Wo ìdí tí àwọn aṣòfin ṣe ní kí NCC fòfin de ojú òpó tó ń sàfihàn ìbálòpọ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile igbimọ aṣoju-ṣofin orilẹede Naijiria ni ki ajọ to n risi ibaraẹnisọrọ NCC, paṣẹ fun awọn ileeṣẹ to n pese ayelujara pe ki wọn fofin de gbogbo awọn oju opo ayelujara to ṣafihan fọnran ibalopọ ni kiakia.

Aba ofin yii ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin gba wọle ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta ọdun 2025 lati ọwọ ọmọ ile, Dalhatu Tafoki, ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress nipinlẹ Katsina.

Tafoki ni awọn fọnran ibalopọ lo jẹ aisan agbaye, ti Naijiria si kọ lati gbe igbesẹ to yẹ lati tako iwa yii lawujọ.

O ṣapejuwe orilẹede Naijiria gẹgẹ bii eyi to jẹ orilẹede ẹṣin, ibi ti ọpọ onigbagbọ wa, ti igbagbọ wọn si tako fifi ihoho han sita.

"Ọpọ awọn orilẹede agbaye ni Afrika, Asia ati Middle East lo ti gbe igbesẹ yii lati fofin de fọnran ibalopọ.

"Ọpọ ijamba ni awọn fọnran yii le se, to si le gbero ọpọ nnkan ti ko da si ọkan awọn ọdọ wa."

Ọpọ awọn aṣofin lo ke ero lẹyin.

Saaju ni wọn ti darukọ orilẹ-ede Naijiria gẹgẹ bi orilẹ-ede to n wọ ori ayelujara lati wo fidio ibalopọ julọ lọdun 2019.

Oju opo ayelujara kan to maa n ṣe afihan fidio ibalopọ, Porn Hub, lo fi iroyin yii sita loju opo rẹ pe l'ọdun 2019, awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lo wo fidio ibalopọ julọ lọdọọ wọn.

Oju opo ayelujara 'Porn Hub' sọ pe eyi jẹ abajade akiyesi wọn nipa awọn to wo fidio ibalopọ loju opo wọn l'ọdun 2019.

Aworan ile igbimọ asofin sofin

Oríṣun àwòrán, Others