Wọ́n yẹgi fún ọmọ ọ̀dọ̀ lórí ẹ̀sùn pé o pa ọmọ ọ̀gá rẹ̀ tó ń tọ́jú

Shahzadi Khan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba United Arab Emirates ti yẹ igi fun ọmọ orilẹede India kan to n ṣiṣẹ ọmọ ọdọ nilẹ naa lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe, o ṣekupa ọmọ ẹni to gba a siṣẹ.

Ijọba India sọ pe oṣu to kọja ni wọn yẹ igi fun Shahzadi Khan, to n ṣiṣe fun tọkọtaya kan ti awọn naa jẹ ọmọ orilẹede India.

Iwe ile-ẹjọ to ni ki wọn yẹgi fun Khan sọ pe, ṣe ni o mọọmọ di ọna ti eemi n gba wọ inu agọ ara ọmọ naa pa, eyii to yọri si iku rẹ.

Amọ ṣa, dokita kan to jẹri nibi igbẹjọ naa sọ pe oun ko le fidi alaye naa mulẹ nitori wọn ko fun oun laaye lati ṣe ayẹwo oku ọmọ ọhun.

Awọn mọlẹbi Khan ti sọ pe ọmọ awọn ko jẹbi ẹsun iṣekupani ti wọn fi kan an, ati pe abẹrẹ ajẹsara kan ti ọmọ oṣu mẹrin naa gba lọjọ to jade laye lo ṣokunfa iku rẹ.

Wọn tẹsiwaju pe afurasi ọhun ko ni aṣoju to dantọ ati agbẹjọrọ to moye lasiko igbejọ rẹ.

Ọjọ karundinlogun, oṣu Keji, ọdun 2025 ni wọn gbẹmi Khan amọ ko si ẹni to gbọ nipa igbesẹ naa titi di igba ti awọn mọlẹbi rẹ kọwe si ile-ẹjọ giga ilu Delhi lati mọ ibi to wa.

Ọpọ ọmọ orilẹede India lo n woye eredi ti ijọba UAE, to ni ibaṣepọ to dan mọran pẹlu India, ṣe se ọrọ naa ni oku oru.

Iwe ti mọlẹbi rẹ kọ sile ẹjọ giga ilu Delhi fi han pe inu oṣu Kejila, ọdun 2021 ni oloogbe naa tẹkọ leti lọ UAE lati lọ maa ṣe iṣẹ ọmọ ọdọ pẹlu mọlẹbi ti ọmọ wọn ku.

Baba Khan sọ fun awọn akọroyin pe, loorekoore lo maa n pe awọn lori ipe fidio lati ba awọn sọrọ, koda o maa n fi ọmọ tuntun naa han awọn lori fidio.

Ṣugbọn wọn ko gburo rẹ mọ lẹyin iku rẹ.

Lẹyin iku ọmọ naa ni ọlọpaa mu Khan, ṣugbọn o sọ pe ṣe ni wọn fi tipa-tipa mu oun lati sọ pe oun l'oun pa ọmọ naa, eyi ti wọn ka silẹ.

Inu oṣu Keje ọdun 2023 ni wọn ṣedajọ iku fun, ti ile-ẹjọ si kọ ẹjọ kotẹmilọrun to pe ninu oṣu Keji, ọdun 2024.