"Aya méjì, ọmọ méje àti ìyá ni alága darandaran tí wọn yìnbọn pa fi sílẹ̀, ìjọba, ẹ ṣàánú lórí ìtọ́jú wọn"
Awọn ọmọ ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah nipinlẹ Kwara ti n rawọ rasẹ si ijọba ipinlẹ naa lati dide iranwọ fun ẹbi alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Idris Abubakar ti awọn agbebọn kan yinbọn pa.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Miyetti Allah to ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe ọdun kan pere ninu ọdun mẹrin, ni Alhaji Idris Abubakar tii lo lori aleefa gẹgẹ bii alaga.
O fikun pe o si ni anfaani lati lo ọdun mẹta si lori oye, o si kun le beere afikun ọdun mẹrin miran ni saa keji amọ wọn ti fi iku ja afojusun rẹ kulẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe nnkan bii aago mẹẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2025 ni awọn agbebọn kan lọ ka Abubakar, ẹni ọdun mejilelọgbọn mọ ile rẹ to wa ni agbegbe, Oke-Ose, Oke-Oyi, ipinlẹ Kwara.
Ni ọjọ Aje, ọjọ kẹwaa, ni BBC Yoruba sabẹwo si ile oloogbe naa nibiti ọpọ eeyan darijọ si lati sedaro ẹni wọn to lọ.

Ẹgbẹ Miyetti Allah tẹsiwaju pe Alhaji Idris nigba aye rẹ fẹran igbe aye alaafia, ti kii se jagidijagan.
Wọn ni ẹni ọdun mejilelọgbọn ni Idris to di oloogbe naa, to si fi iya, aya meji ati ọmọ meje silẹ.
Wọn ni bukata nla ni ẹru yii jẹ, ti wọn si n rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati se iranwọ nidi biba wọn gbe lara ẹru naa.
Bakan naa ni ẹgbẹ Miyetti Allah n gba ijọba niyanju lati pese eto aabo to peye fun araalu lọna ati dena irufẹ iwa ipaniyan bayii.
'Géètì ni ọkọ mi ní kí n wá á ṣí fún òun, à ṣé àwọn tí yòó paá ti wà lẹ́nu ọ̀nà'

Wayi o, awọn ẹbi oloogbe, Alhaji Idris Abubakar Sakaina, alaga ẹgbẹ Miyetti Allah Cattle Breeders Association of Nigeria ti ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti awọn agbébọn kan pa, ti rawọ ẹbẹ fun iranlọwọ lori awọn ọmọ ti oloogbe naa fi saye lọ.
Bakan naa ni awọn ẹbi ọun rọ ajọ ọlọpaa lati san sokoto wọn lati rii pe ọwọ tẹ awọn ọdaran to se isẹ ibi yii, ki wọn si fimu kata ofin.
Iyawo oloogbe naa, Aisha Abubakar sọ pẹlu omije loju pe ki ijọba jọ jare siju aanu wo oun ati awọn ọmọ ọun nitori iku ọkọ oun jẹ ojiji ti awọn si nilo iranlọwọ lasiko yii.
Àlàyé lórí bí àwọn agbébọn ṣe yìnbọn pa Abubakar

Aisha sọ wi pe "ni bi ọwọ aago mẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta, mo wa ninu ile, ọkọ mi wa pe mi pe ki n wa si geeti fun oun.
"Bi mo ṣe si geeti ni mo ri awọn ọkunrin meji kan ti mi o riri. Bi wọn ṣe ri mi ni wọn fa ibọn yọ wọn yin-in si ọdọ mi.
"Bi wọn ṣe ṣe eyi ni mo sa pada wọ inu ile lati sa asala fun ẹmi mi.
"Mo gbiyanju agbara mi lati kan si awọn eniyan ki wọn ran ọkọ mi lọwọ tori mo mọ pe wahala ti de sugbọn ko si ẹnikẹni ni arọwọto.
"Bi mo ṣe wa ninu ile naa ni mo n gbọ iro ibọn, igba ti mo fi maa jade, awọn eniyan yii ti lọ, sugbọn mo ba oku ọkọ mi nilẹ, nibi ti wọn yinbọn paa si.
Idris Ali Kau, to jẹ ẹgbọn fun oloogbe naa ke si ijọba Kwara ati ijọba apapọ lati ran idile oloogbe naa lọwọ.
Idris sọ pe oloogbe ẹni ọdun mejilelọgbọn ọhun fi iyawo meji, ọmọ meje ati iya rẹ saye lọ.
O fi kun-un pe, Abubakar jẹ ọlọgbọn ati eniyan to n lepa alaafia ni awọn ṣe yan-an gẹgẹ bi alaga gbogbo Fulani, Miyetti Allah ni gbogbo ipinlẹ Kwara.
O sọ pe o ṣẹsẹ lo ọdun kan lori oye ni tori ọdun to kọja lawọn yan-an.
O sọ ọ di mimọ pe iku rẹ ṣe oun ati awọn yooku ni kayeefi nitori oloogbe naa jẹ onirẹlẹ, awọn o si gbọ ọ ri pe o se jagidijagan pẹlu ẹnikẹni nigba to wa laye.
O ni awọn kan man n gbọ iru iṣẹlẹ bi eyi lo kere ni pe, ko sẹlẹ ri ninu ẹgbẹ awọn.
Idris wa rọ ijọba ki wọn tunbọ mojuto eto abo lati dẹkun iru isẹlẹ laabi bi eleyi.

Ni ọjọ Aiku ni ajọ ọlọpaa Kwara fidi isẹlẹ naa mulẹ nipasẹ atẹjade ti agbẹnusọ ajọ naa ni Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi fi lede.
Adetoun sọ pe awọn ọlọpaa ba ọta ibọn marun-un niwaju ile naa.
O fi kun-un pe awọn ti gbe oku Abubakar lọ si ile ìgbokuupamọ si ni ile iwosan ikọsẹ UITH to wa ni Oke Ose.
Agbẹnusọ naa rọ awọn araalu lati fọkan balẹ, nitori ajọ naa yo sa ipa rẹ lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu isẹlẹ naa.
















