Mọ̀ nípa ààrùn Diphtheria tó pa akẹ́kọ̀ọ́ kan, sọ ọ̀pọ̀ di èèrò iléèwòsàn l'Eko

Aworan ọwọ wọ ibọwọ, to mu abẹrẹ ajẹsara to n dena Diphtheria dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan ọwọ wọ ibọwọ, to mu abẹrẹ ajẹsara to n dena Diphtheria dani
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Laipẹ yii ni iroyin gbode pe akẹkọọ ọkunrin kan to jẹ ọmọ ile ẹkọ King's College nipinlẹ Eko, jade laye nitori aarun Diphteria to bẹ silẹ nie-ẹkọ naa.

Eyi ti mu ki ijọba ipinlẹ Eko bẹrẹ igbesẹ ilaniloye lori arun naa,ti wọn si n fun awọn akẹkọọ nile-ẹkọ King's College ni abẹrẹ ajẹsara to n dena aarun Diphteria.

Àlàyé Kọmíṣánnà ètò ìlera ìpínlẹ̀ Eko lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ náà

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna eto ilera nipinlẹ Eko, Dokita Akin Abayọmi, ṣe ṣalaye lori iku akẹkọọ naa, o ni ọjọ kejilelogun, oṣu Keji ọdun 2025 ni wọn gbe ọmọ ọdun mejila naa lọ si ileewosan to wa ni ile-ẹkọ King's College.

Ọna ọfun ni wọn sọ pe o n dun un bii Kọmiṣanna ṣe wi, o si tun ni aarun iba pẹlu.

Ṣugbọn nigba to di ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta ọdun yii, ọmọdekunrin naa jade laye.

Iku rẹ yii lo mu ki igbẹsẹ bẹrẹ lati maa ṣọ awọn awọn akẹkọọ to ti fararo ṣaaju iṣẹlẹ naa, lati mọ boya aarun yii ti fọwọ ba wọn.

O kere tan, eeyan mẹrinlelọgbọn ni wọn n yẹwo boya wọn ti ni Diphtheria nibẹ.

Mẹrinla ninu awọn akẹkọọ to n gbe ninu ọgba King's College ni akọsilẹ ijọba Eko fidi rẹ mulẹ pe, wọn fi apẹẹrẹ aarun Diphteria han.

Mejila ninu wọn ni ayẹwo si fi han pe wọn ti ni aarun naa, wọn si ti bẹrẹ si i gba itọju.

Bakan naa ni Dokita Abayomi fi kun un pe "ajakalẹ aarun yii ko kọja ohun ti apa wa ka, ko si si idi kan fun ẹnikẹni lati ko ọkan soke, nitori gbogbo eto to yẹ lati ri i pe a da aabo bo araalu yoo maa tẹsiwaju, lati dẹkun aarun to maa n ran yii."

Bakan naa ni wọn rọ awọn olugbe Eko lati mu imọtoto ni koko.

Ikilọ naa sọ pe ki wọn ṣora fun ibi ti ero ba pọ ju, ki wọn si tete gba ileewosan lọ bi wọn ba kẹẹfin awọn apẹẹrẹ to fara jọ arun Diphtheria.

Ikede nipa abẹrẹ to n dena arun yii ti bẹrẹ fun awọn akẹkọọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eto ilera nileewe naa bayii.

Bẹẹ ni awọn alaṣẹ n ṣiṣẹ nipa bi yoo ṣe kari gbogbo ipinlẹ Eko pata.

Kí ni Diphtheria?

Aarun ti oloyinbo n pe ni Diphtheria jẹ aarun kan to maa n tete ràn gidi.

Kokoro aifojuri ti a mọ si Bacteria lo maa n fa a. O si maa n kọlu imu ati ọna ọfun, yoo gba ibẹ wọnu itọ ẹnu, ikọ ti eeyan ba n hu ati bi eeyan ba n sín.

Bakan naa lo tun le kọlu eeyan ti ẹni naa ba fọwọ kan nnkan ti kokoro to n bi Diphtheria ba ti wa lara rẹ, paapaa nibi ti ero ba ti pọju, tabi ti atẹgun gidi ko ti fẹ wọle.

Ni 2023, aarun Diphtheria bẹ silẹ ni Naijiria, eeyan to ku lati ara ikọlu naa si le ni ẹgbẹta (600), ọmọde lo pọ ju ninu awọn to di oloogbe naa.

Ipinlẹ mọkandinlogun ni ikọlu naa ba ninu mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria, apa Ariwa ni pupọ ninu wọn si wa.

Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Diphtheria

Aarun Diphtheria jẹ oriṣi kokoro aifojuri 'bacteria' to ma n kọlu eroja (mucous membranes) to n daabo bo imú ati ọ̀fun.

Lootọ ni oogun oyinbo maa n wo diphtheria, ṣugbọn to ba ti pọ ju ninu ara, o le ba ọkàn, kindinrin ati ọpọlọ jẹ.

Koda pẹlu itọju, aarun naa ṣi le pa eeyan, paapaa awọn ọmọde.

Awọn ami ti Diphtheria maa n fi han ninu ara:

  • Laarin ọjọ meji si marun-un ni aarun Diphtheria maa n farahan to ba ti wọ ara.
  • Lara awọn ami naa si ni:
  • Egbo ni ọna ọfun
  • Ọrun yoo wú
  • Idiwọ si eemi tabi ki eeyan o maa mi lakọ-lakọ
  • Ikun imu yoo ma jade lai dawọ duro
  • Ara gbigbona ati otutu
  • Aarẹ yoo mu ara
  • Kẹlẹbẹ to ni awọ eeru yoo bo ọfun

Bakan naa lo ṣee ṣe ki ẹni to ni Diphtheria ma ri ami kankan – iru awọn eeyan bayii lo maa n ṣaba pin aarun naa kiri, lai ṣe pe awọn funra wọn dubulẹ aisan.

Ki lo n fa Diphtheria?

Oriṣi kokoro aifojuri 'Corynebacterium Diphtheria' lo n fa a . Kokoro aifojuri naa yoo maa pọ si ni ọna ọfun tabi ni awọ ara.

Ti ẹni to ni aarun Diphtheria ba sín tabi hu ikọ sinu afẹfẹ, ẹni to ba sunmọ ọn tabi kọja lasiko naa le fa Diphtheria si imu.

Ọna kan pataki ti Diphtheria fi maa n di ajakalẹ ree, paapaa ni ayika ti ero ba pọ si.

Eeyan tun le ko aarun yii to ba fi ọwọ kan awọn ohun elo bi aṣọ inuwọ ati awọn nnkan mi-in ti ẹni to ni aarun Diphtheria ti lo, nitori pe o ṣee ṣe ki aarun naa ti sa pamọ si wọn lara.

Yatọ si ọna ọfun, Diphtheria tun le farahan ni awọ ara.

Iru eyi ma n fa irora ninu ara, ara wiwu ati ara pipọn.

Bo tilẹ jẹ pe ko wọpọ niru agbegbe bii Naijiria, o le ṣẹlẹ laarin awọn eeyan ti imọtoto wọn ko ba dara to, tabi awọn to n gbe ni ibi ti ero ti pọ ju bo ṣe yẹ lọ.