Àwọn aṣòfin buwọ́lu owó orí tuntun, àti bí àwọn ìjọba yóò ṣe máa pín-in

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin gbogbo awuyewuye to ti n waye lori owo ori ati ele ori ọja, Value Added Tax ti a mọ si VAT, ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti buwọlu iye ti yoo kan ijọba ipinlẹ ati ti ibilẹ kọọkan ni Naijiria.
Ọjọbọ, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹta ọdun 2025 ni igbimọ to n ri si owo ori nile igbimọ naa, ya ida marundinlọgọta (55%) fun awọn ipinlẹ gẹgẹ bii owo ti yoo maa bọ si apo wọn lati ara owo to ba wọle, nigba ti tijọba ibilẹ jẹ ida marundinlogoji (35%).
Èlé ori ọja ti i ṣe VAT ko yipada lẹyin ijiroro awọn igbimọ naa, wọn ni 7.5 % to wa naa ni yoo ṣi wa ti araalu yoo maa san.
Ipinnu yii waye lẹyin ti igbimọ to n ri si awọn owo ori mẹrin ti Aarẹ Bola Tinubu fi ṣọwọ sile igbimọ aṣofin agba loṣu Kẹwaa, ọdun 2024, jiroro lori rẹ.
Ẹ o ranti pe ofin owo ori mẹrin ti aarẹ gbe lọ nigba naa ni:
- Nigerian Tax Bill;
- Nigeria Tax Administration Bill;
- Joint Revenue Board Bill; ati
- Nigeria Revenue Service Bill.
Alaga igbimọ to jokoo lori ofin owo ori yii, Abiodun Faleke, ṣalaye pe ipele-ipele lawọn pin owo ori naa si.
O ni lẹyin ipade ita gbangba ọlọjọ mẹta to kan awọn eeyan lati ipinlẹ mẹrindinlogoji ti Naijiria ni, lawọn ṣẹṣẹ fi ẹnu ko si ipinnu yii.
Lapapọ, atunṣe mọkandinlogun (19) lo ni o waye, titi de ori eyi ti awọn gomina kan lawọn ko fẹ ko ri bẹẹ lapa Ariwa, ṣugbọn ti Aarẹ Tinubu sọ pe ilana to dara ju niyẹn.
Olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Tajudeen Abass, sọ pe eyi ni igba akọkọ ti abajade kan yoo jẹ itẹwọgba lati ọwọ gbogbo ọmọ ile.
Bàwo ni wọ́n ṣe pín in báyìí?

Oríṣun àwòrán, @NASS NIGERIA
Lara atunṣe to waye labẹ ofin owo ori naa bayii ni pe awọn ṣọja ko ni i maa sanwo ori mọ lati ara owo to ba n wọle fun wọn bii ajẹmọnu (Personal Income Tax).
Abala 77 ninu iwe atunṣe ofin owo ori naa ṣalaye pe:
Fun ijọba ipinlẹ, wọn yoo pin ida aadọta (50%) owo to ba wọle ni ọgbọọgba.
Ida ogun (20%), yoo wa fun bi wọn ba ṣe pọ to nipinlẹ naa, nigba ti wọn yoo gba ida ọgbọn ninu owo ori to n wọle lati ara ounjẹ ati nnkan lilo.
Wọn tẹnu mọ ọn pe ibi ti wọn ba ti n pawo wọle ju nipa ohun ti wọn n jẹ ni ijọba yoo fi pin in, ki i ṣe ibi ti wọn ti n fi owo ọhun ranṣẹ si apo ijọba.
Bakan naa lo ri fun ijọba ibilẹ ti yoo gba ida marundinlogoji (35%).
Bẹẹ ni wọn si tun fi kun iye ọjọ ti wọn yoo maa fi pese nọmba idanimọ owo ori araalu, Tax Identification Number.
Wọn sun un kuro ni ọjọ meji, o ti di marun-un bayii.
Ileeṣẹ to ba kogba wọle yoo maa fi oṣu mẹta sanwo ori to yẹ (Corporate tax filing)
Tẹlẹ, oṣu mẹfa ni ofin la kalẹ fun ileeṣẹ to ba kogba wọle lati fi sanwo ori to yẹ fun ijọba.
Ṣugbọn pẹlu atunṣe yii, wọn ti din in ku si mẹta lati din ofo to ṣe ileeṣẹ bẹẹ ku.
Bi aarẹ tabi gomina ba sanwo ori , awọn ile igbimọ aṣofin agba gbọdọ buwọ lu u, bi atunṣe yii ṣe wi.
Àwọn ti wọn kò ní í sanwó orí mọ́
Abala karundinlọgọrin (75), kede pe ki ẹnikẹni too ma sanwo ori mọ, ile igbimọ aṣofin agba gbọdọ fi ọwọ si i.
Abala 76 lo faaye gba Oluṣiro owo agba lorilẹede yii lati yọ awọn owo ori to ba yẹ ki awọn ileeṣẹ ijọba san ṣugbọn ti wọn kọ lati san.
Ile igbimọ aṣofin agba yoo si buwọ lu u lati ri bẹẹ.
Fun iṣoju-ṣẹyin, igbimọ yii gbero lati yan aṣoju mẹfa lati ẹkun mẹfẹẹfa Naijiria, ti wọn yoo jẹ adari fun ileeṣẹ to n pawo wọle labẹnu, FIRS.
Bẹẹ ni wọn yoo si tun yan aṣoju lati ipinlẹ kọọkan ati lati Abuja, ki gbogbo wọn le tẹle ilana ofin.
Labẹ ofin meji to ku to jẹ Nigeria Tax Bill ati, awọn ileeṣẹ yoo maa san 30% owo ori ti wọn ti n san tẹlẹ lọ, nigba ti awọn ti iṣẹ wọn ṣe pataki gan-an yoo maa san 25% fun ọdun marun-un .
Àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tí yóò jẹ anfaani owó ìdàgbàsókè
Awọn ileewe giga yoo gba 50%, Nigerian Education Loan Fund to n ri si ẹyawo lati gba ẹkọ yoo gba 3%.
Ẹka National Information Technology Development Fund yoo gba ida marun-un (5%), nigba ti National Agency for Science and Engineering Infrastructure yoo gba ida mẹwaa (10%.) ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọṣe to n bọ yii ni wọn yoo tun gbe ofin yii yẹwo fun igba ikẹyin nile igbimọ, eyi naa ni yoo si jẹ aṣekagba ti wọn yoo fi sọ ọ di ofin.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?
O ti to ọjọ mẹta kan ti Aarẹ Bola Tinubu ti gunle awọn atunṣe kan lori ọna tawọn araalu ati ijọba ipinlẹ n gba san owo ori, paapaa awọn owo to n ti awọn ipinlẹ wa ati bi wọn ṣe n pin wọn.
Lati ri i pe awọn ipinlẹ to n ṣiṣẹ bii Eerin ko maa jẹ ijẹ Ẹliri, ko si ma di pe araalu ti ko ri ṣenji gidi kojọ yoo maa san owo ori to gar ani Aarẹ sọ pe oun ṣe gbe igbesẹ atunṣe naa.
O yan awọn igbimọ lati ri si eyi, lẹyin to tig be awọn apa ibi ofin to fẹ atunṣe lorii wọn naa lọ sọdọ awọn aṣofin.
Wọnyi ni diẹ ninu alaye ohun to ti ṣẹlẹ ṣiwaju.
Ofin owo ori tuntun yii ko kan awọn alaini
Taiwo Oyedele, to jẹ alaga igbimọ to n ṣakoso owo ori tuntun naa ti sọ pe ko kan awọn alaini.
Nigba to n sọrọ niwaju awọn aṣofin, o ni awọn ọlọla nikan ni ọrọ naa kan, ati pe ofin ọhun tun waye lasiko yii lati ṣe atunṣe si kudiẹ-kudiẹ to wa ninu bi ijọba ṣe n pin owo ori ti araalu n san.
Oyedele sọ pe "Abadofin mẹrin to ṣe koko ni igbimọ yii gbe wa eyii ti afojusun rẹ jẹ lati ṣe atunṣe si eto owo ori wa.
"Ofin naa fẹ ko gbogbo ofin owo ori si abẹ ofin kan ṣoṣo, ki a mu irọrun ba bi araalu yoo ṣe maa san owo ori ki a si yọ awọn to n pa owo kereje kuro.
"Obadofin naa yoo ṣamulo bi a o ṣe maa fi imọ ẹrọ gba owo ori ati bi gbigba rẹ yoo ṣe rọrun."
Lorin ọrọ bi wọn ṣe n pin owo ori to n wọle laarin awọn ipinlẹ, Oyedele sọ pe bi wọn ṣe n pin owo ori naa lọwọ yii fi sẹgbẹ kan.
O ni eyii ko bojumu latari pe awọn ipinlẹ ti ọọfisi olu ileeṣẹ nla-nla wa nikan lo n gbadun rẹ.
Ọrọ naa ko kan aralu to n pa owo to din ni miliọnu kan wọle lọdun
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ofin tuntun naa ko ni kan awọn ti owo ti wọn n pa wọle ko to miliọnu kan naira laarin ọdun.
O ni "Lonii, a n gba owo ori lọwọ ẹni to n gba ₦30,000 loṣu, o n tumọ si pe irufẹ ẹni bẹẹ n pa ₦1,000 pere lojumọ, bawo ni eeyan ṣe le bọ ara rẹ pẹlu ₦30,000 lodidi oṣu kan?
"Ti irufẹ ẹni beo ba tilẹ n danikan gbe gan, yoo ṣaa wọ ọkọ, yoo ra ounjẹ, yoo san owo ile, bẹẹ ni yoo san owo ina mọnamọna. Nitori naa ko le rọrun fun wọn.
"Idi ree ti a fi n daba ofin pe ẹnikẹni to ba n pa ₦800,000 lọdun, pẹlu ₦200,000 gẹgẹ bii owo ile, ti apapọ rẹ jẹ bii miliọnu kan naira, pe ki irufẹ ẹni ma maa san owo ori mọ.
Wayi o, awọn araalu kan ṣi gbagbọ pe ilu le lọwọ yii, nitori naa kii ṣe asiko yii lo yẹ ki ijọba maa ronu ọna ti yoo fi gba lọwọ araalu.














