Ọ̀rọ̀ Sunday Igboho àti ìjọba àpapọ̀ gba ọ̀nà míràn yọ; Igboho tún ẹjọ́ pè

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajafẹtọọ ọmọniyan to tun jẹ ọkan gboogi lara awọn to n polongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, tun ti pe ẹjọ tako ijọba Naijiria ati awọn mii, nile ẹjọ to ga julọ.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2025, ni agbẹjọro fun Igboho, Yomi Aliu (SAN), gbe iwe ẹjọ naa lọ si ile-ẹjọ.

Agbẹjọro Agba fun Naijiria, ileeṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS, ati ajọ DSS nipinlẹ Oyo, ni wọn pe lẹjọ.

Ẹjọ tuntun yii gẹgẹ bi Amofin Aliu ṣe sọ, lo wa lati rọ ile-ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, pe ko paṣẹ fun gbogbo awọn ti Sunday Ighoho fi ẹsun kan, lati san awọn owo itunu ti ile-ẹjọ giga ni ki wọn o san fun un.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kini, oṣu Keje, ọdun 2021, ni awọn oṣiṣẹ alaabo ọtẹlẹmuyẹ DSS, yabo ile Sunday Igboho to w ani agbegbe Soka niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo.

Lasiko ikọlu naa ni wọn tiba awọn dukia rẹ jẹ, wọn pa eeyan meji, wọn si tun mu ọpọ eeyan lọ si atimọle.

Oṣu diẹ lẹyin iṣẹlẹ naa ni Sunday Igboho, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Yomi Aliu, pe ẹjọ , to si beere fun 500bn Naira gẹgẹ bi owo gba, mabinu, fun dukia rẹ ti ajọ DSS bajẹ.

Amọ ninu idajọ rẹ, adajọ to gbọ ẹjọ naa ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2021 bakan naa, Ladiran Akintola, buwọlu 20bn Naira pere, gẹgẹ bi owo ti ijọba yoo san fun un.

Ki lo wa ninu iwe ipẹjọ tuntun naa?

Ninu iwe ipẹjọ tuntun ti Igboho gbe lọ sile ẹjọ bayii, Amofin Aliu ṣalaye pe nnkan to gbe awọn lọ si ile-ẹjọ to ga ju lọ ni pe, ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ki ijọba o san gbogbo owo naa fun.

"A n pe ẹjọ tako idajọ ile ẹjọ kekere pe, ohun to ṣẹlẹ si Igboho ko tapa si ẹtọ rẹ gẹgẹ bi eniyan."

Diẹ lara awọn nnkan to tun wa ninu iwe ipẹjọ tuntun naa ni:

  • Boya ajọ DSS tẹ ẹtọ Igboho mọlẹ
  • Boya o bojumu bi ile-ẹjọ giga to kọkọ gbọ ẹjọ naa ṣe da gbogbo awọn ariwisi ti Sunday Igboho gbe lọ siwaju rẹ.
  • Lara oun ti wọn tun pe ẹjọ le lori ni lati mọ boya ile-ẹjọ giga naa jẹbi fun bo ṣe ni ko tọ si Sunday Igboho lati pe fun idasilẹ orilẹede miran gẹgẹ bi ofin African Charter ṣe la a kalẹ.
  • Ati pe boya ile-ẹjọ naa ṣe ayẹwo finni-finni lori awọn awijare Igboho, ko to o di pe o da ẹjọ to gbe ijọba apapọ

Yatọ si eyi, wọn ni awọn tun n fẹ ki ijọba mu ẹri to daju jade pe, Igboho lo ni awọn nnkan ijagun ti awọn oṣiṣẹ alaabo ni awọn b anile rẹ.