Obìnrin tó fi ilé onílé ṣe ìdúpẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì di èèrò ilé-ẹjọ́

Aworan Loveth Helen Alo ti a bo loju
Àkọlé àwòrán, Aworan Loveth Helen Alo ti a bo loju
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Obinrin kan, Loveth Helen Alo, ti foju ba kootu nipinlẹ Enugu bayii lori ẹsun pe o fi ile ti ki i ṣe tiẹ ṣe idupẹ ni ṣọọṣi Zion ministry to wa nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Enugu ṣe ṣalaye, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta ọdun 2025 ni wọn fi oju Loveth ba kootu.

Awọn ọlọpaa ṣalaye pe Loveth parọ pe miliọnu lọna igba naira, (200 million) ni oun ra ile naa.

Ninu alaye awọn ọlọpaa ni wọn ti sọ pe afurasi to n jẹjọ yii lọ si ile ijọsin Zion Ministry to wa ni ipinlẹ Eko, ninu oṣu Keji, to si jẹri si oore Ọlọrun pẹlu idupẹ pe, oun ti kọ ile nla si Enugu.

Nigba ti Pasitọ Ebuka Obi to n dari ile ijọsin naa ni ko jẹ ki gbogbo ijọ ri ile tuntun naa, Lovett fi aworan ati fidio ile kan han pẹlu ayika rẹ, eyi to jẹ kawọn eeyan gba a gbọ pe o ti di onile lootọ.

Ile to fi dupẹ naa jẹ eyi ti oloyinbo n pe ni duplex. O wa lojule kẹrindinlogun, WTC Estate, Enugu.

Báwo ni àṣírí ṣe tú?

Aworan kootu majisreeti ipinle Enugu

Lẹyin ọjọ diẹ ti afurasi naa ṣe idupẹ ni ṣọọṣi ni ẹni to ni ile gan-an, Ọgbẹni Jude Asogwa, tako idupẹ naa.

Ọgbẹni Asogwa sọ pe ile oun ni Loveth fi ṣe idupẹ, yoo si wu oun ko mu ẹri rẹ wa pe oun lo ni ile naa.

Bayii ni ọrọ ṣe di ti ọlọpaa, ti wọn si mu Loveth Helen Alo.

Bakan naa ni itọpinpin ati iwadii ọlọpaa fi han pe Loveth kọ lo ni ile naa, o kan ya aworan ibẹ lati fi kede ohun ti ko ri bẹẹ ni.

Mi ò jẹ̀bì, mo ṣe ìdúpẹ́ pẹ̀lú ìrètí pé èmi náà máa kọ́ irú ilé bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni-Loveth

Nigba to n ṣalaye ara rẹ ni kootu, Loveth sọ pe oun ko jẹbi bi oun ṣe fi ile onile ṣe idupẹ.

Obinrin naa sọ pe ko si ẹnikan to ba oun to gbogbo idupẹ irọ naa pọ, bi ko ṣe pe o wu oun lati ni iru ile bẹẹ ni.

O ni oun ṣe idupẹ pẹlu igbagbọ pe, oun naa yoo kọ iru rẹ lọjọ kan.

Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, Charles Emeka Nwodo, sọ pe onibaara oun ko jẹbi ẹsun kankan.

O ni Loveth ko gbimọpọ pẹlu ẹnikẹni ninu ipinnu rẹ, ko si ni ero aburu lọkan lori ile onile to fi dupẹ.

Awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu sisọ ohun ti ko ri bẹẹ, igbiyanju lati fipa gba ohun ti ki i ṣe tẹni, ati jijẹri eke ni wọn fi kan olujẹjọ.

Adajọ S.O Chukwuani, fi aaye beeli silẹ fun un pẹlu miliọnu kan naira, o ssi un igbẹjọ si ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin ọdun 2025.

Àlàyé Pásítọ̀ tó ni ṣọọṣi tí Loveth ti ṣe ìdúpẹ́ irọ́

Aworan Ẹfanjẹliisi Ebuka Obi

Ajihinrere Ebuka Obi to ni ile ijọsin Zion Mininstry ti idupẹ irọ naa ti waye, sọ fun BBC pe oun ko ni ohunkohun lati sọ ju bẹẹ lori iṣẹlẹ naa.

Ebuka ṣalaye pe ẹjọ to wa nilẹ yii ki i ṣe lati ṣọọṣi oun, bi ko ṣe pe ẹni to ni ile lo pe ẹjọ tako Loveth Helen Alo.

O ni ki iwadii to lọọrin waye lori rẹ, lati le mọ awọn to ran obinrin naa waa dupẹ eke ni ṣọọṣi Zion Mininstry l'Ekoo, nigba ti ile to fi n dupẹ wa l'Enugu.

Iru nnkan bayii ko ṣẹṣẹ maa waye ni Naijiria

Eyi kọ ni igba akọkọ ti iru iṣẹlẹ bayii n waye ni Naijiria, nibi ti awọn eeyan yoo ti fi dukia ti kii ṣe ti wọn, paapaa ọkọ ayọkẹlẹ, ya fọto, ti wọn o si fi si ori ayelujara.

Iru iṣẹlẹ to di ti agọ ọlọpaa ti waye ni ọdun diẹ sẹyin, nigba ti gbajugbaja ori ayelujara, Blessing Okoro, fi ile kan ti kii ṣe tirẹ ya aworan, to si gbe e si ori ayelujara rẹ lọdun 2019.

Nigba ti ẹni to ni ile ri awọn aworan naa, ati ẹri nu Arabinrin ni ọrọ di ariwo, ko to o di pe arabinrin naa tọrọ aforijin.

O ni oun fi ile naa tọrọ iru rẹ fun ara oun ni.