to ba tapa si ofin ọhun.

Lara awọn ijiya naa ni fifi ṣikun ofin mu wọn ati lilu niluu bara; fun awọn mii a gbọ pe wọn maa n fi ipa ba wọn lopọ ni ahamọ ti wọn ba fi wọn si.

Esi iwadii yii lo n waye lẹyin ti obinrin kan, Mahsa Amini, ku si ahamọ lọdun 2022 lẹyin ti wọn wu iwa ipa si i.

Awọn oṣojumi koro sọ pe ni ṣe ni awọn ọlọpaa ẹsin lu oloogbe naa niluu bara lasiko ti wọn fi ṣikun ofin gbe.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ni arun ọkan lo ṣekupa a, iku rẹ da ifẹhonuhan nla silẹ ninu eyii ti araalu fi n bere idajọ ododo lori iku rẹ.

Ọdun meji lẹyin iku Mahsa Amini, wọn ṣi n tẹ ẹtọ awọn obinrin loju mọlẹ ni Iran.

Ni fasiti Amirkabir to wa niluu Tehran, wọn ri kamẹra kan mọ ilẹkun abawọle rẹ to maa n ka oju awọn ti ko ba wọ hijab silẹ.